Data Usage: Ọ̀nà márún-ún láti mú àdínkù bá dátà fóònù lílò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Njẹ eyi ti ṣẹlẹ̀ sí ọ ri, tí wà á sùn lálẹ pẹ̀lú dátà ti ilẹ̀ si mọ ti gbogbo ǹkan to kù kò tó mẹgábáítì mẹ́wàá lọ mọ?
To ba ri bẹẹ, àsìkò yìí gan an ni òó mọ pé ọ̀rọ̀ dátà níní lóri fóònu jẹ ìpènijà gidi fún àwọn eniyan láwùjọ.
Títẹ fóònù máa ń dùn mọ ènìyàn gan an ni tí ọ̀pọ̀ dátà ba wà láti wo gbogbo ǹkan to n lọ lágbàyé.
Koda, ọpọ a maa fẹ wo àwọn ǹkan ti ọrẹ́ ti gbé sórí Snapchat, Instagram àti àwọn oríṣirísí èròjà tó wà lóri ẹ̀rọ ayélujara, sùgbọ́n ó ni láti ròó dáràdára kí o to tẹ̀síwáju nítori bi yóò ṣe maa jẹ dátà rẹ.
Gbogbo ènìyàn ló mọ pe owó dátà kò rọrùn rárá, àbí ẹ ẹ melo ní ẹ ti ròó pé ó yẹ ki àwọn Mààmí àti Bàámí ti fi kún owó àkosápò yín nítori ǹkan ti dátà ń gbà lọ ninu owó ti wọ́n ń fún yín

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sùgbọ́n ìfòyà kò sí mọ nítori Oluwakorede Cole gẹ́gẹ́ bi orúkọ rẹ̀ ti kó ire wọ̀lú.
O jẹ ẹni tó ń ṣe àgbélẹ̀rọ èròjà ayélujára, ó si ti sàlàyé fún BBC pe ọ̀nà àbáyọ ti wà láti sàmúlò dátà kékere tó wà lóri ẹ̀rọ alágbéka rẹ
- Wo àwọn irinṣẹ tó ń siṣẹ́ lábẹlẹ̀ kí o si pa 'ààpù' wọ̀n ti wọ́n kò ba ṣe pàtàkì lóju ẹsẹ.
- Lo Wi-Fi fún àwọn ǹkan to ba gba dátà púpọ to ba fẹ se lori ayelujara, bí àpẹrẹ gbígba máàpù tí kìí jẹ dátà tàbí o fẹ jẹ ki àgbéga bá àwọn 'áàpù' ti ó wà ló ẹ̀rọ alágbeka rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Wíwo fọ́ràn pẹ̀lú dátà rẹ kìí ṣe eyí to le sànfani fún dátà rẹ.
- Ri dáju pé ò kí ń wo fọ́nran orin, eré tàbi ǹkan míràn pẹlú dátà rẹ, ọ̀nà abáyọ ni láti kọ́kọ́ gbàá sílẹ̀ kí ó to wòó, pàápàá jùlọ ti ó ba ri ànfàni Wi-Fi.
- Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn fóònù máa ní ibi ti a ti le mú àdínku bá iye dáta ti a fẹ lo.
- Ríi dáju pé o lọ ṣe èyí ki o máà ba lo ju iye ti o yẹ ki o lo lọ láàrin iye gbèdéke ti o ba fi si bẹ.
- Kini ìdí ti ó fi ń lo àwọn irinṣẹ́ aṣàwári tí àwọn ènìyàn ńlá ń lò, ọ̀pọ̀ àwọn irinṣẹ́ aṣàwári wà ti yóò ràn ó lọ́wọ́ láti yọ ìpólówó ọjà kúrò àti àwọn ǹkan míràn ti kò ṣe pàtàkì















