Kano Chained Man: Ìdáǹdé dé fún bàbá táwọn ẹbí rẹ so mọlẹ fun ọgbọn ọdun

Oríṣun àwòrán, Human Rights Network
Ni ilu Kano lẹẹkan si, itura ti de ba baba ẹni ọdun marundinlọgọta kan, ti wọn fi ẹwọn so mọlẹ fun ọgbọn ọdun.
Gẹgẹ bi ajafẹtọ ilu kan, Shuaibu Sani ti fidi rẹ mulẹ fun BBC, awọn ọlọpaa lo tu ọkunrin naa silẹ, ẹni ti awọn ẹbi rẹ so mọlẹ lori ẹsun pe o ni arun ọpọlọ.
Shuaibu ni "Iya jẹ ọkunrin naa fun ọpọlọpọ ọdun, ti wsn so so mọ ara igi pẹlu irin ninu yara kan ti ko ni ilẹkun tabi ferese."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù
- Làásìgbò òṣèlú wáyé nílùú Ondo, ọ̀pọ̀ èèyàn fara pa
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé oṣù ojú ọ̀run táwọn Mùsùlùmí ń lò ti wà saájú Ànọ́bì?
- Ẹ ṣí ilé ìwé padà ní Áfíríkà torí ọjọ́ iwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yín - WHO, UNICEF
- Háà, èyí tún ga! Wó ọkùnrin táwọn obìnrin fipá bá lòpọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejì
O ni bi oun se gbọ nipa igbesẹ tawọn ọlọpaa n gbe lati doola ọkunrin naa, ni oun dara pọ mọ wọn lati wa itura fun ninu ile kan to wa nilu Rogo.

Oríṣun àwòrán, Human Rights Network
"Wọn lo ni arun ọpọlọ, to si n huwa ipa amọ dipo ki baba rẹ lọ tọju rẹ lati ọdun 1990, se lo pinnu lati ti ọmọ rẹ mọle."
Shuaibu tẹsiwaju pe "nigba ti baba rẹ ku lọdun diẹ sẹyin, awọn aburo rẹ ọkunrin meji tun tẹsiwaju lati maa tii mọle sugbọn loni, o ti gba ominira.
Koda, awọn aladugbo wọn gan mọ nipa isẹlẹ naa, ti wọn si dide lati ran ọkunrin naa lọwọ."
Lọwọlọwọ bayii, o ni ọkunrin naa ti wa nile iwosan ijọba to wa nilu Rodo, nibi to ti n gba itọju, tawọn ọlọpaa si n fi ọrọ wa awọn aburo rẹ lẹnu wo.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nilu Kano, abdullahi Haruna naa fidi idoola ẹmi yii mulẹ fun BBC, to si ni iwadi n lọ lọwọ.
- Bí ìyàwó rẹ bá lóyún tàbí bímọ ní ìpínlẹ̀ Oyo, wo bí o ti ṣe lé gba ìsinmi ìtọ́mọ (Paternity leave)
- Ẹ̀bùn #500,000 wà fún ẹni tọ bá ba wa rí afurasí ikú Akinyẹle tó sọnù- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Wo àmúyẹ kí o tó lè di ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà pẹ̀lú fọ́ọ́mù tó jáde yìí
- Ṣé òótọ́ ni pé ìgbẹ́ erin le è wo arùn Coronavirus sàn?
- Wo ìdí tí Osun fi kede ìsinmi fún ọdún ìṣẹ̀ṣe, tàwọn ìpínlẹ̀ yókù kò dáhùn,
O ni igba kẹta ree tileesẹ ọlspaa ipinlẹ Kano yoo gunle eto idoola ẹmi fun awọn eeyan ti wọn so mọlẹ fun ọjọ pipẹ bii iru eyi.
Bí ọwọ́ ọlọ́pàá Sharia Kano ṣé tẹ ọkùnrin 26 tó mura bi obìnrin

Ọwọ ọlọpaa Ṣẹria ti wọn pe ni 'Hisbah Police' ti tẹ awọn ọkunrin mẹrindinlọgbọn kan ti wọn mura bi obinrin ni ilu Kano.
'Yan Daudu' lorukọ tawọn eeyan ma n pe iru awọn ọkunrin bẹẹ ni ilẹ ariwa.
Igbakeji ọga awọn ọlọpaa Sharia ni Kano, Mallam Tasiu sọ pe ọwọ tẹ awọn ọkunrin naa nibi apejẹ ọjọ ibi ọkan ninu wọn ladugbo Badawa ni ilu Kano.
O ṣalaye pe ''Iroyin to tẹ wa lọwọ pe wọn ṣe apejẹ ọjọ ibi ọkan lara wọn lo mu ki awọn eeyan wa tara ṣaṣa lọ si bẹ.
Ohun adojuti ni ki awọn ọkunrin maa hu iru iwa ka maa mura bi obinrin''
Tasiu fi kun un pe "Awọn yoo fi wọn si ahamọ titi tawọn obi wn yoo fi yọju siwa. A ti ṣe iwaasu fun wọn ti a si ti parọwa si wọn lati maa kirun.Ti awọn obi wọn ba de, a o tu wọn silẹ''
Ọkan lara awọn ti wọn mu ṣugbọn ti ko fẹ sọ orukọ rẹ fakọroyin sọ pe ọrẹ oun lo pe oun wa si ibi apejẹ naa ki ọwọ palaba awọn to ṣegi.
"Ọlọjọ ibi kii ṣe ọrẹ mi, ọrẹ mi lo ni ki n sin oun kalọ. Bi mo ba mọ pe iru nkan ti yoo ṣẹlẹ re e, mi o ba ma yọju. Kete ti ẹni to n ṣe ọjọ ibi ri awọn ọlọpaa Hisbah lo fo iganna salọ''
O tun sọ pe ''wọn ti ṣe waasi fun wa, a si ti ki irun Rakaah ogoji lati igba ti wọn ti mu wa. Mo kabamọ ohun to ṣẹlẹ .Mi o si ni ṣe bẹẹ mọ pẹlu ogo Ọlọrun''
MK Adam to jẹ agbẹnusọ awọn ajafẹtọmọniyan ni Kano sọ pe lopin igba tawọn ọkunrin ti wọn mu yi ti tasẹ agẹrẹ sofin, awọn ko le ṣe iranwọ kankan fun wọn.
"Awujọ kọọkan ni o ni ofin ti rẹ. Tohun ti pe awọn ọmọ iya wa lawọn ti Hisbah mu yi, ofin Kano lodi si iwa ti wọn hu yi.
Arọwa mi si wọn ni ki ijọba wa ọna lati ṣayipada wọn ki wọn baa le di eeyan daada lawujọ''
Lati ọdun 2001 ni ofin Sharia ti fẹsẹ rinlẹ ni Kano ti awọn ọlọpaa Hisbah si ni agbara lati mu awọn to ba ṣe ohun to tako ofin Islam.














