BBN Whitemoney: Láàrin ọ̀sẹ̀ kan lọ́dún 2015 ni nǹkan yípadà fún mi lẹ́yìn tí mo jìyà fún ọ̀pọ̀ ọdún

Oríṣun àwòrán, whitemoney__
Awọn agba ni oju ẹni maa la, yoo ri to, oju ẹni maa la, yoo ri iyọnu nitori ọla gan ni iyọnu.
Ọpọ eeyan ti irawọ wọn n tan lonii, lo ti la oriṣiriṣi ipenija kọja, ti awọn funra wọn gan ko lero pe o ṣeeṣe ki wọn bọ ninu rẹ.
Pupọ awọn eeyan bẹẹ lo mori bọ ninu inira wọn, ti wọn si lẹnu ọpẹ ni ikẹyin.
Irufẹ eeyan bẹẹ ni ọkan lara awọn olukopa ninu idije ẹlẹgbọn agba, Big Brother Naija, iyẹn Hazel Onou, ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Whitemoney.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sapara-Williams: Ọmọ Oòduà tó kọ́kọ́ dábàá pé kí ilẹ̀ Yorùbá dúró lábẹ́ àkóso kan ṣoṣo
- Wo ànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Ẹ̀yin agbébọn, ajínigbé àti ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀, ìjọba mi yóò fimú yín dárin - Buhari
- Wo ìye owó tí lítà epo pẹtirólú kan yóò jẹ́ lẹ́yìn ìpàdé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba
- "Inú òjò ní mo sùn fún wákàtí 48 pẹ̀lú ebi ní àhámọ́ ajinigbé"
- Àwọn ajagungbalẹ̀ gba ilẹ̀ tó yẹ fún kíkọ́ iléèwé girama ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Wo oúnjẹ́ àdàpọ̀ mẹ́fà tó lè di májèlé nínú àgọ́ ara
- A kú oríire! Oró agbọ́n leè wo àìsàn jẹjẹrẹ ọmú sàn, wo ohun tí wàá lò pọ̀ mọ́ra wọn
- Ẹ fura o! Àjọ elétò ìdìbò INEC kígbe síta lórí ọ̀nà tuntun tí àwọn kan fẹ́ gbà ṣọṣẹ́ fún ìbò 2023
- Ọpọ Obìnrin ní inú wọn kún fún ìbànújẹ lásìkò yìí nítorí wọn kò yó ìfẹ lónà tó yẹ- Tonto Dikeh
Whitemoney ṣalaye ninu ile naa fun awọn olukopa ẹgbẹ rẹ, bi igbe aye rẹ ṣe ri latẹyinwa ko to de ipo to wa lonii.

Oríṣun àwòrán, @whitemoney__
Gẹgẹ bii ohun ti Whitemoney sọ, abẹ afara ati ile kan ti wọn ko tii kọ tan ni oun n gbe ni adugbo Makinde to wa ni Ojuelegba, iyẹn nipinlẹ Eko lọdun 2013.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O ṣalaye pe ori afara Ojuelegba naa ni oun ti maa n wẹ, ti awọn eeyan a si maa wo oun ni gbagba ita.
O sọ siwaju si pe oun ko ni anfani si ile iwẹ tabi ile igbọnsẹ, koda o ni inu ọra ni oun maa n ṣe igbọnsẹ si lọdun naa lọhun, ki Eledua to gbọ adura oun.
Whitemoney sọ pe "Laarin ọsẹ kan ni nnkan yipada si rere fun mi, ti mo si pinnu lati tẹẹ pa si Eko."
"Lọdun naa lọhun, ọkan lara awọn mọlẹbi mi lo gba mi sile, ṣugbọn ọdun 2015 ni ayipada si rere de ba mi."
Whitemoney teṣiwaju pe "Mo tọwọ bọwe adehun orin kikọ pẹlu ileeṣẹ kan, lati ibẹ lọ ni mo ti di ẹni to kuro labẹ afara, ti mo si di ẹni to nile, lẹyin naa ni mo ra ọkọ bọgini SUV tuntun."
O pari ọrọ rẹ pe, bo tilẹ jẹ pe o ni ọpọ eeyan ni ko mọ ohun ti oun ti la kọja sẹyin, ṣugbọn oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe aye oun ti yipada bayii.
Whitemoney jẹ ọkan lara awọn oludije BBNaija ti awọn eeyan fẹran nitori akitiyan ninuile naa, paapaa bo ṣe farajin lati maa se ounjẹ fun awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn le ni ogun.














