Ọlọ́wọ̀: Ayẹyẹ ìgbadé ń bọ̀ ní ọjọ́ mẹ́tàdínlógún sí àsìkò yìí

Oríṣun àwòrán, @juwon2017
Ori nii gbe ni, taa fi n dade owo, ori nii gbe ni, taa fi n tẹ ọpa ilẹkẹ, ori naa nii gbe ni taa fi n gori itẹ awọn baba nla ẹni.
Ori ti gbe Ọmọọba tẹlẹ, Gbadegẹsin Ogunoye, to si ti gori itẹ awọn baba nla rẹ, oun si ni Ọlọwọ ti ilu Ọwọ tuntun bayii lẹyin awọn etutu ti wọn ti se fun ni Ipebi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bẹẹba gbagbe, laipẹ yii ni awọn afọbajẹ kede pe wọn yan Ọmọọba Ogunoye gẹgẹ bii Ọlọwọ tuntun, to si ti wa ni Ipebi lati igba naa, ko to wa jade sita lọjọ Ẹti, to si gun ori itẹ awọn baba nla rẹ.
Ọba Ogunoye yii, tii se Ọlọwọ tilu Ọwọ kẹtalelọgbọn, ni ayẹyẹ etutu jijade sita rẹ bẹrẹ ni kutu hai ọjọ Ẹti, eyi to se oju ogunlọgọ awọn ọmọ ilu naa.

Oríṣun àwòrán, @juwon2017
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lasiko yiyọju ọba sita naa, Ojumu tilu Ọwọ, Oloye Ọlanrewaju Famakinwa salaye pe o se dandan ki awọn se awọn etutu naa gẹgẹ bii asa ati ise ilu Ọwọ ti laa kalẹ.
Famakinwa ni ida alaafia ni Kabiesi tuntun mu lasiko etutu rẹ, eyi to tumọ si pe alaafia yooo jọba nilu Ọwọ lasiko ti Ọba naa ba fi wa lori itẹ.

Oríṣun àwòrán, @juwon2017
"Ni ilana asa ibilẹ wa, Ọlọwọ tuntun gbọdọ mu ida kan ni Oke Mapo, ida to ba si mu, ni igbagbọ wa pe yoo sọ bi akoko rẹ lori itẹ yoo se ri. Kẹ si maa wo, irufẹ ida ti baba rẹ mu ni ọgbọn ọdun o le diẹ sẹyin, naa ni Ọba Ogunoye naa tun mu yii."
- Ìdí rèé tí mi ò fi yọjú sí ìgbìmọ̀ àjọ PFN- Fatoyinbo
- Ẹ yọjú sí FBI bí ẹ kìí bá ṣe ''yahoo boys'' - Abike Dabiri-Erewa
- Èmi àti Saheed kìí ṣe ọmọdé, a ti jọ ṣe Sinimá papọ̀, èyí túmọ̀ sí pé ìjà ti parí - Fathia Balogun
- Wọ́n ta ère Ọ̀ṣun Osogbo sí Togo - Bàbá Ọṣun figbe ta
- Ayédèrú Ọ̀ṣun ni wọ́n ń bọ lónìí, kìí ṣe ojúlówó - Bàbá Ọlọ́ṣun tún figbe ta
Ọlọwọ tuntun yii, tii se amofin, la wa n gbadura fun pe igba rẹ yoo tu ilu Ọwọ ati ilẹ Yoruba lapapọ lara.












