Live Eviction show BBNaija 2021 :WhiteMoney ló gbé igbá orókè nínú ètò ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà ọdún 2021

Ètò ẹlẹ́gbọ́n àgbà ọdún 2021 ti wa o si ti parí lẹyin ọṣẹ mẹwaa tí gbogbo àwọn ọdọ ti kojú mọ ètò náàs lóri amóhúnmáwòrán.
Whitemoney ni oludije to gbegba oroke ninu idije BBNaija eyi to jẹ ipele ikẹfa iru rẹ.
Ibeere ti ọpọ n beere ni pe ta ni Whitemoney naa?
- "Who wants to be a Milionaire'' tí pada sí orí afẹ́fẹ́! ẹyin olólùfẹ́ rẹ̀, ẹ kú oríire!
- Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Bolanle afurasí adigunjalè làyájọ́ òmìnira Nàìjíríà
- Kí ní ọ̀rọ̀ mí tí ẹ mú bẹnu lórí onimọ̀ àyẹ̀wò 'Forensic' tí ilé ẹjọ́ pè kó wá jẹ́rìí?- Yomi Fabiyi
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
Ta ni Whitemoney to gba aadọrun un miliọnu lọ ninu idije BB Naija?
Orukọ abisọ whitemoney ni Hazel Oyeye Onou.
Oun lo figagbaga pẹlu awọn to le ni ogun ninu ile ẹlẹgbọn ọn agba ti ọdun 2021 ti wọn pe ni 'shine Ya Eye'
Whitemoney jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn.
Omo bibi ipinlẹ enugu ni ila oorun guusu Naijiria ni.
O jẹ oniṣowo bata lati ilẹ okeere ati ni Naijiria.
O ti dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijira fun atilẹyin wọn fun oun.
Sùgbọ́n lẹ́yìn ò rẹyin Hazel Oyeze Onou ti gbogbo eniyan mọ si Whitemoney ló gbegba oroke fun ti eto ọdun yii ti Roseline Omokhoa Afije ti gbogbo eniyan mọ si Liquorose si gba ipo keji.
Whitemoney da oju awọn ọmọ ile ogun to u bolẹ lati gbegba oroke ti ọdun yii, o jẹ́ ẹni kẹfa ti yuoo jawee olubori ninu eto naa lati igba ti o ti bẹrẹ.
- Bí mo ṣe ná $88,521 lórí, igún, ìfun eerin, agbárí kìnnìhún láti gbé ẹbọ
- Ìdí tí ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn fi ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn lórí ẹ̀tọ́ láti ṣẹ́yún
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- Ọlọ́pàá tají padà lẹ́yìn 'Coma' oṣù mẹ́sàán, 'sack letter' làwọn ọ̀gá rẹ̀ fi kíi káàbọ̀
Ni bayii o ti darapọ mọ awọn to ti gbegba oroke eto nas saaju bi: Katung Aduwakwey to gba ti saa akọkọ eto naa, lọdun 2006, Efe Ejeba (2017), Miracle Ikechukwu (2018) ,Mercy Eke (2019), àti Laycon lọdun 2020.
Whitemoney jẹ onisowo ti o si ti jẹ ki gbogbo eniyan mọ lati ibẹrẹ pe, owo ni oun yoo ṣe.
Whitemoney lo gbe igbá orókè nínú ètò ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà ọdún 2021
Ẹbun aadọrun mílọnu naa ni owo ọgbọn miliọnu naira, Owo ninu apo Abeg digital ati bitcoin lati ọwọ Patricia, ile oni yara meji, Mọto ayọkẹlẹ igbalode ati irina ajo lo si Dubai.

Live Eviction show BBNaija 2021 : Emmanuel, Angel, Cross ati Pere ti lọ ile
Nínú ètò ilé ẹlẹgbọn àgbà tó n lọ lọ́wọ́, àwọn mẹ́rin ni wọ́n ti kíuro nínú ilé báyiì i ìjàkadi si kù sí ààrín White Money ati Liquorose
Tani yóò gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́rún Nàìrà lọ le.

Eto ti alẹ́ yìí kọ́ka ran Emmanuel lọ ile, ti ọ̀pọ̀ sì n sọ pé, nǹkan ti o tọ ni ati pe, ore-ọfẹ ni Emmanuel ni lati wa ninu ile élégbọn agba titi di asiko tí o lọ.
Eto sin nlọ lọwọ sugbọn a ko ti mọ ẹni ti yoo gba ẹgbun tabua yii lọle
Lasiko ti Pere n lọ o ní ọ̀rọ̀ kan ti òn yoo sọ ni pe oun nifẹ Maria
Òní ní BBNaija 2021 ń parí, tani yóò fí 90m naira sara rindin?

Oríṣun àwòrán, BBNaija
Awọn ololufẹ ere idaraya ori tẹlifisọn ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Big Brother Naija'' n foju sọna fun opin ere naa ti yoo waye ni Ọjọ Aiku, Ọjọ Kẹta, Osu Kẹwaa, ọdun 2021.
Oni to jẹ opin Big Brother Naija naa ni o pe ọjọ mejilelaadọrin ti awọn ọmọ ile Big Brother ti lo ninu ile naa ni saa yii.
Amọ, eniyan kan ninu awọn oludije mẹfa to lu ninu awọn mẹrindinlọgbọn to bẹrẹ lati ibẹrẹ ni yoo gbe igba oroke ni oni.
Awọn mẹfa to ku naa ni Whitemoney, Liquorose, Pere, Cross, Angel ati Emmanuel, bio tilẹ jẹpe oju wa lara Whitemoney ati Liquorose gẹgẹ bi ẹni ti yoo yege julọ nitori bi awọn oluworan ṣe fẹran wọn si.
- Orí afárá ni mo sì ti ń wẹ̀ l'Ojuelegba, ilé àkọ́kù ni mò ń gbé tẹ́lẹ̀ - Whitemoney
- Ẹ bá wa bẹ̀ BB Naija kò bẹ̀rẹ̀ Big Mama nàá, mo ṣetán láti ṣí ara sílẹ̀ nítorí owó - Fali Werepe
- Whitemoney, Queen, Pere, Angel, Boma kọjú ìjà sí ara wọn nínú ilé Big Brother Naija
- Láyé! Mi ò lè wo BBNaija! Ìdí tí mo fi gbá ètò náà ní "blocking" tí ẹnikẹ́ni ò gbudọ̀ wò ó nílé mi rèé'
Kini eto Big Brother Naija da le lori?
Ere idaraya lori ẹrọ tẹlifisọn ni Big Brother Naija, ti awọn ileeṣẹ amohunmaworan kan si n ṣe agbatẹru fun un.
Ohun ti o ma n ṣẹlẹ ni Big Brother ni pe awọn eniyan yoo jọ gbepọ ninu ile kan naa fun ọjọ mejilelaadọrin, lai ni anfaani si ohun to n ṣẹlẹ ni agbaye, to fi mọ aini anafaani si ẹrọ ilewọ wọn.
Awọn alakoso eto naa ma n lo ẹrọ amọhun ati amaworan lati fi tọ paṣẹ awọn ọmọ ile naa fun wakati merinlelogun ọjọ lai yọ ẹnikẹni silẹ.
Bakan naa ni Big Brother ma n gbe iṣẹ fun wọn lati ṣe, eleyii to ni owo lori.
Ọṣọọṣẹ si ni wọn ma n dinku lẹyin ti awọn ara ile ba dibo yan ẹni ti wọn fẹ ko kuro ninu ile ni ọṣẹ naa.
Ni oni to jẹ ọjọ to gbẹyin naa ni awọn eniyan yoo tun dibo fun ẹni ti wọn fẹ ko gbe igba oroke ninu eto naa.
Kini yoo ṣẹlẹ loni ni ọjọ ti Big Brother Naija 2021 yoo wa sopin?
Gẹgẹ bi awọn adari eto naa ṣe sọ, Ọjọ Aiku, Ọjọ Kẹta, Osu Kẹwaa, ọdun 2021 ni yoo pari.
Awọn eniyan si le wo aṣekagba naa ni ori ikanni ayelujara Dstv channel 198, GOtv channel 29 (Channel 129 for Ghana and Channel 329 for Uganda).
Aago meje asalẹ oni ni yoo waye ni ori ikanni BBNaija ti awọn eniyan ti n wo.

Oríṣun àwòrán, BBNaija
Ebuka Obi -Uchendu ni yoo tun se atọkun eto naa loni pẹlu awọn amuludun olorin lati orilẹede Naijiria ti yoo ma a da awọn eniyan ni ara ya.
Bi o tilẹ jẹpe wọn ko i tii fi idi rẹ mulẹ, o ṣeeṣe ki awọn ọmọ ile Big Brother Naija ti wọn ti le lọ pẹjọ pọ si ibi aṣekagba naa loni.
Kini iwuri to wa fun ẹni to ba gbe igba oroke ni saa yii?
Ẹnikẹni to ba gbegba oroke ninu awọn mẹfa to ku to n dije loni yoo gba aadọrun miliọnu naira, N90M lo si ile fi ṣe ara rindin.
Awọn ohun to wa ninu aadọrun miliọnu naira naa ni ọgbọn miliọnu naira ni iye owo amudani, ti wọn yoo tun ni owo ẹrọ ayelujara Abeg digital wallet, bitcoins lati ọwọ onigbọwọ wọn Patricia.
Bakan naa ni ẹni ọhun yoo gba ẹbun ile olojule meji (two-bedroom apartment) lati ọwọ RevolutionPlus Property.
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- Muinat Ilebiyi Imeko classroom collapse: Fún ọjọ́ márùn-ún, a ò rí tísà ọmọ mi tó kú kó yọjú sí wa
To fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ a top of di range SUV ti Innoson Motors ti orilẹede Naijiria ṣe.
Ko tan si bẹ, ẹni to ba jawe olubori yoo tun rin irinajo igbafẹ fun eniyan meji, eleyii ti Travelbeta yoo ṣe agbatẹru rẹ.
Awọn to ti jawe olubori ni eto BBNaija ṣẹyin re e...
- Big Brother Nigeria 1 Katung Aduwak $100,000
- Big Brother Naija 2 Efe Ejeba N25,000,000
- Big Brother Naija 3 Miracle Igbokwe N45,000,000
- Big Brother Naija 4 Mercy Eke N60,000,000
- Big Brother Naija 5 Olamilekan Agbeleshe N85,000,000


















