FRSC: èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí èyí máa ṣẹlẹ̀

frsc

Oríṣun àwòrán, @FRSC

Àkọlé àwòrán, Iwa ibajẹ riba gbigba gbọdọ dopin ni Naijiria

Ọwọ òfin ti tẹ àwọn oṣiṣẹ aabo oju popo mẹtadinlogoji nitori rìbá gbígbà.

Ṣé Yorùbá bò, wón ní, ohun tó wu ọmọ ó jẹ, ní i rún ọmọ nínú, ọwọ sìkún òfin tẹ àwọn ọmọ àjò ẹṣọ ojú pópó látàrí owó ẹyin ti wọn gbà lọ́wọ́ aráàlú.

Ogbeni Clement Oladele to jẹ óga àgbà àjọ náà ni ìpínlè Ogun lo ṣalaye okunfa iṣẹlẹ naa.

O ni ìjìyà tó dájú wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lu òfin ninu wọn.

O sọrọ yii lasiko to ń bá ilé ise lroyin BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ látàrí àwọn ọmọ àjọ náà tí owo tẹ ní ìpínlè náà.

Igbimọ apapọ ajọ DSS, ICPC, àti FRSC ni wọn jọ jade ki ọwọ wọn to tẹ awọn oṣiṣẹ ti ọwọ tẹ.

Oladele tesiwaju wí pé, ó wá nínú ẹ̀kọ́ tí wón ń kó gbogbo oṣiṣẹ FRSC pe wọn ko gbọdọ gba riba lọwọ ẹnikẹni.

O ni eyi ṣe koko ninu ẹkọ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ ìgbáradì àjọ náà.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ilé iṣẹ́ FRSC àti àwọn agbófinró tóku yòó yẹ̀wé ọkọ̀ wò

Oga agba FRSC kò ṣai fẹnu bá a pé, loorekoore ni wọn yóò máà ṣàyẹ̀wò sí àwọn ọmọ àjọ náà lójú pópó láti mu ẹ̀dínkù ba ìwà ìbàjé owó ẹyin gbígbà.

O ni gbogbo awọn ti ọrọ kan ni iwadii lori ẹsun naa ti bẹrẹ fun ati pe ijiya wa fun awọn ti ade ọrọ naa ba ṣimọ lori.

Ṣe laipe yìí ni ọwọ ṣìkún àwọn agbófinró tẹ pupọ lára àwọn ọmọ àjọ náà ni ìpínlè Ogun, Kogi àti àwọn Ìpínlẹ̀ Abia, Ebonyi àti Imo ni ila oorun guusu Naijiria.