Who wants to be a Milionaire: Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, "Who wants to be a Milionaire'' pada sí orí afẹ́fẹ́!

Oríṣun àwòrán, Alamy
Eto ''Who wants to be a Milionaire'' ti ọpọlọpọ eniyan fẹran ti pada ti ṣetan lati pada si oju iworan awọn eniyan lẹyin ọdun mẹrin.
Awọn alakoso eto naa ti ni ogun miliọnu naira ni ẹni to ba bori yoo ma gba ni ọṣọọṣẹ fun ọdun ti wọn ba fi ṣe eto naa.
Eto naa ti wọn bẹrẹ ni Naijiria ni nkan bi ọdun mẹtala ṣẹyin lo ṣe atẹlẹ iru eto naa ni Ilẹ Gẹẹsi ti wọn pe orukọ rẹ ni "Millionaire" tabi "WWTBAM".
- Òní ní BBNaija 2021 ń parí, tani yóò fí 90m naira sara rindin?
- Whitemoney lo gbe igbá orókè nínú ètò ẹlẹ́gbọ́n àgbà ọdún 2021
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- Muinat Ilebiyi Imeko classroom collapse: Fún ọjọ́ márùn-ún, a ò rí tísà ọmọ mi tó kú kó yọjú sí wa
Ọdun 2004 ni wọn bẹrẹ ni Naijiria titi di ọdun 2017 ti wọn ko le e ṣe mọ lẹyin ti ileeṣẹ ero ibanisọrọ MTN fa ṣẹyin kuro ninu eto naa, eleyii to jasi opin eto naa nigba naa.
Ni ọdun mẹtala ti wọn fi ṣe eto naa ni awọn eniyan fi kopa ninu eto naa nitori o kọ awọn eniyan ni ọgbọn ati imọ nipa ohun to n ṣẹlẹ ni ayika ẹni.
Aroma Ufodike lati ilu Nnewi, ni ipinlẹ Anambra to kopa ninu eto naa ni ọdun 2009 lo gba miliọnu mẹwaa naira lẹyin to jawe olubori.
Bawo ni eto ''Who wants to be a Milionaire'' yoo ṣe lọ?
Eto naa ni awọn agbekalẹ to tẹle fun ẹnikẹni to ba fẹ kopa ninu eto naa, ti awọn olukopa ninu eto naa fun saa kọọkan yoo kọkọ kopa ninu eto "Fastest Finger First" lati ṣe atunto ọrọ bi o ti yẹ.
Ẹni to ba bori ni ipele kini yii ni yoo lọ si ipele keji lati bẹrẹ si ni dahun ibeere ninu eto naa.
Wẹrẹ ti oludije ba bẹrẹ si ni kopa ninu eto naa ni wn yoo ma bere awọn ibeere to le lati dahun ni ọwọ rẹ pẹlu idahun eleyọ mẹrin, ti ludije yoo mu gẹgẹ bi idahun to peye.
Bi ẹni naa ba ṣe n gba ibeere naa si ni owo rẹ yoo ma a goke si.
Lasiko idije naa, olukopa yoo ni anfaani lati bere fun iranwọ, eleyii ti yoo mu ki idahun ibeere rẹ jẹ meji, eleyii ti yoo mu ọkan ninu rẹ.
- Ṣé ẹ ti rí 'Penis Fish,' ẹ̀ja tuntun tó rí bí nǹkan ọmọkùnrin tó lúwẹ̀ẹ́ jáde nínú òkun rí?
- Mínísítà Sunday Dare gbéná w'ojú Obasanjọ tó ní Buhari ò pèsè iṣẹ́ f'áwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà
- Ọwọ́ tẹ bàbá ẹni ọdún 52 tó ń bá ọmọ rẹ̀ lòpọ̀ fún ọdún méjì
- Ọlọ́pàá tají padà lẹ́yìn 'Coma' oṣù mẹ́sàán, 'sack letter' làwọn ọ̀gá rẹ̀ fi kíi káàbọ̀
- Ọ̀gágun ojú òfurufú Sikiru Smith tí wọ́n jí gbé l'Eko ti bọ́ lọ́wọ́ ajinigbé
- 'Àwa akẹ́ẹ̀kọ́ tako bí àwọn adarí fásitì OAU ṣe ti iléẹ̀kọ́, ìfẹ̀hónúhàn tẹ̀síwújú lórí ikú akẹgbẹ́ wa'
Bakan naa ni olukopa ni anfaani lati pe ọrẹ ni iṣẹju aaya ọgbọn lati sọ idahun si ibeere naa fun un.
Ko tan si bẹ, awọn oluworan naa ni anfaani lati ṣeranwọ fun olukopa nipa sisọ idahun naa ti wọn ba ti fun wọn ni anfaani.
Kini tuntun ninu eto ''Who wants to be a milionaire'' ti saa yii?
Adari Ileeṣẹ BLK HUT media to n ṣe eto naa, Hakeem Condotti ni awọn yoo sa ipa wọn ni saa yii lati ri pe eto naa yoo jẹ moriya, moriwu ati eto ilanilọye fun awọn oluworan.
Condotti ni eto naa yoo ni afihan imọ to lamilaaka bi ti ilẹ okeere fun igbadun awọn ọmọ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Others
Bakan naa ni wọn fikun un pe eto naa yoo jẹ itunu fun awọn eniyan lẹyin ipenija ajakalẹ aarun Coronavirus to mi gbogbo eniyan titi.
Lara awọn olukopa to ti jawe olubori ninu eto naa ni Osazuwa Osahon Daniels - N5 million (2009), Aroma Ufodike Chimuanya - N10 million (2009), Babatunde Oni Oladipo - N5 million (2010), Nnaemeka Ubaekwena - N5 million (2012).



















