Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú

Gbajugbaja alapata ẹran kan ni ilu Ikare-Akoko nipinlẹ Ondo, ti padanu ẹmi rẹ lẹyin ojo alagbara kan to rọ nilu naa.
Alapata naa ti awọn eeyan mọ si Ayepareti ni iroyin sọ pe o kagbako iku ojiji lasiko to sa si abẹ òrùlé ile kan ni adugbo Okela nitori ojo to n rọ.

Nise ni ile naa wo lu u mọ́lẹ̀, ileewosan ti wọn gbe lọ sini wọn ti fidirẹmulẹ pe o ti ku.
Ẹni kan lara awọn olori agbegbe naa to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun iwe iroyin ori ayelujara The Precision, Ibrahim Kilani sọ pe ojo naa ko rọ ju ogoji isẹju lọ, sugbọn ọpọ eeyan lo sọ di alainilelori.
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- "Who wants to be a Milionaire'' tí pada sí orí afẹ́fẹ́! ẹyin olólùfẹ́ rẹ̀, ẹ kú oríire!
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà
Gẹgẹ bi Ọgbẹni Kilani ṣe sọ, aago méje alẹ ti kọja ki ojo naa to o bẹrẹ ni ọjọ Aiku, ti yìnyín nlanla si n jabọ pẹlu atẹgun lile.
Kilani ni ile bi i aadọjọ lo si òrùlé wọn ni awọn agbegbe bi i Ilepa, Okela ati Okoja.
Alapata naa ti orukọ ẹ njẹ Ayeparẹti ni o di ologbe lẹyìn ti ile ti o sapamọ si nigbati ojo naa n rọ dawo le lori.

Ojo ọun ti a gbọ pe o rọ fun bi ogoji iṣẹju pẹlu yinyin ati iji lile ni o ba ọpọlọpọ ile ti o ju aadojọ jẹ ni ilu naa.
Ọkan ninu awọn adari ilu Ikarẹ, Alhaji Ibrahim Kilani ti o fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe iku Ayeparẹti ti ju awọn ara ilu naa sinu ọfọ.
Iṣẹlẹ naa si ti mu ki awọn araalu ati awọn agbaagba beere fun iranlọwọ lati ọdọ ijọba fun awọn to padanu dukia wọn, paapaa nitori owo eroja ikọle to ti lọ soke.
Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ awọn agbaagba ilu Ikare, alagba James Oladetohun ba awọn ti o f'ara kasa ninu iṣẹlẹ naa kẹdun, o si kepe ijọba lati pese iranwọ fun wọn.
Awọn adugbo ti iṣẹle arọida ojo naa ti ṣe oṣẹ ni Ilepa, Okela ati Okoja















