Sunday Igboho in Benin Republic: Ọ̀gágunfẹ̀yìntì Buratai gúnlẹ̀ sí Benin Republic láti rí Ààrẹ Patrice Talon gẹ́gẹ́ bí aṣojú ìjọba Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Benin presidency
Olori ileeṣẹ ọmọogun Naijiria nigba kan ri, Tukur Buratai ti farahan niwaju aarẹ orilẹede Benin Republic, Patirce Talon. Ọjọ Iṣẹgun ni eyi waye nile aarẹ Orilẹede naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe orilẹede Benin yii kan naa ni eekan ọmọ Yoruba to n lewaju idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho wa bayii to ti n jẹjọ lẹyin to fẹ gba orilẹede naa kọja si orilẹede Gernmany.
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
- Irọ́ ni, a kò pe Sunday Igboho ní Prophet Muhammed (S.A.W) - Ẹgbẹ́ Afenifere
- Àwọn ọ̀nà tí òfin tuntun CBN lórí Bureau De Change tí wọ́n gbé'gi lé ṣe kàn ọ́
- Pàá lẹ́ẹ̀kínní, pàá lẹ́ẹ̀kejì, Germany d'áṣọ ìyà fún D'Tigers Nàìjíríà lẹ́yìn ìkọlù Australia ní Olympics
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa Ọjà Ebeano tí ọmọ kékeré kan jó níná ní ìlú Abuja
- Wọ́n ti fi ẹ̀sùn míì kan Sunday Igboho ní ìlú Benin! - Agbẹ́jọ́rò Igboho
Amọṣa kii ṣe tori ọrọ Igboho ni Ọgagunfẹyinti Buratai ṣe lọ si ilẹ Benin Republic, Ọgagunfẹyinti Buratai ni aṣoju ijọba orilẹede Naijiria tuntun si orilẹede Benin. Ni ọjọ Iṣẹgun lo si mu iwe aṣẹ lọ fun aarẹ orilẹede naa, Patrice Talon.
Ilu Cotonou, olu ilu orilẹede Benin ni awọn agbofinro ti mu Sunday Igboho.











