Wo tuntun tó ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn òṣèré Yollywood bíi Femi Adebayo, Odunlade Adekola, Toyin Abraham, Funke Akindele lọ́sè̩ yìí

Odunlade, Jenifa ati Femi Adebayo n dara

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lọsẹ yii, o da bii pe awọn oṣere Yoruba naa ti n wọle pada sẹnu iṣẹ tiata wọn ni pẹrẹwu gẹgẹ bi ijọba naa ṣe bẹrẹ si ni ṣi awọn ibi kọọkan pada lẹyin isede oṣu gbọọrọ torii arun COVID-19.

Ọpọlọpọ sinima agbelewo lo ti n jade bo tilẹ jẹ wi pe lori ayelujara nikan naa lẹ ṣi ti le ri wọn wo bayii.

Awọn oṣere gangan ti n bọ sori itage pada bayii pẹlu oniruuru sinima to ni akọle awoyanu atawọn eto pataki mii to yatọ si sinima tawọn oṣere gbe ṣe laarin ọsẹ to kogba wọle lọ yii.

Oni gan ni Toyin Abraham, iya Ire pe ẹni ogoji ọdun laye Toyin Abraham pé 40, wo ohun márùn ún tó mú dá yàtọ̀ láàrín ogójì ọdún

Ọpọ eeyan lo ti n kii ku oriire lai yọ baba Ire gan an silẹ to ki Toyin ni oriki to pọ pẹlu adura ọjọ iwaju rere.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Toyin Abraham funra rẹ naa ki ara rẹ ku oriire pẹlu adura pe...

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ọṣẹ yii ninu aye Odunlade Adekọla:

Gbogbo ọsẹ yii ni ilumọọka oṣere, Odunlade Adekola fi n polowo ipadabọọ sinima rẹ, Saamu Alajọ eyi ti gbogbo eeyan n wari fun

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Loju opo instagram rẹ, lo ti n fun awọn eeyan ni itọwo kekeke ninu ẹkunrẹrẹ fiimu Saaamu Alajọ to jẹ sinima apanilẹrin.

Àkọlé fídíò, Nítorí owú jíjẹ, ọkọ Zarka gé imú aya rẹ̀ dànú!

Lọdọ Funke Akindele n kọ lọsẹ yii?

Lati ọsẹ to kọja ti Funke Akindele ti ṣe nkan ayọ onibẹta iyẹn ayẹyẹ ọdun igbeyawo oun ati ọkọ rẹ, ọjọ ibi rẹ bakan naa lo kede fiimu tuntun rẹ to gbe jade eyi to jẹ ipadabọ fiimu rẹ "Omo Ghetto".

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 4

Pẹlu awọn aworan to n fi sita lo ti ye ni pe ara ọtọ leyii bẹẹ si ni Funke Akindele gan an ninu sinima naa yatọ si eyi tẹẹ mọ ninu apa kinni Omo Ghetto.

Bẹẹ si ni o da bii pe ipa ti o ko ninu sinima eleyii tun yi lori ju ti akọkọ lọ.

Ninu aye Femi Adebayo, bẹbẹ jade lọsẹ yii:

Odu ni Femi Adebayo ninu agbo awọn oṣere Yoruba toun naa si ti n ṣe itọwo awọn fiimu to fẹ gbe jade.

Skip Instagram post, 5
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 5

Oṣere ọmọ Ilorin yii ti baba rẹ ati aburo rẹ naa jẹ akẹgbẹ fun un ninu iṣẹ fiimu ti n fi oriṣiriṣi aworan sinima ara ọtọ meji kan sita - "Ẹsin Agbere" eyi to ṣe lati fi tu aṣiri awọn aafaa to n ṣe lodi si bi o ṣe yẹ ki wọn maa ṣe ẹsin ati "Sisi".

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Saka, Sunkanmi Omobolanle àtàwọn òṣèré sinimá míràn lọ́sẹ̀ to kọja

Eyi ni awọn iroyin nipa awọn oṣere sinima to waye laarin ọsẹ to kọja.

Saka ati Kelvin Ikeduba ṣe ọjọ Ibi

Ṣe ẹ ranti agba oṣere "Saka I don port" alawada ninu ọpọ ere agbelewo ṣe ọjọ ibi ni Ọjọbọ, Ogunjọ osu kẹjọ ọdun yii.

Ni ọdun 1963 ni wọn bi alagba Afeez Oyetoro ti ọpọ mọ si Saka ninu ere agbelewo.

Afeez Oyetoro

Oríṣun àwòrán, Brodashaggi

Ilu isẹyin ni wọn si bii si ni ipinlẹ Ọyọ.

Lọwọ yii, olukọni ni ni ileewe ẹkọṣẹ olukọni agba, Adeniran Ogunsanya College of Education ni ilu Eko.

Ọpọlọpọ awọn eekan oṣere ni wọn ki alagba naa ku oriire ayẹyẹ orikadun.

Skip Instagram post, 6
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 6

Yatọ si alagba Saka, eekan oṣere miran, Kelvin Idkeduba pẹlu ṣe ọjọ Ibi rẹ lọsẹ yii.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ ni ọjọ ibi Kelvin ni tirẹ.

Ni ọdun 1976 ni wọn bi Kelvin Ikeduba lagbegbe Ebute Metta ni ilu Eko.

Bi o ṣe n ṣe ere ede Yoruba naa lo n ṣe sinima ede Oyinbo ati Igbo.

Lara awọn eekan to kii ku ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ni Mercy Aigbe, Sunkanmi Ọmọbọlanle

Skip Instagram post, 7
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 7

Sunkanmi omobolanle

Oríṣun àwòrán, Sunkanmi omobolanle

Sunkanmi Ọmọbọlanle gbalejo ọmọ tuntun

Eekan oṣere tiata, Sunkanmi Ọmọbọlanle, ọmọ gbajugbaja oṣere, Sunday Ọmọbọlanle ti ọpọ mọ si Pappy Luwẹ ti gbalejo ọmọ tuntun ni aarin ọsẹ yii.

Sunkanmi to fi fọto ati ikede ibi ọmọ rẹ si oju opo Instagram rẹ ni Aderinsọla ni wọn sọ orukọ ọmọ naa.

Skip Instagram post, 8
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 8

omotala_jalade ekehinde

Oríṣun àwòrán, omotala_jalade

Awọn ololufẹ Omọtọla Ekeinde ti ọpọlọpọ mọ si Ọmọsexy gbadura fun un lẹyin to ko COVID-19

Lati igba ti o kede pe oun ti ko aarun COVID-19 laipẹ yii, awọn ololufẹ agba oṣere sinima naa ti n ki i pẹlu adura pe yoo ye arun naa ati pe piri lolongo rẹ yoo ji lẹyin o rẹyin arun naa.

Awọn ololufẹ rẹ ya bo oju opo Instagram rẹ ti wọn si n fi adura ati ikini ranṣẹ sii.

Kumbalee

Oríṣun àwòrán, others

Ikú Williams Aanuoluwa lágbo òṣèré hú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ síta

Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá kọjú ìjà síra wọn lórí ìdárò akẹẹgbẹ́ wọn tó kú

Awaye ku ko si, Ọba oke mase jẹ ka fi ọjọ ọlọjọ lọ ni.

Ọfọ nla ti sẹ ni agbo ere tiata ni ọjọ Aje, eyi to dori awọn irawọ osere kodo.

Iku tun to wọ agbo awọn oṣere tiata nilẹ yii naa, nigba ti yoo si fi jade, ọkan lara awọn aṣaraloge (Makeup Artist) lẹka ere tiata Yoruba, lo mu lọ.

Orukọ oloogbe naa ni Williams Anuoluwapọ, ti ọpọ mọ si Kumbalee.

Sugbọn awọn ọrọ ti awọn osere kan n sọ lori iku ọkunrin naa ati awọn eeyan to n sọfọ rẹ, n kọ ni lominu.

Eyi si lo mu kawọn osere tiata kan fajuro lori ohun tawọn akẹẹgbẹ wọn n kọ nipa iku ọkunrin naa, ti wọn si n gbena woju ara wọn.

Sugbọn ọrọ aro ti ọpọ wọn n kọ soju opo Instagram wọn lo safihan pe, wọn n paroko ọrọ ransẹ saarin ara wọn, to si ni itumọ to jinlẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá