Cameroon fòfin de gbígbé ìròyìn jáde nípa ìlera Ààrẹ Biya

Oríṣun àwòrán, AFP
Bi oju akata ba lewo, ki i ṣe ẹnu adiyẹ lo yẹ ka ti gbọ. Eyi ni awọn alaṣẹ lorilẹede Cameoon ṣe paṣẹ fun awọn akọroyin ibẹ, lati ma ṣe gbe ohunkohun jade mọ nipa ilera aarẹ wọn, Paul Biya.
Aṣẹ yii waye lẹyin ti ahesọ gbode pe Aarẹ Biya ti jade laye.
Minisita ọrọ abele ni Cameroon, Paul Atanga Nji, ṣalaye pe iroyin iku aarẹ naa da omi alaafia ilu ru, o si ko awọn araalu laya soke.
“ A ti fofin de gbogbo ohun to ba jẹ mọ iroyin nipa ilera aarẹ, oniroyin to ba si tapa si aṣẹ yii yoo foju wina ofin.’’ Bẹẹ ni minista naa wi.
Ko sẹni kan to tun foju kan Aarẹ Paul Biya ni gbagede mọ, lẹyin ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 to bawọn pejọ sibi ipade kan ti wọn ṣe ni Beijing, lorilẹede China.
Eyi naa lo fa a ti iroyin nipa ipo ilera rẹ tabi pe o ti papoda fi jẹyọ.
Ẹni ọdun mọkanlelaaadọrun-un (91) ni Aarẹ Paul Biya, ọdun kejilelogoji si ree to ti wa nipo aarẹ orilẹede Cameroon.
Awọn kan ninu ijọba rẹ taku pe alaafia ni Aarẹ Paul Biya wa, wọn ni o kan wu u lati da wa nibi kan ni Geneva, lorilẹde Switzerland ni.
Bakan naa ni minisita ọrọ abẹle rẹ naa sọ pe ipo ilera aarẹ ki i ṣe iroyin to kan le maa tan yika, o ni aabo aarẹ ni aabo ilu.
Nji paṣẹ fawọn gomina lati ba awọn oniroyin ipinlẹ wọn sọrọ, ki kaluku dakẹ nipa ilera aarẹ.
Ojú ìwòye àwọn oníròyìn nípa àṣẹ náà
Ọpọlọpọ akọroyin lorilẹede Cameroon ni wọn sọ pe awọn ri aṣẹ yii bii titapa si ofin to faaye gba ki oniroyin le sọ ọrọ ẹnu rẹ lai foya.
“ Emi ri aṣẹ yii bii titẹ ofin awa akọroyin loju mọlẹ. Aṣẹ naa yoo ṣ’akoba fun iṣẹ wa, nitori ko ni i jẹ ka le sọrọ bo ba ṣe ri, ka ma lọọ ko si wahala ijọba”
Akọroyin Cameroon kan lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Bakan naa ni ofin to de awọn akọroyin yii ti mu ki ẹru maa ba awọn eeyan lori aabo wọn.
Ọpọ igba ni awọn alaṣẹ maa n dọdẹ awọn akọroyin ni Cameroon, bẹẹ naa si ni awọn ẹgbẹ ti ko nifẹẹ alaafia maa n ṣọ wọn kiri.
“ Emi a maa kọ iroyin lọ nitemi, bo tiẹ jẹ pe ẹru n ba mi pe wọn le ṣọ mi ki wọn si mu mi, nitori ko si bi iroyin mi ko ṣe ni i mẹnuba ilera aarẹ ati ibi to wa.
Ṣugbọn sibẹ, mo maa tẹsiwaju ninu iṣẹ mi.’’
Bẹẹ ni akọroyin miran tun sọ fun BBC.
Ninu atẹjade kan ti igbimọ to n ri si aabo awọn akọroyin(Committee to Protect Journalists) (CPJ), fi sita l’Ọjọbọ, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 ni wọn ti ni ki ijọba yee dunkooko mọ awọn akọroyin.
Bi ọrọ ilera Aarẹ Biya ṣe n ja ran-in nilẹ to, o tun fẹẹ dupo aarẹ ni 2025.
Ṣaa, bi yoo ṣe yọju si awọn araalu, ti awuyewuye yoo tan nilẹ ni wọn lo jẹ awọn ọmọ Cameeroon logun bayii.














