Àwọn agbébọn kọlu àwọn akọ̀ròyìn, ṣekúpa èèyàn mẹ́ta

Aworan awon agbebon

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n risi ere bọọlu lorilẹede Naijiria, NFF ti ransẹ ibanikẹdun si idile mọlẹbi akọroyin Supersport ati eeyan méjì to padanu ẹmi wọn lasiko ikọlu awọn ajinigbe.

Iṣẹlẹ naa waye ni ọna Ihiala sì Orlu nipinlẹ Anambra ni ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹwaa.

Nínu atẹjade kan ti NFF fi lede lọjọ Satide, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe ayaworan, Ọlọpaa ati Dẹrẹba ọkọ lo padanu ẹmi wọn.

Awọn oloogbe yii lo n rin irinajo ninu ọkọ Supersport nigba ti awọn agbébọn naa sina bolẹ fun wọn.

Lasiko irinajo wọn lọ si ilu Uyo nipinlẹ Akwa Ibom lati lọ ṣe iroyin nípa ìfẹsẹwọnsẹ laarin Naijiria ati Libya ni iṣẹlẹ naa waye.

NFF, ninu atẹjade naa ni eeyan mẹjọ ni wọn rí dola, ti meji si ri aye lati salọ sugbọn wọn ko ti ri eeyan kan laarin wọn.

Saaju ni ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Anambra kede sita pe wọn rí eeyan mẹfa doola lọwọ awọn ajinigbe.

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ naa, SP Tochukwu Ikenga ni akitiyan n lọ lọwọ lati doola eeyan kan to di àwátì..

Aarẹ NFF, Alhaji Musa Gusau ni iṣẹlẹ naa lo bani ninu jẹ pupọ bo ti lẹ jẹ pe orilẹede Naijiria borí ìfẹsẹwọnsẹ naa.

"Bẹẹni, a borí ìfẹsẹwọnsẹ naa sugbọn a padanu eeyan mẹta, to si dun wa pupọ.

"Adura wa ni pe ki Ọlọrun duro tí awọn mọlẹbi eeyan to padanu ẹmi wọn."