Joe Igbokwe kò yẹ́ fún ipò ti wọ́n fún un nípìnlẹ̀ Eko - Babatunde Gbadamosi
Awuyewuye kò ti i pari lórí àwọn Kọmísọnà àti olubadámọràn pàtàkì tí gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, ti Babatunde Sanwo-Olu yàn ní ọjọ Ajé.
Lẹ́yìn tí Sanwo-Olu fi orúkọ ènìyàn mẹ́jìdínlógójì sọ́wọ́ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, orúkọ márùndínlọ́gbọ̀n ló kógo já Sanwo Olu yan kọ̀míṣọ́nnà 25 àtàwọn olùbádámọ́ràn.
Babatunde Gbadamosi, ọkan lara awon oludije dupo gomina ipinlẹ Eko ninu eto idibo to kọja sọrọ lori awon mẹta ti wọn yọ nipo eti ero rẹ pe ọmọ ẹni ko le ṣe idi bẹbẹrẹ ki a ko ilẹkẹ sidii ọmọ ẹlomii.
O ni pé ẹni to moju ogun lo yẹ ki wọn yan ko pabì nire lainii fi ṣe iran ẹni naa.
Loju Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ko si ohun to buru ninu yiyan ọmọ iran miran bii Igbo sipo nipinlẹ Eko ṣugbọn ẹni naa gbọdọ kunju oṣunwọn to.
O ni, omo Yoruba ni won yọ, ti won si fi omo guusu ila oorun ti awọn iṣẹ to ti ṣe sẹyin to jẹ aridimu ko wu ni lori to.
Bakan naa ni BBC kan si alaga igbimọ fidihẹ lori eto iroyin ati ifitonileti gbogbo fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Oloye Tunde Braimoh lati Alimoṣọ II sọrọ lori koko yii nibi to ti ni oun ko faramọ ero Gbadamọsi rara.
O ni ipinlẹ Eko jẹ ipinlẹ gbogbo eniyan Naijiria ati pe ko si ẹni ti awọn eeyan n fẹ ti wọn ti ko le di ipo mu nipinlẹ Eko.
O ni koko ti oun ri ni pe irinajo oṣelu ti yatọ si ti atẹyinwa ati pe ko sẹni to le dipo mu lai nii ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu.
Oloye Tunde ni laisi pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa mọ irufẹ ẹni naa iwọnba ni awọn ọmọ ile igbimọ le ṣe mọ.
Yatọ si eyi, gbogbo nkan to yẹ ki ẹni ti wọn ba dibo yan yẹ ko ni ni iriri ati eto ẹkọ to yaranti, naa lo yẹ ki ẹni to ba fẹ gba ipo kọmiṣọna ni ki ato buwọ lu iyansipo wọn.