Sani Abacha Loots: $6.5m ni ilẹ̀ Ireland fẹ́ fún Nàíjíríà lára owó tí olórí ológun tẹ́lẹ̀ jí kó

Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, Nigeria High Commision

Àkọlé àwòrán, Owo Abacha

Ko si ibi ti iranwọ ko ti lee dide fun ẹda, koda, oku gan n se iranwọ owo fun orilẹede Naijiria.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu owo ti adari ijọba ologun tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Oloogbe Sani Abacha n fi ransẹ lati ajule ọrun ri bayii.

Idi ni pe orilẹede Naijiria tun ti n reti owo miran to jẹ eyi ti Abacha ko pamọ lasiko to n dari orilẹede yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọtẹ yii, orilẹede Ireland ni owo to to miliọnu mẹfa ati aabọ dọla ($6.5m) ti n bọ, eyi to to biliọnu meji ati aabọ owo Naira ilẹ wa.

Àkọlé fídíò, The Polytechnic Ibadan: Ẹ̀rọ abẹ́lé tó ń fọ ọwọ́ àti ‘Ventilator’ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

Minisita feto idajọ ati agbẹjọro agba, Abubakar Malami lo sisọ loju ọrọ yii fun ileesẹ akoroyinjọ Reuters.

Minisita feto idajọ nilẹ Ireland, Helen McEntee ni owo naa jẹ eyi ti orilẹede rẹ gbẹsẹle lara owo ti Abach ji ko.

O ni ijọba ilẹ Naijiria ati Ireland si ti tọwọ bọ iwe adehun lori ọna ti wọn fi da owo naa pada silẹ wa.

Igba akọkọ si ree ti orilẹede Ireland yoo da owo Abacha pada eyi to gbẹsẹle lọdun 2014.

Àkọlé fídíò, Mr Macaroni sọ nípa eré tí Fraky freaky, Sugar Daddy, You are doing well, freaky spicy fẹ́

Owo naa si jẹ ara biliọnu kan dọla ti wọn gbẹsẹle jakejado agbaye.

Bẹẹ ba gbagbe, eyi kii se igba akọkọ ti orilẹede Naijiria yoo gba owo ti Abacha ji ko pada lati ilẹ okeere.

Losu Karun ọdun 2020 yii, Naijiria gba ọọdunrun miliọnu dọla owo Abacha lati ọwọ ijọba ilẹ Amẹrika ati ẹkun Jersey.

Owó Abacha sì kú, kò tíì tán, $319m kan sì wà ní UK àti France - Amẹ́ríkà

Abacha

Oríṣun àwòrán, @MaziAsochukwu

Ijọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tún ti sísọ lójú rẹ pé, owó tó to okoolelọọdunrun ó dín kan dọla ($319m), owó tí Abacha jí kò pamọ sì ìlú ọba, UK àti Faranse sì tún wà nilẹ.

Atẹjade kan ti ileesẹ aṣojú ìjọba Amẹ́ríkà fisita ni Ọjọru lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí pẹlu àfikún pé, ọgọ́jọ mílíọ̀nù àti méje dọla ($167m) ni Abacha ko pamọ sì ilẹ̀ Faranse nígbà tí mílíọ̀nù mejilelaadọjọ dọla ($152m) miran tún wà ní ilẹ̀ UK, tí wọn sì ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sile ẹjọ́.

Atẹjade náà ni owó tuntun yìí, tí àpapọ̀ rẹ jẹ bílíọ̀nù lọ́nà mejidinlọgọfa náírà, (N118bn) tún yàtọ̀ sí aadọsan mílíọ̀nù dọla ó dín mẹta ($167m) tí ìjọba ilẹ̀ UK àti Faranse gbé ẹsẹ le, tó fi mọ mílíọ̀nù mejilelaadọjọ dola ($152m) miran ti wọn n bá ìjọba UK ṣe ẹjọ́ le lori.

Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, ìjọba Nàìjíríà tí gbé ilẹ UK lọ sile ẹjọ́ láti gba àwọn owó náà, kò tó ko ìdá àádọ́rin fún Atiku Bagudu, tíì ṣe alájọsisẹpọ Sani Abacha, tí àdéhùn jọ wà láàrin òun àti ìjọba Nàìjíríà nípa owó náà.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn nǹkan mẹ́rin tó yẹ kó wà nínú báàgì rẹ lásìkò Covid-19 yìí

Sani Abacha tún pèsè ìrànwọ fún Nàìjíríà láti ipò òkú

Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, Nigeria High Commision

Àkọlé àwòrán, Owo Abacha

Akoójọ pọ iye ìgbà tí Nàìjíríà rí owó tí olórí ìjọba ológun tó ti di olóògbé, Sani Abacha kó pamọ si òkè òkun gbà, tó fi mọ $311m tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ransẹ lọ́jọ́ Ajé.

Láti ọdún 1998 tí olórí ìjọba ológun tẹ́lẹ̀, ọgagun Sani Abacha tí dagbere faye, ọ̀pọ̀ ìgbà ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí rí owó tó ko pamọ sókè òkun gbà padà.

Loore koore sì ni ìjọba àpapọ̀ máa ń kéde pé owó tuntun wọlé láti ara owó Naijiria ti Abacha kò pamọ sókè òkun, tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kò sì leè sọ iye tí àpapọ̀ owó náà jẹ́ báyìí.

Ìdí rèé tí BBC Yoruba fi ṣe ìwádìí nípa àkójọ pọ àwọn owó yìí, àwọn orílẹ̀ èdè tó tú àṣírí owó náà, tí wọn sì fún wa àti ọjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ tẹ́wọ́ gba owó náà.

Bi ẹ bá sì rántí, ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrin, oṣù karùn-ún ni ìjọba Naijiria tún kéde pé, òun rí owó tó lè díẹ̀ ni mílíọ̀nù lọ́nà okoolelọọdunrun ó dín mẹsan an dọla ($311,797,866m) miran gbà padà láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà,

Eyi jẹ nínú owó ilẹ wá ti olórí ìjọba ológun náà fi ọ̀nà aitọ kó lọ sókè òkun.

Èyí sì ni àkójọ pọ owó ti Sani Abacha kò lọ sókè òkun, tí Nàìjíríà tí gbà pada:

* Oṣu karun un, ọdun 2002:

Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo bá ìdílé Sani Abacha ṣe ẹjọ́ láti gba bílíọ̀nù kan àti ìgbà mílíọ̀nù dọla pada ni oṣù karùn-ún, ọdún 2002

Oṣu kọkanla, ọdun 2003:

Minisita feto isuna lọ́dún 2003, Ngozi Okonjo-Iweala kéde pé Nàìjíríà tún ti rí mílíọ̀nù lọ́nà mọkandinlaadọjọ dọla ($149m) gbà láti Jersey Island.

Nínú owó tí Abacha jí kó lọ sókè òkun, ní oṣù kọkànlá ọdún 2003.

Àkọlé fídíò, Irokotọla: Báwo ló ṣe rọrùn láti fi àmì sí ọ̀rọ̀ yìí, ‘Irokotọla’

*Oṣu kẹsan an, ọdun 2007:

Minisita feto isuna lọ́dún 2007, Nenadi Usman náà tún kéde pé, Nàìjíríà tún ti rí bílíọ̀nù méjì àti àbọ̀ dọla ($2.5bn) owó tí Sani Abacha kó pamọ sókè òkun gba.

Ó ní owó ohun ni ìjọba pín fún ileesẹ tó wà fún ohun amusagbara, isẹ òde, eto ìlera, ètò ẹ̀kọ́ àti ohun àlùmọ́ọ́nì inú omi láti fi ṣe àkànṣe isẹ.*Ọdún 2014:

Minisita feto isunna, Ngozi Okonjo-Iweala tún padà kéde pé mílíọ̀nù lọ́nà ẹẹdẹgbẹta dọla ($500m), tí ìjọba Olusegun Obasanjo tún rí gbà lára owó tí Sani Abacha kò lọ sókè òkun,

táwọn sì ti lo owó náà fún isẹ ìdàgbàsókè agbègbè.

Àkọlé fídíò, Asa Trokosi nibi ti ọmọde ti n jiyan ẹsẹ mọlẹbi rẹ , wọpọ ni Ghana, Togo ati Benin.

*Oṣu kẹfa, ọdun 2014:

Nígbà tó tún di oṣù kẹfà, ọdún 2014 ni Lienchtenstein tún dá mílíọ̀nù lọ́nà okòólénígba àti méjì dọla ($227m) padà fún Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi ara owó tí Sani Abacha jí kò lọ sókè òkun*Oṣu kẹjọ,ọdun 2014:

Ileesẹ ètò ìdájọ́ ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní ọjọ́ keje, oṣù kẹjọ ọdún 2014 kéde pé, owó tó tíì pọju nínú ìtàn orílẹ̀-èdè náà, tí àwọn yóò tíì dá padà ní mílíọ̀nù lọ́nà ọrinlenirinwo dola ($480m),

Eyi tàwọn fẹ́ gbé fún ìjọba Nàìjíríà, tíì ṣe ara owó tí Sani Abacha fi ẹyin pọn wá si orílẹ̀ èdè awon*ọdún 2016:

Orílẹ̀ èdè Switzerland náà fìdí rẹ múlẹ̀ pé, òun ti dá owó tó tó mílíọ̀nù lọ́nà okoolelẹẹdẹgbẹrin àti mẹta dọla ($723m) padà fún ìjọba Nàìjíríà lára owó tí Abacha jí kò, táwọn si gbé ẹsẹ le lọ́wọ́ mọlẹbi rẹ

*Oṣu kejila, ọdun 2019:

Oṣù Kejìlá, ọdún 2019 ni orílẹ̀-èdè Switzerland tún kéde pé, òun fe dá mílíọ̀nù lọ́nà

Okoolelọọdunrun àti ẹyọ kan dọla ($321m) padà fún ìjọba Naijiria lati inu owó tí Sani Abacha ko lọ sókè òkun

*Ọjọ karun un, oṣu karun un, ọdun 2020:

Ìjọba Nàìjíríà kéde pé, òun tún ti gba owó tó lè díẹ̀ ni mílíọ̀nù lọ́nà okoolelọọdunrun ó dín mẹsan an dọla ($311,797,866m) míràn gba lọ́wọ́ ilẹ Amẹ́ríkà lára owó tí Sani Abacha ko lọ sókè òkun.

Owó wọgbó! Gẹ̀ẹ́sì gbẹ́sẹ̀ lé ₦82bn owó Abacha

Abacha Loot: Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rí owó Abacha bíi owó ọ̀daràn, ló ṣe gbẹ́sẹ̀ le

Wọ́n tún ti rí lára owó tí olórí orílẹ́èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, olóògbé Sani Abacha kó lọ sílẹ̀ òkèrè.

Ẹgbẹlẹgbẹ owo to to biliọnu mejilelọgọrin naira (£211m) to jẹ ti olori tẹlẹ fun orilẹede Naijiria, oloogbe Ọgagun Sani Abacha, ni wọn ti ri nile ifowopamọ Jersey bank nilẹ okeere.

Abacha, to jẹ olori orilẹede Naijiria laarin ọdun 1993 si 1998 to ti jalaisi, niroyin sọ pe o kowo naa lọ si Channel Islands nilẹ Yuropu, lati ilẹ Amẹrika.

Iwe iroyin Metro nilẹ Gẹẹsi fidi rẹ mulẹ pe, ninu apo aṣuwọn ile iṣẹ Doraville Properties Corporation ni ile ifowopamọ Jersey ti ri owo naa.

Ni bayii, ijọba ilẹ Gẹẹsi ti gbẹsẹ le owo naa titi digba ti awọn alaṣẹ Jersey, ilẹ Amẹrika ati Naijiria ba sọ asọyepọ lori bi wọn yoo ṣe pin owo naa.

Ijọba ilẹ Gẹeṣi maa n gbẹsẹ le owo kowo ti wọn ba ri ni ilu Jersey, ijọba maa n ri owo bẹe bi owo ti awọn ọdaran ji ko.

Àkọlé fídíò, Ladoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Ijọba maa n lo iru owo bẹẹ fun idagbasoke agọ ọlọpaa kaakiri ilẹ Gẹẹsi, ati fun awọn oriṣiiriṣii akanṣe iṣẹ miiran.

Ẹgbẹlẹgbẹ owo ti oloogbe Abacha ko pamọ silẹ okeere nigba to wa lori oye ni ijọba Naijiria ti gba.