'Iṣẹ́ tíátà ló gba ilé ọkọ lọ́wọ́ mi, àmọ́ mi ò kábàámọ̀ pé mo dúró nídìí iṣẹ́ nàá'
Agba oṣerebinrin, Taiwo akinwande, ti ọpọ mọ si Yetunde Wumi, ti ṣalaye lori bi irinajo rẹ sinu iṣẹ tiata ṣe bẹrẹ.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Wumi ṣalaye pe iṣẹ tiata naa lo gba ile ọkọ lọwọ oun, o ni ṣugbọn oun ko kabamọ pe oun duro nidi iṣẹ naa.
Ọdun 1982 ni Yetunde Wumi bẹrẹ iṣẹ tiata, ni abẹ Ọgbẹni Sunday Akinola, ti gbogbo eeyan mọ si Feyikọgbọn.
Lori bi awọn eeyan kan ṣe gbagbọ pe awọn oṣerebinrin maa n fi ara gba iṣ, Arabinrin Yetunde Wumi sọ pe eyi ko ri bẹẹ. O ni Ọlọrun lo n kọ irawọ mọ eeyan, ẹni ti ko ba ni di ilumọọka, koda ko fi ara gba iṣẹ, ko nii ri bẹẹ.
Wumi sọ pe iriri kan ti oun ko le gbagbe nidi iṣẹ naa ni ọjọ kan ti oun gbe ọmọ ogoji ọjọ lọ si oko ere tiata ni ilu Ilorin.
O ni loot ni pe iye owo iṣẹ ti oun gba, Nairan mẹrindinlogun, naa ni oun fi wo aisan to ṣe ọmọ naa nibẹ.
‘Mi o ri eyi ro rara, nitori pe inu mi dun pe mo ri iṣẹ sẹ. Amọ nnkan ẹykan to ba mi ninu jẹ ni pe, ọmọ naa pada ku nigba to le diẹ ni ọdun kan.
‘Ko duro ba mi jẹ ọrọ iṣẹ tiata.’

Agba oṣere naa wa a sọ pe ṣiṣi ara silẹ tabi fi ihoho oun han nikan ni ipa ti oun ko le ko ninu ere.
Botilẹ jẹ pe agba oṣere naa sọ pe oriṣiriṣi nnkan lo mu inu oun dun nidi iṣẹ naa, o ni amọ ọjọ ti inu ohun bajẹ julọ ni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si ni ọdun diẹ sẹyin.
O ni oun ko fẹ maa sọrọ nipa iṣẹlẹ naa mọ.
Fun awọn ti ko ba mọ, ni ọdun 2006 ni ajọ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro, NDLEA, mu Yetunde wumi, fun ẹsun pe o gbe egboogi oloro.
Papakọ ọkọ ofurufu Muritala Muhammed ni wọn ti mu lasiko to n rirninajo lọ silu London.
Lara awọn fiimu ti Yetunde Wumi ti kopa ni Apaadi, Egbin Ara













