Àjọ elétò ìdìbò INEC ní àwọn kan gbé òfégè ojú òpó ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò síta yàtọ̀ sí ojúlówó ti INEC kéde

oṣiṣẹ ajọ INEC n ṣe iforusikọlẹ oludibo kan.

Oríṣun àwòrán, Inec

Ajọ eleto idibo ni Naijiria ti pariwo sita lori ayederu oju opo iforukọsilẹ ori ayelujara kan to wa nita.

Atẹjade kan ti alaga igbimọ iforukọsilẹ ati ilanilọyẹ awọn oludibo lajọ INEC, Festus Okoye fi sita ajọ INEC ni adirẹsi oju opo naa ni https://register.inec-pvc.online/ pẹlu abuda ti wọn pe ni https://bit.ly/INEC-PvcReg2021.

Atẹjade naa fa awọn ọmọ Naijiria gbogbo leti lati maṣe ko sọwọ awọn kọlọransi to foju pamọ sẹyin ayederu oju opo naa.

Bakan naa ni INEC ni awọn ko fun ajọ tabi ẹnikẹni ni aṣẹ lati ṣe iforukọsilẹ lori ayelujara lorukọ oun.

Ajọ naa wa fi kun un pe oju opo iforukọsilẹ ori ayelujara to jẹ ojulowo ti ajọ naa ni https://cvr.inecnigeria.org,

Irọrun wo ni iforukọsilẹ ori ayelujara ti INEC gbe kalẹ yoo mu ba awọn oludibo to fẹ forukọ silẹ?

Awọn oṣiṣẹ ajọ INEC n ṣe iforusikọlẹ oludibo kan.

Oríṣun àwòrán, Inec

Amọṣa alaga ajọ naa ti kọkọ ṣaaju kede agbekalẹ oju opo ayelujara kan silẹ fun awọnoludibo to ṣẹṣẹ fẹ forukọ silẹ lati lee ṣe bẹẹ lai si wọlukọlu lawọn ileeṣẹ ajọ INEC kaakiri orilẹede Naijiria paapaa lasiko ajakalẹ arun COVID-19 to gbode yii.

Ninu ọrọ kan ti alaga apapọ ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣalaye pe ara awọn igbesẹ ọgbọn atinuda ti ajọ naa gbe kalẹ niyi lati mu ki eto iforukọ silẹ awọn oludibo o mu irọrun dani, ki o si tun lee wa larọwọto awọn oludibo, ti yoo si mu eto naa jẹ awo rẹrin fawọn oludibo to fẹ dibo lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Wikipedia: Ẹ̀nìkan sọ fún mi pé iṣẹ́ ìdọ̀tí ni màá ṣe ni mo ṣe ń ta ìwé

Awọn wo lanfani naa wa fun ni yajoyajo?

Yats si awọn to ṣẹṣẹ fẹ dibo fun igba akọkọ to fẹ tipasẹ bẹẹ fi orukọ silẹ, awọn to ti forukọ silẹ tẹlẹ ṣugbọn ti wọn fẹ ṣe ayipada ibudo ibi ti wọn ti forukọ silẹ ati ti wọn ti lẹtọ ati le dibo naa yoo le lo anfani oju opo ayelujara yii lati ṣe eyi.