Mínísítà 43 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe ìbúra fún to yàn sípò

Oríṣun àwòrán, @others
Bakan naa lo tun fun awọn minisita kọọkan ni iṣẹ ati ileeṣẹ ijọba ti wọn yoo mojuto ninu iṣejọba rẹ.
Aarẹ Buhari ni oun ti tubọ fẹ awọn ileeṣẹ ijọba loju sii ki idagbasoke lee tete sun araalu bọ.
Awọn minisita naa ree pẹlu orukọ ileeṣẹ ti wọn yoo dimu:
- Ọmọwe Okechukwu Ogar- Minisita abẹle fun idagbasoke Irin tutu ati iwakusa
- Muhammadu Bello-Minisita fun Olu ilu Ilẹẹwa, FCT
- Sẹnetọ Godswill Akpabio- Minisita fun agbegbe Niger Delta
- Dokita Chris Ngige-Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ
- Sharon Ikeazor- Minisita abẹle fun ọrọ ayika
- Mallam Adamu Adamu- Minisita fun eto ẹkọ
- Mariam Katagum- Minisita Abẹle fun ọrọ ileeṣẹ, idokoowo, ati karakata
- Timiprey Silva- Minisita kekere fun epo rọbi
- Sẹnetọ George Akume- Minisita fun akanṣe iṣẹ ati ọrọ ilẹ okeere
- Mustapha Baba Shehuri - Minisita kekere fun eto ọgbin ati idagbasoke igberiko
- Goddy Jedi Agba (Cross River)- Minisita kekere fun ipese ina manamana
- Festus Keyamo (Delta)- Minisita kekere fun ẹkun Niger Delta
- Ogbonaya Onu (Ebonyi)- Minisita fun imọ Sayẹnsi ati imọ ẹrọ
- Osagie Ehanire (Edo)- Minisita fun eto ilera.
- Clement Anade Agba (Edo)- Minisita abẹle fun aato ati inawo
- Ọtunba Adeniyi Adebayọ - Minisita fun ileeṣẹ, idokoowo ati karakata
- Geofery Onyeama (Enugu) - Minisita fun ọrọ okeere
- Ali Isa Ibrahim Pantami (Gombe)- Minisita fun ibaranisọrọ
- Emeka Nwajiuba (Imo)- Minisita abẹle fun eto Ẹkọ
- Suleiman Adamu (Jigawa) - Minisita fun ohun alumọni inu omi
- Zainab Shamsuna Ahmed (Kaduna) - Minisita feto iṣuna ati aato ilẹẹwa
- Mohammed Mahmud - Minisita fun ọrọ ayika
- Mohammed Sabo Nanono (Kano) - Minisita fun eto Ọgbin ati idagbasoke igberiko
- Bashir Magashiri (Kano) - Minisita fun eto abo
- Sẹnetọ Hadi Sirika - Minisita fun irinna ofurufu
- Abubakar Malami - Agbẹjọro agba ati minisita fun eto idajọ.
- Ramatu Tijani (Kogi)- Minisita abẹle fun olu ilu orilẹede Naijiria, FCT
- Lai Mohammed- Minisita feto iroyin ati aṣa
- Gbemisọla Saraki - Minisita abẹle fun igbokegbodo ọkọ
- Babatunde Faṣọla - Minisita fun iṣẹ ode ati ile gbigbe
- Sẹnetọ Olọrunnibẹ Mamoora - Minisita abẹle fun eto ilera
- Mohammed Abdullahi- Minisita abẹle fun imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ.
- Suberu Dada - Minisita abẹle fun ọrọ ilẹ okeere.
- Ọlamilkekan Adegbitẹ - Minisita fun idagbasoke Irin tutu ati iwakusa.
- Sẹnetọ Tayọ Alaṣọ Adura- Minisita abẹle fun ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ
- Rauf Arẹgbẹṣọla -Minisita fun ọrọ abẹle
- Sunday Dare - Minisita fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya.
- Pauline Tallen - Minisita fun ọrọ awọn obinrin.
- Rotimi Amaechi - Minisita fun igbokegbodo ọkọ
- Mohammed Maigari (Sokoto) - Minisita fun ọrọ ọlọpaa
- Onimọẹrọ Saleh Maman - Minisita fun ipese ina ọba
- Abubakar Aliyu - Minisita Abẹle fun iṣẹ ode ati ile gbigbe
- Sadiya farouq - minisita fun iṣẹlẹ pajawiri.
Mínísítà mẹ́tàlélógójì ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe ìbúra fún
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Aare Muhammadu Buhari ti pari ikede to fi yan awọn minista tuntun sipo loni.
Aarẹ yan awon minisita tuntun si ipo loni ni ilu AbujaWo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn obìnrin méje ti Buhari fẹ́ yàn sípò minista.
Ayẹyẹ yiyan awọn minisita naa ti n waye lẹyin ti aarẹ ti fi orukọ awọn mẹtalelogoji ransẹ si ile igbimọ asofin nilu Abuja fun ifọwọsi.
Boss Mustapha, ẹni ti o jẹ akówe gbogbogbo ijọba orilẹ-ede yii lo fi ọrọ naa lede ni ọjọ Isẹgun pe, ayẹyẹ yiyan awọn minisita tuntun naa yio waye ni deede aago mọkanla owuro loni.
Lara awọn minisita ti o ti wa ni ipo tẹlẹ ti o si tun n pada bọ nibẹ ni Babatunde Fashola, lati ilu Eko, eni ti o jẹ minisita fun ohun amuṣagbara, ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe.

Oríṣun àwòrán, @TheMbuhari
Bakan naa ni Adamu Adamu, lati ipinlẹ Bauchi, ẹni ti o jẹ minisita fun eto ẹkọ nigba naa. Ati Lai Mohammed, minista fun eto ifitonileti, aṣa ati iroyin.
Lara awọn ti aarẹ Buhari ko ni ba ṣisẹ ni saa yi ni Audu Ogbeh, minista fun eto ọgbin.

Oríṣun àwòrán, @BuhariMediaORG
Solomon Dalung, minista fun eto ọdọ ati ere idaraya.
Beeni aare tun ja Abdur-Raheem Adebayo Shittu silẹ, eni ti o je minisita fun eto ibaraẹnisọrọ.
Kete lẹyin ibura yii ni awọn eniyan gba pe aarẹ Buhari yoo kede ipo ti onikaluku a dimu gẹgẹ bi minista.
Lẹyin ayẹwo awọn minista ki lo ti ṣẹlẹ?
Ni kete ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ti pari ayẹwo awọn ti aarẹ Buhari forukọ wọn ranṣẹ sile ni wọn ti n poungbẹ.
Ijọba Naijiria ṣeto idanilẹkọ nibi apero ọlọjọ meji to waye ni ọjọ Aje ati ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, ṣaaju ibura toni n ilu Abuja.
Nibi ti aarẹ ti fi ye wọn pe iṣẹ wọn ṣẹṣẹ n bẹrẹ ni ati pe kekere kọ ni ike Ramọ iṣoro ti ijọba n wa ojutu si ni Naijria lasiko yii.
A o maa muu wa fun igbadun yin, bi ohun gbogbo ba ṣe n ṣelẹ loju opo yii...












