Masturbation: Ire ni àbí ibi fún ìlera ẹ̀dá?

Awọn eeyan kii ṣaba sọrọ nipa fifun ara ẹni ni adun ibalopọ, paapa ni gbangba.
Kii ṣe nilẹ Afirika nikan ni wọn ti ma n fi oju buruku wo o, bakan naa ni ọrọ ri ni awọn apa ibikan nilẹ India ati Asia.
Idi ni pe iwa idọti, nnkan ti eeyan ko gbọdọ danwo, ni wọn maa n pe e.
Ṣugbọn ṣa, o dabi ẹni pe 'masturbation' ni awọn anfaani kan to n ṣe fun ilera ẹda.
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
- Hadiza, ìyàwó Ààrẹ Shagari jáde láyé.
- Ẹ̀dà Delta Variant COVID-19 ń gbèrú síi ní Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ra abẹ́rẹ́ àjẹsára 176,000
- Ọba alayé kan àti gómìnà kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi, kí n tó fẹ́ Mr Lawal - Lizzy Anjorin
- Apostle Suleman lo ọlọ́pàá láti fi ìyà jẹ oníbàárà mi, ó fi sí àtìmọ́lé torí ọ̀rọ̀ tó sọ - Amòfin
- Aàrẹ Marcelo Rebelo de Sousa ẹni ọdùn 71 bẹ́ sómi láti dóòlà obìnrin méjì tó fẹ́ rì sómi
- Ẹ̀rọ CCTV tú àsírí ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀
Abajade iwadii wa re e:
Gẹgẹ bi Cynthia Fogoe, onimọ nipa ibalopọ ṣe sọ, fifun ara ẹni ni adun tabi itẹlọrun ibalopọ, ni iwulo to n ṣe fun ara.
O sọ fun akọroyin BBC, Mobeeb Azar, lasiko ifọrọwerọ kan pe, awọn anfaani bayii lo n fun ni:
- O ma n din aarẹ ara ku lati fun ara ni isinmi
- O ma n din ibẹru tabi aya jija ku
- O ma n ran awọn obinrin lọwọ lati ni imọ nipa ẹya ara wọn, ati nkan to le fun wọn ni adun ibalopọ
- O tun jẹ ọna lati ṣamulo ominira, nitori pe kii ṣe atọwọda

Bakan naa ni Dokita kan ni Naijiria,Chidinma Njoku, sọ pe:
- 'Masturbation' jẹ ọna ti eeyan le gba kọ ẹkọ nipa bi agọ ara rẹ ṣe ri
- Ko si ibẹru oyun nibẹ
- Ko fi bẹ ẹ si ewu lati ko arun ibalopọ
- O ma n jẹ ki awọn to n ṣe e sun daadaa
- Fun awọn obinrin kan, o ma n din irora ku fun wọn lasiko ti wọn ba n ṣe nkan oṣu
Amọ Njoku fikun un pe gbogbo nnkan to n dan kọ ni wura, ninu ọrọ titẹ ara ẹni lọrun fun ibalopọ.
Awọn abawọn tabi ewu to wa nibẹ nkọ?
Fogoe ṣalaye pe awọn ijamba kan wa ti iwa yii le ṣe fun awọn to ba n ṣe e.
Fun awọn ọkunrin to ba ma n se e, o ṣe e ṣe ko bẹrẹ sini nira fun wọn lati pẹ lori ibalopọ pẹlu obinrin.
Ti o ba n ṣe e ni gbogbo igba, n ṣe ni o n sọ fun ọpọlọ rẹ pe ọna kan ṣoṣo (masturbation) to wa niyẹn lati ni itura ibalopọ.
Eyi tun tumọ si pe, o le nira fun nnkan ọmọkunrin awọn ọkunrin kan lati dide tabi duro fun igba pipẹ lasiko ibalopọ.

Fagoe sọ pe, awọn ọkunrin kan ti ẹ le ma damira lẹyin ibalopọ.
Ko tan sibẹ o, iwadii ijinlẹ kan tun sọ pe, wiwo fidio ibalopọ - to ṣaba ma n waye pẹlu titẹ ara ẹni lọrun, ma n ni ipa ti ko dara lara ọpọlọ.
Wiwo awọn fidio yii tabi fifun ara ẹni ni adun ibalopọ, ma n mu adinku ba bi ibalopọ ṣe ma n wu ọkunrin si pẹlu iyawo tabi ọrẹbinrin wọn.

Oríṣun àwòrán, Other
Njẹ awọn obinrin ma n ṣe bẹ ẹ?
Iyalẹnu to wa nibẹ ni pe, ti ọpọ ba n ronu nipa 'masturbation', ọkunrin ni wọn ma n ro o si.
Ṣugbọn, Radhika Sanghani to jẹ akọroyin gba pe eyi ko ri bẹ ẹ.
O sọ pe "awọn obinrin ma n ṣe e, amọ wọn kii ṣaba sọrọ nipa rẹ".
Bakan naa lo sọ pe awọn obinrin kan ko ti ẹ jẹwọ ri pe awọ́n ma n se e tabi wọn ti ṣe e ri.
"Eyi jẹ ibanujẹ fun mi, nitori pe ọpọlọpọ obinrin ti ọjọ ori wọn le ni ogun ọdun, lo ni idalẹbi ati itiju to ma n tẹle ti wọn ba fi le sọ sita.
Paapa lati ọdọ ẹbi ati ile ijọsin wọn pẹlu.














