Mo di ẹni tí wọ́n ń fi N10,000 pè sí òdé eré lẹ́yìn tí ẹlẹ́mìí ríran sí mi - Ajoke Cinderella

Àkọlé fídíò, Orí àkìtàn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ eré Fuji ṣíṣe - Ajoke Cinderella
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fatimah Ajoke, ti ọpọ eeyan mọ si ajoke Cinderella, gbajumọ olorin fuji, ti ba BBC sọrọ lori nnkan to fa a ti aye ko fi gbohun rẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Ọsẹ diẹ sẹyin ni orin kan ti Ajoke kọ, 'Bisimillahi mo ti de' deede ṣẹyọ lori ayelujara Tiktok, to si di nnkan ti tmọde-tagba n kọ nigboro.

Orin naa to pada jade lo mu ki ọpọ eeyan to jẹ ololufẹ arabinrin naa ranti rẹ, ti wọn si n beere pe, nibo gan-an lo wa lati ọjọ yii ti wọn ko fi gbohun rẹ lagbo Fuji mọ.

BBC Yoruba ṣe awari arabinrin naa, to si sọ gbogbo bi irinajo rẹ ṣe ri.

Arabinrin Fatimah Ajoke sọ fun BBC pe ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ni oun wa nigba ti ẹbunorin ti n jẹ jade lara oun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iya oun ma n da waka orin asalaatu nigba naa, eyi ti oun naa fi ma n dan orin kikọ wo.

Lẹyin dun diẹ, Ajoke Cinderella kuro ni ilu abinibi rẹ, o si di ẹni to n gbe niluu Eko.

"Ile ẹkọ alakọbẹẹrẹ ni emi ati awọn akẹẹgbẹ mi ti ma n fi agolo ṣe irinaṣẹ orin, ti mo ma n kọ.

"Erekusu Eko, nibi ti wọn n pe ni Ori Dunghill' ni mo ti bẹrẹ orin kikọ."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọdun 2006 ni awo orin rẹ akọkọ, Yellow Card, jade.

Ẹkun omi da Ajoke Cinderella pada si ẹsẹ aarọ

Ajoke Cinderella

Oríṣun àwòrán, BBC/Ajoke Cinderella

O ni lẹyin naa oun ko ṣe awo orin miran jade laarin ọdun 2008 si 2010.

Asiko naa lo pinnu lati ni ọkọ, to si bimọ.

"Bi mo ṣe ni oyun ọmọ mi, mo ṣi n lọ si ode ere, amọ ko dabi.

Ajoke ṣalaye pe lasiko naa, oun ti kọ ile kan ni agbegbe Ojokoro nipinlẹ Eko.

"Aarọ ọjọ kan ni mo ji sinu omi ninu ile mi, lẹyin ti ojo rọ.

"Nibi ti mo ti lọ fun eto adura nile ijọsin alaṣọfunfun kan ti mo n lọ, ni ẹlẹmi ti rina si mi pe, ki n fi ilu eko silẹ patapata.

Akọrin Fuji ọhun sọ pe oun gbran si aṣẹ naa, eyi to sọ ọ di ẹni to n ṣe awọsun lọdọ ọrẹ rẹ kan niluu Ile-Ife, nipinlẹ Osun.

Mo di ẹni ti wọn n fi 10,000 Naira lọ ni ode orin kikọ

Fatimah Ajoke cinderella sọ pe oun ko fi iṣẹ orin kikọ silẹ, nitori pe oun ni iṣẹ oojọ oun.

"Mo ma n pe awọn onigbọwọ mi ni Ibadan.

'"Emi ti mo ti n gba 300,000, 500,000 si 800,000 Naira fun ode orin kikọ, di ẹni ti wọn n fi N20,000 ati N10,000 lọ."

O ni oun ko le sọ bi orin kan ti oun kọ ni ode ariya kan ni National Theatre nipinlẹ Eko ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ṣe jade si ori ayelujara.

Orin naa to jade lo pada jẹ ki awọn eeyan o tun gburo rẹ.

Arabinrin Ajoke sọ pe nnkan to wu oun lasiko yii ni lati gbe awo orin jade .