Coronavirus domestic violence: Àwọn nǹkan tí obìnrin leè ṣe pẹ̀lú olólùfẹ́ oníwa ipá lásìkò ìgbélé Coronavirus yí

- Author, Azeezat Olaoluwa
- Role, Women's Affairs Reporter, West Africa
Kaakiri ilẹ Afrika, ọpọ ijọba pẹlu awọn agbofinro ti sọ pe idjukọ awọn obinrin ninu igbeyawo wọn lasiko igbele Coronavirus n peleke sii.
Koda, ajọ iṣokan orilẹde agbaye, UN, ti sọ pe ajakalẹ arun kan ni ki obinmrin maa ni idojukọ ninu igbeyawo wọn, papa pẹlu ọkọ oniwa ipa.
Kini ohun to yẹ ki eeyan ṣe to ba n ni idojukọ ninu igbeyawo rẹ lasiko yii?
A bere lọwọ awọn to ti la iru nnkan bẹ kọja lati sọ iriri wọn ati awọn ohun ti eeyan lee ṣẹ to ba n ni idojukọ ninu igbeyawo rẹ, pẹlu ọkọ oniwa ipa..
Arabirin kan, Esther ṣalaye fun akọroyin wa pe "Ti eeyan ba wa ninu igbeyawo oni jagidijagan, awọn iwa ipa naa ma n wa lemọ lemọ ni, bii eebu ati ilu bara."
O tẹsiwaju pe "Opin ọsẹ lo ma n lekenka ju nitori ko ki n si ẹnikẹni ninu ile. Fun idi eyi, ololufẹ ẹni ma n ni aye lati ṣe bo ṣe wu nigba ti ọwọ wọn ba ti dinlẹ, igba yẹn gan ni wọn ma n ri aye lati fa wahala lẹsẹ."
O ni "Wọn ma n bẹrẹ pẹlu awọn ọrọ kobakungbe to maa mu inu bi eeyan, eyi tyo jẹ ọna ti wọn ma n gba lati fa ijọgbọn lẹsẹ."
Bi ẹni wa ninu ahamọ
"Ti idawa opin ọsẹ ba le mu ki ọkunrin lu eeyan, ẹ ro ohun ti iru ọkunrin bẹ le ṣe ti eeyan ba wa pẹlu rẹ fun oṣu. Ibẹru lọsan atoru ni iru obinrion bẹ ma n wa."

O ti to ọdun diẹ bayii ti Esther ti fi ọkọ rẹ silẹ, bo tilẹ jẹ pe ko rọrun, ṣugbọn igboya lo fi gbe igbesẹ to gbe.
Esther sọ pe "Ni ṣe lo dabi ẹni pe mo wa nin u ẹwọn ti wọn fi irin yika ti mi o si le jade, o jẹ ohun to ṣoro funmi, bẹẹ naa ni mo tun n ro ti awọn ọmọ mi pẹlu.
"Nigba miran ẹwẹ, papa nile adulawọ ti iya eeyan mọ pe ọmọ rẹ obinri ti ṣegbeyawo, irufẹ obinrin bẹ ko ni fẹ kokuro nile ọkọ rẹ."
Yoo ṣoro diẹ fun ọpọ awọn obinrin ti wọn n fẹ lati kuro nile ọkọ lasiko yii nitori ofin konile-o-gbele to wa lode lasiko arun Covid-19.
Ti iru obinrin bẹẹ ba dede jade kuro nile lọwọ alẹ, awọn agbofinro le da duro lọna lati ṣalayae ibi to n lọ, tabi ko ma ri ọkọ loju popo.
Ọpọ awọn orilẹ-ede lo ti ṣagbekalẹ ẹrọ ibaraẹni sọrọ ti awọn eeyan le pe ti ọkọ wọn ba n lu wọn nile, ọpọ awọn obinrin lo si ti bẹrẹ si n pe awọn ẹro ibaraẹni sọrọ naa.
'Iṣẹlẹ naa n peleke sii'
Ni ọsẹ akọkọ ofin konile-o-gbele, ileeṣẹ ọlọpaa South Africa gba ipe to le lẹgbẹrun meji, eyi to jẹ ti iwa ipa akọ si abo to pọ ju bo ṣe ri tẹlẹ lọ pẹlu ida mẹtadinlogoji.
Nilẹ Zimbabwe, iye awọn to ti fẹjọ sun ijọba lori iwa ipa akọ si abo ti le ni ida mẹta.
Ajafẹtọ ọmọniyan lori iwa ipa akọ si abo kan ni Naijiria, Dorothy Njemanze sọ fun BBC pe bi iṣẹlẹ ọhun ṣe n peleke si ni Naijiria n kọ oun lominu.
Awọn orilẹede kan nilẹ Afrika ti gbe iranlọwọ dide fun obinrin to n ni idojukọ yii; fun apẹrẹ, ijọba Tunisia ti gbe nọmba ipe kalẹ fun awọn obinrin.

Ni Zimbabwe, awọn agbalagba mọkanlelogun ati ọmọde meje lo n gbe ile kan ti ileeṣẹ ti wọn n pe ni "Roots One Stop Shelter" gbe kalẹ.
Adari ileeṣẹ ọhun, Beatrice Savadye ni wọn n gbiyuanju ati gba awọn eeyan naa la kurọ lọwọ iwa ipa ti wọn n dojukọ ninu ile wọn.
'Ibi ti awọn obinrin le foripamọ si'
Bakan naa ni ilẹ Kenya, oṣiṣẹ awujọ kan, Dianah Kamande ni ileeṣẹ oun ṣi ni aye lati fun awọn obinrin ni abo si lẹyin to ti gba obinrin mẹtadinlogun la ni Nairobi nikan.
Ni Naijiria, bo tilẹ jẹ ọpọ ibi tawọn obinrin lee foripamọ si ti di titi pa nitori ofin konile-o-gbele, awọn eeyan kan ṣi n ran awọn obinrin lọwọ lati gbawọn la kuro lọwọ ọkọ oniwa ipa.

- Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà wọ́gilé ẹ̀wọ̀n Orji Uzor Kalu, pàṣẹ ìgbẹ́jọ́ tuntun
- Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá kó gbogbo ọlọ́pàá ẹkùn Ondo lọ fún àyẹ̀wò COVID-19
- "Ọkọ kọ̀ mí, mo fẹ́ jẹ májèlé torí mo bímọ tó ní ojú ara takọtabo"
- Coronavirus: Ǹjẹ́ àwọn dókítà tó ń tọ́jú eyín ń ṣisẹ́ lásìkò pàjáwìrì? Àti àwọn ìbéèrè míràn

Ṣugbọn adari ile tawọn obinrin Kenya le fori pamọ si julọ, Nana Sunnu ni wọn kole gba ẹnikẹni bayii nitori ajakalẹ arun to wa lode, ati pe ibi tawọn eeyan le gbe fun anfani idanikan wa ko to nkan.
Esther to ru igbeyawo oniwa ipa la ti bẹrẹ si n ṣiṣẹ pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ to ti la iru nkan bẹ kọja ri.
O rọ awọn obinrin lati kan si awọn ajafẹtọẹni loju opo ikansiraẹni ti wọn le fọkan tan.

Onimọ ijinlẹ kan nipa bi eeyan ṣe n ronu nilẹ South Africa, Nthabiseng Ramothwala ni o yẹ ki awọn ara adugbo jẹ oluranwọ aladugbo wọn ti wọn lero pe o le ma la igbeyawo to ni iwa ipa kọja.
Bẹẹ naa lo tun rọ awọn obinrin lati kan si awọn to sunmọ wọn fun iranlọwọ.
O ni "Ẹ mọ nọmba pajawiri ti ẹ le pe, ẹ jẹ ki awọn aladugbo yin mọ ohun ti ẹ n la kọja, ẹ sọ awọn apẹrẹ ti wọn le ri lara yin funwọn lọna ati le ran yin lọwọ.
O tẹsiwaju pe "Ẹ fun wọn ni nọmba awọn ẹbi yin ti wọn lee pe lati wa gba yin nigba ti wahala ba ṣelẹ."
Fun awọn ti wọn ko le ṣa asala fun ẹmi wọn, Esther ni imọran mii.
O sọ pe "Ko yẹ ki o dakẹ nitori pe o ko fẹ ṣẹ ẹlomiran, ti wọn ba ti n sọrọ to ba bi ẹ ninu, iwọ ṣaa maa wo ni tiẹ."
Ti wọn ba gbiyanju ati mu ẹ binu, wa nnkan mii ṣe, bii ki o kawe ti o ba fẹran tabi ohunkohun to le mu ọkan rẹ jina rere si sakani wọn."
Ti o ba le ṣaṣeyọri ninu eyi fun nnkan bi oṣu meji tabi mẹta titi di igba ti ofi konile-o-gbele yoo fi kasẹ nilẹ, o ti n bopri diẹ diẹ niyẹn."
Esther pari ọrọ rẹ pe "A ko tii le sọ pe ọna ababyọ kan gboogi ni eyi o, ṣugbọn ti ẹmi ba wa, ireti n bẹ."












