Ogún ọdún ni mo fi gbáradì fún àjàkálẹ̀ ààrùn coronavirus

Oríṣun àwòrán, Emma Russell
Igbe aye lasiko itankalẹ aarun coronavirus yii le nira pupọ, paapa fun awọn ti ipaya ipa ti aarun naa le ni l'ara wọn. BBC ba Peter Goffin sọrọ l'ori ọna to n gba lo igbesi aye rẹ lasiko yii.
Peter jẹ ẹni to ni ailera ti awọn onimọ n pe ni Obsessive Compulsive Disorder (COD).
Ailera yii tumọ si ki eeyan o deede ni ipaya pe ewu wa fun oun lasiko to tọ, ati asiko ti ko tọ ọ. Iru ẹni bẹ le maa ni ipaya ju bose yẹ lọ nipa kokoro aifojuri, eyi to le mu ki wọn o maa ṣe imọtoto ju bose yẹ lọ.
- Atẹ́gùn òjò rán ọ̀pọ̀ lóko àdánù nílùú Ìbàdàn, aráàlú gbarata
- Wò ohun mẹ́ta tí a mọ̀ tí yóò mú ìjọba pàṣẹ kónílé-ó-gbélé lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Èkó
- Àwọn nǹkan tí obìnrin lè ṣe pẹ̀lú olólùfẹ́ oníwà ipá lásìkò ìgbélé Coronavirus yìí
- Coronavirus: Ǹjẹ́ àwọn dókítà tó ń tọ́jú eyín ń ṣisẹ́ lásìkò pàjáwìrì? Àti àwọn ìbéèrè míràn
Ailera ti Peter ni mu ki o rọrun fun-un lati mọ bi o ṣe le gbe igbe aye to ni itumọ lasiko ajakalẹ aarun Covid-19.
"Ilẹ̀ yaara ìdáná mi ni mo joko si, ti mo n fi oogun apakokoro nu ara apo oúnjẹ onihoro kan, ni mo ri ifihan kan: Bi ogun ọdun ni mo n mura silẹ fun ajakalẹ aarun coronavirus.
Nigba ti mo wa ni ọdọ langba, wọn sọ pe mo ni ipenija Obsessive Compulsive Disorder (OCD).
Ìdá meji ninu mẹta asiko ti mo ti lo laye, ni mo fi n wa imọ nipa kokoro aifojuri, bi wọn ṣe le gba ara ẹni kan de ti ẹlomiran, ati bi mo ṣe le kapa wọn.

Oríṣun àwòrán, Emma Russell
Eyi lo si ranmi lọwọ lati tete mọ nkan to yẹ lati ṣe niru asiko ajakalẹ aarun coronavirus, ti gbogbo eniyan ni ilana ti wọn gbọdọ pamọ.
Gbogbo igbesẹ bi i ka jina sira ẹni nibi ti kii ba se ile mi, ọwọ fifọ lẹyin ti mo ba fi ọwọ kan nkan ti ẹlomiran ti fọwọ́ kan, to fi mọ fifi ọsẹ fọ awọn oúnjẹ ti mo ba ra, ni mo ti gbe ni gbogbo ọjọ aye mi. O ti mọ mi lara.
Ko fẹ ẹ si eyi to sajoji si mi ninu gbogbo ilana antẹẹle lori coronavirus.
Eyi to kan ma n jẹ jade ju ni aini ifọkanbalẹ pe aabo wa fun mi lọwọ aarun.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún eniyan kaakiri agbaye lo n bi ara wọn lere bayii pe: "Ṣe kii ṣe pe ẹni ti mo pade nile itaja yẹn sunmọ mi ju?"
Ha, ṣe mo fọ ọwọ mi daada báyìí?"
Ṣe ọsẹ yii ma a pa gbogbo kokoro aifojuri?"
Lootọ ni a le maa tẹle gbogbo ilana ti wọn ni ki a maa tẹle lasiko yii, lati daabo bo ara wa. Sugbọn iyemeji ati ipaya ko le salai maa waye.

Oríṣun àwòrán, Emma Russell
Eyi ko tumọ si pe eeyan n ro erokero, awọn nkan wọn yii lo mu ki a máa kiyesara.
Sugbọn kan to wa nibẹ ni pe wọn le kọja bose yẹ.
Nigba ti mo n dagba lorilẹ-ede Canada, iṣoro ti mo ni ni bibori ẹ̀rù lati igba ti mo wa ni bi ọmọ ọdún maarun si mẹfa. Nigba ti ma a si fi pe ọdun mejila, o ti dinku si ifoya nípa imọtoto, paapa nipa fifi ara ko àwọn nkan to n jade lara ẹlomiran: bi itọ́ to n jade lẹ́nu wọn ti wọn ba sọrọ, kokoro aifojuri to n tankalẹ ti wọn ko ba fọwọ́ wọn lẹyin ti wọn lo ile ìyàgbẹ́, ati gbogbo awọn kokoro aifojuri ti mo lero pe o yi mi ka.
Awọn ẹbí mi sakiyesi pe mi o ki n fẹ fi ọwọ kan awọn nkankan, ti mo si maa n fọwọ́ kọja bose yẹ.
Wọn ti mi lẹyin, wọn si mu mi lọ ọ ri onímọ̀ nipa ilera ọpọlọ. Lati igba naa ni mo ti n lo oogun fun ìrẹ̀wẹ̀sì ọkan, titi di oni.
Lootọ ni oogun lilo ati OCD ti mọ mi lara, sugbọn o koba igba èwe mi diẹ, nitori pe ọpọ igba ni mo maa n mu ọrọ imototo kọja bose yẹ.
Lati nkan bi ọdun maarun, apá mi ti ka ipaya ti OCD maa n fun mi:mo ti mọ ẹ̀rù to tọ́ ati eyi ti ko yẹ ki n gba laaye.
Ọpọlọpọ eeyan to ri bi i temi lo sọ pe awọn ko fi bẹ ẹ ni ipaya lasiko ajakalẹ aarun yii. Boya nitori pe gbogbo aye lo n ṣe bi i wọn bayii.
Bẹ ẹ lo ri fun emi naa, sugbọn o tun ti da ji awọn ipaya mi kọọkan dide.

Oríṣun àwòrán, Emma Russell
Mo ti pada si iwa ikiyesara ju bose yẹ lọ, fifọ awọn nkan ti mo ba ra ki n to o ko wọn sinu firiiji, fọfọ ọwọ laimọye igba, fifọ bata ti mo ba wọ jade; awọn iwa ti mo ro pe mo ti jawọ ninu rẹ.
Lootọ ni awọn eeyan ti n pe fun ṣíṣí ọrọ aje pada, yoo sọrọ lati ni ifọkanbalẹ. Ko si si igba to wu ki wọn o si awọn ile itaja, ileesẹ ati ileewe, ibẹru ati ipaya ti Covid-19 mu wa ko le lọ kiakia,yoo to ọpọlọpọ oṣu. Sugbọn nkan to damiloju ni pe eeyan le kapa ifoya rẹ.
Emi gẹgẹ bi ẹnikan ti lọ fun idanilẹkọọ lorisirisi bi mo ṣe le bori awọn ipenija mi.
Lootọ lo dara lati ri akọṣẹmọṣẹ nipa ipenija yii, sugbọn o le ṣe diẹ fúnra rẹ : o le kọ awọn nkan to n ja ọ laya si ibi kan, ati idi ti o fi n jaya, ati bi o ṣe ni imọlara si. Eyi ni wọn yoo ṣe agbeyẹwo rẹ lati mọ iru iranlọwọ ti o nilo.
Ko si iru ipaya ti aarun coronavirus le mu ba ọ, boya nípa ilera rẹ, pipanu isẹ, faaji, oun ti o ni lati mọ nipe kii se iwọ nikan lo n laa kọja.
Bakan naa ni awọn imọran awọn eleto ilera to sọ pe ọpọ to ni aarun Covid-19 yoo ru u là, tabi pé fifi omi ati ọsẹ fọ ọwọ rẹ yoo mu ọ mọ tonitoni, to fi mọ fifọ aṣọ rẹ bi i ti tẹlẹ yoo mu kokoro naa kuro lara rẹ, le fi ọ lọkan balẹ.
Ju gbogbo rẹ lọ, maa ranti pe ọrọ aarun coronavirus yii kii ṣe tẹnikan."












