Orji Uzor Kalu: Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà wọ́gilé ẹ̀wọ̀n Orji Uzor Kalu, pàṣẹ ìgbẹ́jọ́ tuntun

Uzor Kalu atawọn ẹṣọ agbofinro
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti wọgile idajọ ẹwọn ọdun mejila ati gbigbẹsẹle dukia ti ile ẹjọ gbe le gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ Orji Uzor Kalu.

Gbogbo adajọ mejeeje to joko lori igbẹjọ naa ni wọn fohun ṣọkan pe ile ẹjs giga apapọ ilu Eko to gbe idajọ kalẹ pe Kalu, ileeṣẹ rẹ Slok Nigeria Limited ati oludari eto iṣuna tẹlẹ nipinlẹ Abia, Jones Udeogu jẹbi ẹsun kiko ipinlẹ Abia owo to le ni biliọnu meje naira jẹ.

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria woye pe Onidajọ Mohammed Liman to dajọ naa kii ṣe adajọ mọ nigba to gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ naa.

O ni niwọn igba to jẹ pe wọn ti gbe Onidajọ Liman ga lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣaaju igba naa, ko lẹtọ mọ lati pada lọ gbọ ẹjọ naa tabi gbe idajọ kalẹ lori rẹ. Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria woye pe aṣẹ ti aarẹ ile ẹjọ kotẹmilọrun fun un pe ko lọ gbs ẹjọ naa labẹ ofin iṣedajọ lorilẹede Naijiria ko ba ofin mu.

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria wa wọgile idajọ naa pẹlu aṣẹ pe ki wọn lọ tun ẹjọ naa gbọ lati ibẹrẹ

EFCC: Àwọn ọmọ Orji Kanu la mú, kìí se ti Atiku

ami idanimọ EFCC

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Àkọlé àwòrán, àjọ EFCC ní òun leè fọwọ́ sọ̀yà pé iṣẹ́ ń lọ ní pẹrẹu

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, ti kegbare sita pe, awọn ko fi panpẹ ofin gbe awọn ọmọkunrin oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar.

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣelu PDP fi ikede kan sita pe, ajọ naa lọ tu ile awọn ọmọ Atiku wo, lati mọ boya wọn ko owo ilẹ okeere pamọ sile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Igun OPC: OPC ti sọnù, àwọn èèyàn ń sá fún wa láì fẹ́ darapọ̀ mọ́ wa

Sugbọn EFCC, ninu atẹkade kan loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ ṣalaye pe, ahesọ ọrọ ati irọ to jina sootọ ni ẹsun naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

EFCC ṣalaye wi pe, ọmọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Abia, Theodore Orji Kalu, ati ọrẹ rẹ kan ni awọn mu.

Ajọ naa to ti n ṣe iwadi gomina naa tẹlẹ fun ẹsun kiko biliọnu mẹtadinlogun Naira pamọ lọna aitọ, ti 'iṣẹ iwadi wọn si fihan pe, Orji ko diẹ lara owo naa pamọ nipasẹ awọn ọmọ rẹ ọkunrin.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ajọ EFCC to ni, igbesẹ awọn ko ni nkankan ṣe pẹlu Atiku Abubakar tabi awọn ọmọ rẹ, wa tako awọn iroyin to wa nita.

Wọn fikun pe awọn ko mọ ohunkohun nipa bi wọn ṣe gbẹsẹ le apo aṣuwọn oludije fun igbakeji rẹ, Peter Obi, eyi to tako ohun ti ẹgbẹ oṣelu PDP sọ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Bakan naa ni agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu sọ pe, ayederu iroyin ni ẹgbẹ oṣelu PDP n fi sita lori ọrọ naa.

Sheu loju opo Twitter sọ pe, irọ ni pe ijọba apapọ Naijiria lo paṣẹ pe ki EFCC ṣayẹwo ile awọn ọmọ Atiku Abubakar.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

EFCC tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe, idaji ọjọ Abamẹta to kọja ni ọwọ wọn tẹ ọkan lara awọn ọmọ naa, Ogbonna Orji ati ọrẹ rẹ kan, lasiko ti wọn lọ fun igbadun opin ọsẹ nile igbafẹ kan l'Abuja.

Eyi mu ki EFCC tẹle awọn ọmọkunrin mejeeji lọ sile ti wọn n gbe, ti ayẹwo wọn si fihan pe, ọgọrun miliọnu Naira ni ọmọkunrin Orji ra ọkọ ayọkẹlẹ to n lo, ti ti ọrẹ rẹ, Kelvin Ilonah si jẹ miliọnu marundinlogoji Naira.

Bakan naa ni EFCC sọ pe, miliọnu mẹtala Naira l'ọdun ni ile ti ọkọọkan wọn n gbe.