Wọle Ṣoyinka: Ẹ máṣe gba gbogbo ohun tẹ bá rí lórí ayélujára gbọ́ nípa mi

Oríṣun àwòrán, @akhirebhulu
Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti sọ fun ijọba apapọ pe ko ye fi awọn oṣiṣẹ eleto aabo dunkoko mọ awọn Naijiria mọ.
Ọjọgbọn Ṣoyinka ni iwa ki awọn agbofinro ma halẹ mọ awọn eeyan nibi ti wọn ba ti n takurọsọ, ku diẹ kaato.
Ṣoyinka sọrọ yii niluu Badagry nibi to ti lọ ṣi iṣẹ ọna kan to nii ṣe pẹlu ayajọ ọjọ ibi rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdẹ̀ra dé, Gẹnẹrátọ̀ tó ń lo omi dé, a bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn
- "Ojú wa rí tó ní Egypt, bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ wá lọ́mú, ni wọ́n ń gbá wa ní ìdí"
- Ọlọ́wọ̀ tìlú Ọ̀wọ̀ tuntun gorí ìtẹ́, idà àlááfìà ló mú ní Ìpèbí
- Á máa ṣíjú àánú wo ẹlẹ́wọ̀n láti mú àdínkù bá ọgbà ẹ̀wọ̀n - Ìjọba Ọyọ
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
Ọjọgbọn Ṣoyinka sọ pe, nigba ku gba ti ijọba ba n fi awọn ologun, ọlọpaa atawọn ọtẹlẹmuyẹ dunkoko mọ ara ilu, o tumọ si pe ijọba n bẹru ni.
O fi kun ọrọ rẹ pe, iru igbesẹ bẹẹ maa n ṣe adinku eeyan gẹgẹ bi ẹlẹran ara nitori o fihan pe, ijọba ko fẹ gbọ ohun ti ara ilu n wi ni.
Bẹẹ ba gbagbe, lọjọ Aje ọsẹ to lọ ni Ikeja niluu Eko lawọn ologun, ọlọpaa ati ọtẹlẹmuyẹ ti gbọngan kan pa, eyi tawọn ajafẹtọ ọmọniyan bii Ṣoyinka, agbẹjọro Femi Falana atawọn eeyan miran, ti fẹ ṣe apero.

Oríṣun àwòrán, @akhirebhulu
Ṣọyinka wa rọ ijọba atawọn oṣiṣẹ eleto aabo lati jawọ ninu apọn ti o yọ, ki wọn da omi ila kana.
Ọjọgbọn Ṣoyinka tun rọ awọn ọmọ Naijiria pe, ki wọn mase gba gbogbo iroyin ti wọn ri lori ayelujara gbọ.
O ṣalaye pe, ewu to wa ninu iroyin ori ayelujara pọ nitori ni iṣẹju akan ni yoo tan kalẹ kaakiri.
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Fayemi fojú Alufa to fipa bá ọmọde lòpọ̀ síta l'Ekiti
- 'El-Zakzaky lè má láńfààní láti lọ gba ìtọ́jú mọ́ lókè òkun'
- Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Mercy Aigbe lórí bó ṣe ki Adeniyi Johnson
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- N30,000 ni mo gbà fún orí, ọwọ́ àti ẹran ara wòlíì Bosede - Kayeefi
Ṣoyinka ni ọpọ igba lawọn eeyan maa n lo orukọ ati fọto oun fun iroyin lori ayelujara, nigba t'oun o tiẹ sọrọ kankan.












