Àwọn aráàlú fò fáyọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n pa erinmilókun tó ń yọ wọ́n lẹ́nu nípìnlẹ̀ Kebbi

Aworan erinmidò ti wọn pa

Oríṣun àwòrán, Sani Yauri

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Níṣe ni àwọn èèyàn ìlú Yauri ní ìpínlẹ̀ Kebbi ń fò fáyọ̀ báyìí lẹ́yìn tí wọ́n ṣekúpa erinmilókun kan tó ti ń yọ wọ́n lẹ́nu lágbègbè náà.

Àwọn àgbẹ̀ onírẹsì àti àwọn apẹja ni wọ́n ṣekúpa erinmilókun náà lẹ́yìn tí wọ́n dọdẹ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀.

Erinmilókun àti ọmọ rẹ̀ ni àwọn apẹja náà ṣekúpa.

Lati ìgbà tí erinmilókun ọ̀hún ṣekúpa apẹja kan tó ń ṣiṣẹ́ fún Baálẹ̀ ìlú náà ni àwọn èèyàn ti ń bẹ̀rù rẹ̀ pé ó tún lè ṣe àwọn ní ìjàm̀bá.

Èyí ló mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi pàṣẹ pé kí wọ́n pa ẹranko náà kí àwọn tó ń gbé ní agbègbè odò River Niger ní ìpínlẹ̀ náà lè wà lábẹ́ ààbò tó péye.

Iye erinmilókun tó wà ní Nàìjíríà ni àdínkù ti bá láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn – ìwádìí sọ pé ẹranko náà kò ju bíi ọgọ́rùn-ún kan lọ mọ́, tó sì jẹ́ pé àwọn ààyè tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wọn ni wọ́n wà.

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin, tí wọ́n lo ọ̀kọ̀ tí wọ́n ṣe ní ìlànà ìbílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní “zagos” láti fi pa erinmilókun náà.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé òkú ẹranko ọ̀hún lọ sí ààfin ọ̀kan lára àwọn Emir ìlú Yauri níbi tí wọ́n ti pín ẹran rẹ̀ fáwọn ara ìlú.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọ̀kan lára àwọn olùgbé ìlú Yauri, Sani Yauri sọ fún BBC pé iṣẹ́ apẹja àti àgbẹ̀ ni àwọn máa ń ṣe ní ìlú àwọn àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kò rí iṣẹ́ ṣe mọ́ látara ìbẹ̀rù pé kí erinmilókun má ya àwọn jẹ.

Sani ṣàlàyé pé yàtọ̀ sí pé ẹranko náà pa òṣìṣẹ́ Emir kan àti ṣíṣe ẹlòmíràn lé ṣe, ó ní ẹranko náà tún máa ń da àwọn láàmú nínú oko.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ oko tó súnmọ́ etí odò tí erinmilókun náà wà ní wọ́n ti máa ń ṣe alábàápàdé rẹ̀.

“Inú wa dùn pé wọ́n rí erinmidò náà pa, àwọn èèyàn ń fò fáyọ̀ tí wọ́n sì tún rí ẹran rẹ̀ gbà.”

Ará ìlú mìíràn, Isa Jamilu sọ pé ọkàn òun ṣẹ̀ṣẹ̀ balẹ̀ báyìí àti pé òun yóò rí bi máa lọ sí oko tí òun ti patì láti ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn nítorí ẹranko náà.

Níṣe ni àwòrán òkú erinmidò náà ti wà lórí ayélujára táwọn èèyàn sì ń sọ èrò wọn lórí ẹranko náà.

Àwọn kan ń kan sáárá sí àwọn ará ìlú Yauri fún pípa erinmidò náà, tí àwọn mìíràn sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ yìí.

Ajàfẹ́tọ̀ọ́ àwọn ẹranko kan, tó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ Nigeria's African Voice for Animals Initiative, Isyaku Abdullahi ní inú òun kò dùn rárá nígbà tí òun rí fídíò bí àwọn èèyàn ṣe ń yọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n pa erinmidò náà tán.

Abdullahi wòye pé nǹkan tó yẹ kí àwọn ará ìlú náà ṣe ni láti lọ fi ọ̀rọ̀ erinmidò náà tó àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹranko létí.

Ó ní àwọn aláṣẹ náà yóò ṣètò bí wọ́n ṣe máa mú ẹranko náà kúrò ní agbègbè tó ti le ṣe ará ìlú ní ìjàm̀bá.

Ó wòye pé àwọn èèyàn tó ń gbé nínú abúlé pàápàá ní irú ìpínlẹ̀ Kebbi tí odò pọ̀ sí nílò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe àmójútó àwọn ẹranko tó lè ṣe èèyàn ní ìjàm̀bá.

Ìpínlẹ̀ Kebbi gbajúmọ̀ fún ṣíṣe ayẹyẹ ọdún odò dídẹ ìyẹn Argungu Festival tó máa ń wáyé ní ọdọọdún, tó sì wà lára àwọn ayẹyẹ tí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN gbà wọlé

Erinmidò ni ẹranko tó wà ní ipò kẹta nínú àwọn ẹranko orí ilẹ̀ tó tóbi jùlọ. Eyín gùn tó 50.8cm, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n le sáré kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n láàárín wákàtí kan.

Ẹranko tó máa ń jẹ ewé ni wọ́n àmọ́ wọ́n le ṣekúpa èèyàn tí wọ́n bá wòye pé èèyàn ń dúnkokò mọ́ ibùgbé àwọn.

Èèyàn tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ni ìwádìí ní wọ́n máa ń ṣokùnfà ikú rẹ̀ ní Áfríkà ní ọdọọdún.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ẹranko yóò máa ṣekúpa èèyàn ní Nàìjíríà. Láìpẹ́ yìí ni Kìnìún kan ṣekúpa ẹni tó ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀ ní ọgbà ẹranko Olusegun Obasanjo Presidential Library tó wà ní Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun.

Bákan náà ni òṣìṣẹ́ ilé ìtọ́jú ẹranko ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo, Ile Ife, Olabode Olawuyi pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ Kìnìún ní ogúnjọ́ oṣù kejì ọdún yìí.