World Isese Day: Àwọn oníṣẹ̀ṣe ṣàlàyé pàtàkì ọdún ìṣẹ̀ṣe àti ìdí tí ìjọba fi gbọdọ̀ kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ bí àwọn ọdún ẹ̀sìn míràn

Awọn oniṣẹṣe n ki alaafin oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin oyo

Ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun ni awọn ẹlẹsin abalaye ya sọtọ fun ayajọ ọdun iṣẹṣe lati ṣajọyọ ẹsin abalaye lagbaye.

Awọn agba awo ni ilẹ Yoruba ti sọ ọ di mimọ pe ọdun to yẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba o mu ni koko.

Gẹgẹ bi awọn agba awo to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣe sọ, ọdun iṣẹṣẹ jẹ ọdun iranti ipilẹ, ori, ati Olodumare.

Ninu ọrọ tirẹ, Babalawo Jogodo ni ọdun naa ni wọn fi n ranti iṣẹṣe ilẹ Yoruba ni lati dupẹ lọwọ Olodumare.

Awo Jogodo ni awọn ijọba nilo lati tubọ ṣe atilẹyin fun ọdun iṣẹṣe naa nitori ohun ni o n mu iranti wa fun awọn ọmọ karọ o jiire lati mọ pataki wọn ni orilẹ agbaye.

Babalawo Jongodo ni iṣẹṣe ni gbongbo eeniyan ati pe o dara ki a mu imọ nipa ọdun naa kọ awọn ewe yoo mu ki ato ati idurodeede wa lawujọ; yoo si din awọn iwa kotọ gbogbo ku lawujọ.

Ninu ọrọ tirẹ, Akọda Awo ṣalaye pe awọn obi, ori, olodumare ni iṣẹṣe ati pe aimọkan lo n ṣe awọn to n ro pe idibajẹ ati iwa okunkun ni.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Ipinlẹ Ọṣun nikan ni wọn ti n kede ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati fi ṣe ajọyọ ajọdun naa.

Nibayii naa, awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ọyọ ti ke si gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde pe ko kede sjọ ajọdun iṣẹṣe gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Ni aafin olubadan ti ilẹ Ibadan lawọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ọyọ korajọpọ si lati ṣe ayajọ ọdun iṣẹṣe ti ọdun yii ni ipinlẹ Ọyọ.

Aarẹ Iṣẹṣe ti ipinlẹ Ọyọ, Oloye Omikẹmi Egbẹlade ni iṣejọba gomina Abiọla Ajimọbi ti ja awọn oniṣẹṣe ni tanmọn ọn nipa kikọ lati kede isinmi lẹnu iṣẹ fun sisami ayajọ ọdun iṣẹṣe lagbaye.

Saaju ni ileegbimọ aṣofin ni ipinlẹ naa ti buwọlu ofin to rọgba yii ka ati pe igbagbọ awọn ni pe iṣejọba gomina Seyi Makinde ko ni tọ ipasẹ rẹ.

Awọn to n bọ Sango

Makinde, jọ̀ọ́ kéde Aug 20 ọdọọdún bíi ọjọ́ ìsinmi fún ìṣẹ̀ṣe - Àwọn oníṣẹ̀ṣe Ọyọ

Yoruba ni tẹni ba dakẹ, tara rẹ maa n baa dakẹ ni.

Eyi lo mu ki awọn ẹlẹsin ibilẹ yika ipinlẹ Ọyọ fi n rawọ ẹbẹ si gomina Seyi Makinde lati ya Ogunjọ osu Kẹjọ ọdọọdun sọtọ gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu isẹ fun ayajọ ọdun awọn onisẹse.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn onisẹse naa, ti wọn korajọpọ si abẹ aburada ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Traditional Religious Worshippers Association Of Nigeria (TRAWASSO) parọwa naa lasiko ti wọn ls se ago laafin si Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji ni aafin rẹ lati fi sami ọdun Isẹse ti ọdun yii.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn onisẹse naa, Akọda Awo tilẹ Ibadan, Oloye Ifalere Ọdẹgbọla ni o ti le ni ọdun meji ti awọn ti gbe ibeere naa siwaju ijọba to kogba wọle.

Amọ o ni gomina ana, Abiọla Ajimọbi ko fontẹ lu ibeere awọn, ti wọn si n rọ ijọba to wa lode nipinlẹ Ọyọ bayii, labẹ gomina Seyi Makinde lati dahun si ibeere naa, gẹgẹ bi akẹẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Ọsun ti se.

Awọn to n bọ Ogun

O ni o yẹ ka jẹ ki awọn araalu mọ pe Isẹse lagba, ayajọ Isẹse yii si ni wọn yoo lo lati gbakanse adura si Ọlọrun ati awọn Alalẹ, bẹẹ si ni Orunmila lo kọkọ fi ipilẹ ilana isẹse yii lelẹ saaju ẹsin Musulumi ati ti Kristiẹni, nitori gbogbo ẹlẹsin lo n tọpasẹ ara wọn de idi ẹsin isẹse.