Ọwọ́ kò tíì tẹ Alfa Saheed Shittu, ní ilé ẹjọ́ bá ju ọmọṣẹ rẹ̀ kan sí ẹ̀wọ̀n n'Ilorin

Aworan Alfa Saheed Shittu

Oríṣun àwòrán, Save Your Soul TV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara ti pasẹ wi pe ki wọn ju ọmọsẹ ilumọọka Alfa, Alhaji Saheed Shittu si ahamọ.

Ile ẹjọ ni ki wọn ju ọmọsẹ Alfa naa ti orukọ rẹ n jẹ Idris Adewale satimọle lori ẹsun igbimọpọ lati ṣeka ati idunkoko mọ agbofinro.

Ẹsun mii ti wọn tun fi kan Adewale ni pe o ṣe idiwọ fun agbofinro kan lati ṣiṣẹ rẹ, eyi ti ile ẹjọ sọ pe o lodi si ofin orileede Naijiria.

Ti ẹ o ba gbagbe, ọga rẹ, Alfa Shittu ni awọn agbofinro ti n wa fun bi oṣu mẹjọ sẹyin bayii, lẹyin ti ile ẹjọ kede pe ki wọn mu un, ki wọn si wọ ọ wa si ile ẹjọ nitori pe kii yọju ni awọn ọjọ igbẹjọ.

Ẹgbẹ APSD tọ jẹ ẹgbẹ awọn ọmọbibi ilu Ilorin lo pe Alfa Shittu lẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ati ẹsun mii.

Bi igbẹjọ naa ṣe lọ ree

Gẹgẹ bi o se wa ninu iwe ipẹjọ ti ileesẹ ọlọpaa mu wa ile ẹjọ, Alfa Saheed Shittu ni o tabuku Emir Ilorin ati awọn mii lori ayelujara ni ọdun 2020, 2021, 2022, ati 2023.

Iwe ipẹjọ naa sọ pe awọn ọlọpaa ti tọpasẹ rẹ lọ si ipinlẹ Eko ti wọn si fun ni iwe ipenilẹjọ ni ọpọlọpọ igba sugbọn ti o kọ eti ikun si wọn.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ naa sẹ sọ "ni ọjọ kẹrin, osu Kẹwaa ọdun 2024, osisẹ ile ẹjọ kan, Ibrahim Fatai Dankastina, lọ si ile Alfa Shittu lati fun un ni iwe ipenilẹjọ, ti o si ba ọmọṣẹ rẹ, Idris Adewale nile.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Nibẹ ni Adewale ti dunkoko mọ ẹni to mu iwe ipẹjọ naa wa lati se e leṣe pẹlu ọbẹ.

"Ni ọjọ kẹsan-an, osu Kẹwaa, ọdun 2024 bakan naa, ni awọn agbofinro tun tẹ ọkọ leti lọ si Eko fun isẹ iwadii lẹyin ti kọmisanna ọlọpaa paṣẹ pe ki wọn mu Saheed Shittu gẹgẹ bi ile ẹjọ ṣe kede rẹ.''

O tun wa ninu iwe ipẹjọ naa wi pe nigba ti wọn ri ọkọ Toyota Hilux rẹ, wọn da a duro fun ayẹwo sugbọn Adewale ti o wa ọkọ naa ko gba wọn laye lati sisẹ wọn, o si da wọn duro fun wakati meji gbako loju ọna, o si tun tabuku wọn.

Ninu ifọrọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn ọlọpaa ni Adewale ti jẹwọ pe, ọkọ Toyota Hilux naa, jẹ ti Saheed Shittu, o si tun mọ si ibanilorukọjẹ to ṣe lori ayelujara.''

Iwadii tun fi han pe ọmọṣẹ Alfa Shittu tabuku ati dunkoko mọ osisẹ ileẹjọ ati ọlọpaa.

Awọn olupẹjọ tun fidi rẹ mulẹ pe Alfa Saheed Shittu ati ọmọṣẹ rẹ lo n lo ayelujara to si n sisẹ lorukọ Save your Soul TV ti wọn si n lo o lati ba oloogbe Sheikh Adam El'Ilori ati awọn olori ẹṣin mii lorukọ jẹ.

Iwe ipẹjọ
Iwe ipẹjọ

Aṣẹ ti adajọ pa

Lẹyin ti wọn ka iwe ipẹjọ naa tan, ni agbefọba, Akinjide Adisa fi iwe ẹsun ọdaran ti wọn lẹ mọ iwe ipẹjọ naa to adajọ leti.

Sugbọn adajọ, M.B. Bamidele, da iwe ẹsun ọdaran naa nu wi pe ẹsun ti wọn fi kan an, ko to eyi ti o wa ninu iwe naa.

Lẹyin eyi lo pasẹ wi pe ki wọn ju Adewale si ahamọ

Adajọ ni ko lọ ma gbatẹgun lọgba ẹwọn Oke-Kura niluu Ilorin nigba ti iwadii yyo si maa tẹ siwaju.

O wa sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, osu kẹwa, ọdun 2024.