After Portugal President rescue: Aàrẹ Marcelo ṣàlàyé bó ṣe dóòlà ẹ̀mí wọ́n létí òkun Algarve

Aarẹ Rebelo de Sousa

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ orilẹ-ede Portugal Marcelo Rebelo de Sousa sare bẹ si omi okun lati doola ẹmi awon obinrin meji to fẹ bomi lọ ni eti okun Algarve lẹyin ti ọkọ oju omi wọn doju de.

Aarẹ naa, ẹni ọdun mọkanlelaadọrin to ba awọn akọroyin sọrọ ni Praia do Alvor, leti ọkun nibi ti o ni oun ti ri awọn obinrin meji kan ti wọn ja fitafita fun ẹmi wọn ninu omi.

Bẹẹ lo bẹ somi to luwẹ lọ doola wọn.

Ọkunrin miran naa tun luwẹ lati lọ ran wọn lọwọ pẹlu nigba ti ọkọ oju omi naa doju de.

Aarẹ Rebelo de Sousa

Oríṣun àwòrán, others

Leyin ti Aarẹ Marcelo Rebelo de Sousa ran awọn obinrin naa lọwọ tan lo salaye fun awọn akọroyin pe, ati eti okun ibomiran ni omi ti gbe awon eniyan naa wa.

O ni: "Ọwọ okun le gan an ni, omi naa wọ awọn obinrin oun sita,

O doju wọn bolẹ, wọn mu omi to pọ wọn o le yi oju ọkọ oju omi wọn pada, tabi ki wọn gun un,

Koda, wọn ko le luwẹ ni bi omi naa se lagbara to."

Aarẹ Rebelo de Sousa

Oríṣun àwòrán, others

Aàrẹ Marcelo Rebelo de Sousa ni ki awọn obinrin naa nilọ ki wọn maa sọra nigba miran

Gẹgẹ bi awọn akọroyin abẹle ṣe sọ, Aarẹ Rebelo de Sousa ti lọ fun isinmi ranpẹ ni eti okun Algarve gẹgẹ ọkan lara eto lati mu igbe larugẹ ba igbafẹ.

Àkọlé fídíò, Nítorí owú jíjẹ, ọkọ Zarka gé imú aya rẹ̀ dànú!

Eto igbafẹ ni laarija eto ọrọ aje Portugal, sugbọn ajakalẹ arun Coronavirus ti ko ba a.

Awọn olugbafẹ ilẹ Gẹẹsi lo saba maa n lọ isinmi nibẹ,

O kere tan, miliọnu mẹta awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi lo n lọ ibẹ lọdun.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu