Osun Kidnap: Òṣìṣẹ́ àjọ FRSC méjì bọ́ sọ́wọ́ àwọn ajínigbé l'Ọsun

Oríṣun àwòrán, FRSC
Awọn ajinigbe ti gbe oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo meji gbe ni ipinlẹ Oṣun.
Agbẹnusọ fun ajọ , Bisi Kazeem ati agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpa ipinlẹ Oṣun, Folasade Odoro lo fi aridaju iṣẹlẹ naa han fun awọn oniroyin.
Wọn ji wọn gbe ni agbegbe Iwaraja ni ijba ibilẹ Oriade lọjọ aje ọsẹ yii.
Gẹgẹ bi wọn ṣe darukọ wọn, awọn oṣiṣẹ ajọ FRSC naa ni Bayegunmi ati Abioye.
Omidan Folasade Odoro ni igbiyanju ti n lọ lọwọ lati doola awọn ti wn ji gbe ọhun.
Ijinigbe bi eleyii ko ṣẹṣẹ maa waye lorilẹede Naijiria to fi mọ iha Guusu-Iwọ Oorun Naijiria eyi ti ipinlẹ Ọṣun wa.
Laipẹ ni wọn ṣẹṣẹ tu ọjọgbọn ile iwe giga fasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ifẹ ni ipinlẹ Oṣun silẹ lẹyin owo itanra gọbọi ti a gbo pe wọn san.










