Akinyele Killings: Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Ibadan fẹ́ fi owó kún móríya ẹni tó bá rí Sunday Shodipe

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpinlẹ̀ Oyo ni ọ̀rọ̀ Sunday Shodipe tó sálọ ní àhámọ́ ọlọ́pàá jẹ́ ǹkan to n kọ àjọ ọlọ́pàá lóminú gidigidi.
Agbẹnusọ ilé iṣẹ ọlọ́pàá ló fidi ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lásìkò tó n ba BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ lóri ibi ti wọ́n bá iṣẹ́ dé lójúnà ati ri Sunday Shodipe, agbénipa to sá lọ lágọọ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Oyo.
O ní ìgbarata àjọ ọlọ́pàá ju ti àrá ilú lọ nítorí ọ̀rọ̀ náà ti fẹ́ mu ìtìjú dání fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, "ṣùgbọ́n ti o ba ku pé ki a fi owó kún owó ẹbùn móríyá fún ẹni to bá bá ọlọ́pàá kẹ́fin Sunday ti yóò si sọ fun ọlọ́pàá, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣetán láti ṣe bẹ́ẹ̀".
- 'Ẹ̀pa ò bóró mọ́! Òkú ọmọ ọdún mẹ́ta tó kó sí kàǹga ní Ipaja ni wọ́n yọ'
- Ta ni arẹwà obìnrin yí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ kó di àárẹ wọn?
- Ọmọ márùn-ún sọnù ní Otto l‘Eko, àwọn ìyá wọn kò jẹ́ èèyàn mọ́ lẹ́yìn ọdún kan
- Coronavirus bí èso rere nílẹ̀ Adúláwọ̀, wo díẹ̀ lára èso náà...
- Ìròyìn ayọ̀! Kùrù-kẹrẹ Coronavirus ṣeéṣe kó dópin láàrín ọdún méjì - WHO

Oríṣun àwòrán, Police
Ó ni ǹkan tó ṣe pàtàkì jùlọ ní pé ojú méjéjì ni ọlọ́pàá fí n wá ọmọkunrin náà ki àṣírí gbogbo àwọn to wu ìwà ìbàjẹ́ náà láàrín àwọn ọlọ́pàá baà le tú.
Agbẹnusọ ọlọ́paàá tún rọ ará ìlú láti ran ọlọ́pàá lọ́wọ́ láti jẹ́ ki àwọn mọ́ ti wọn ba kofìrí rẹ̀, ibi ti ó ń rìn sí kí gbogbo àṣírí tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà le ba tú.
Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá tí kọ́kọ́ kéde ẹ̀bùn owó #500, 000 fún ẹni tó bá rí Sunday Shodipe, afurasí tó sọnù lórí ikú àwọn èèyàn Akinyẹle

Oríṣun àwòrán, Nigeria police force
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira gẹgẹ bi owo ti oun yoo fun ẹnikẹni to ba le e ṣamọna bi wọn ṣe le e mu afurasi to lọwọ ninu iṣekupani to waye ni ipinlẹ naa, Sunday Shodipe.
Ṣaaju ni Shodipe ti kọkọ sa mọ awọn ọlọpaa naa lọwọ lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ́ lori ẹsun pe o lọwọ ninu ọpọ ẹmi to sọnu lagbegbe Akinyele, ni ilu Ibadan.
Ọpọ awọn olugbe ilu Ibadan lo tu sita fun ifẹhonuhan lẹyin ti iroyin jade pe afurasi naa ti salọ mọ awọn agbofinro lọwọ.
Ṣugbọn ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọ pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ni ileeṣẹ naa yoo fun ẹnikẹni to ba le e ranwọn lọwọ lati ri Shodipe mu nigba keji.
O ni "Kọmiṣọnna ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fẹ fi to awọn eeyan leti pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ni ileeṣẹ naa yoo fun ẹni to ba le e ran an lọwọ lati ri afurasi naa mu."
- Ẹ̀yin gómìnà, Ifá nìkan ló le tọ yín sọ́nà láì kùnà lórí Amotekun - Babaláwo
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ sí Mamman Daura àti ìlera rẹ̀?
- Ilé ẹjọ́ yá lórí òfin CAMA tó fẹ́ gba àkóso ilé ìjọsìn, tẹ ẹ̀tọ́ aráàlú mọ́lẹ̀ - SERAP
- Ikú Williams Aanuoluwa lágbo òṣèré hú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ síta
- Adamu Adamu, Minista ètò ẹ̀kọ́ ti fi òfin àátẹ̀lẹ́ síta kí àwọn ilé ìwé lè wọlé
Fadeyi ni: "Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2020 ni ọwọ tẹ ẹni ọdun mọkandinlogun ọhun ti ileeṣẹ ọlọpaa si fi oju rẹ lede, ṣugbọn o salọ mo wọn lọwọ ni ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020."
Lẹyin naa lo rọ awọn ara ilu lati fa ọdaran ọhun le awọn agbofinro lọwọ ni kete ti wọn ba gba a mu.
- Wo àmúyẹ kí o tó lè di ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà pẹ̀lú fọ́ọ́mù tó jáde yìí
- Adamu Adamu, Minista ètò ẹ̀kọ́ ti fi òfin àátẹ̀lẹ́ síta kí àwọn ilé ìwé lè wọlé
- Ṣé òótọ́ ni pé ìgbẹ́ erin le è wo arùn Coronavirus sàn?
- Ọdún Hijri mùsùlùmí tuntun wọlé dé, ẹ wo kókó pàtàkì nípa rẹ̀
- Wo ìdí tí Osun fi kede ìsinmi fún ọdún ìṣẹ̀ṣe, tàwọn ìpínlẹ̀ yókù kò dáhùn,

Oríṣun àwòrán, Twitter/ seyi makinde
Makinde ti sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí asekúpani Akinyele sálo mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ ní àhámọ́
Gomina Ọyọ, Seyin Makinde ti sọrọ fun igba akọkọ lẹyin ti afurasi to lọwọ ninu iku ọpọ obinrin ni Akinyele, Sunday Shodipe, sa kuro ni ahamọ awọn ọlo
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyin Makinde ti sọrọ fun igba akọkọ lẹyin ti afurasi to lọwọ ninu iku ọpọ iku awọn obinrin ni Akinyele, Sunday Shodipe, sa kuro ni ahamọ awọn ọlọpaa.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ fi ṣikun ofin mu Sunday lori iku Barakat Bello, Azeezat Shomuyiwa ati ọmọdekunrin ẹni ọdun marun un kan lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2020.
Ṣugbọn lẹyin nnkan bi oṣu kan lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ ninu atẹjade kan pe ọdanran ọhun ti salọ ninu ahamọ to wa.
Alukoro ileeṣẹ naa, Olugbenga Fadeyi sọ pe wọn ti gbe ọdaran naa lọ sile ẹjọ ko to fẹsẹ fẹ.
Wayii o, gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti wa paṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa lati wa ọdaran naa ri pẹlu gbogbo ọna ti wọn ba lee gba.
Nigba to n ṣuju Makinde nibi ipade ita gbangba kan pẹlu awọn olugbe Akinyele, olubadamọran Pataki lori eto abo, Fatai Owoseni sọ pe, ki awọn ọlọpaa sa gbogbo ipa wọn lati tun ọdanran naa mu.
O ṣalaye pe afujusun ijọba Makinde ni lati daabo bo awọn eeyan ipinlẹ Oyo, o si rọ wọn pe ki wọn má ru ofin lori iṣẹlẹ ọhun.
O ni "Gbogbo wa la mọ ohun to ṣẹlẹ ni Akinyele, a mọ bi awọn ọlọpaa ṣe mu afurasi, bẹẹ la si tun gbọ bo ṣe salọ mọ lọwọ."
Gomina Seyi Makinde ni: "A mọ pe awọn eeyan ni ẹtọ labẹ ofin lati ṣe ifẹhonuhan lẹyin iru iṣẹlẹ bayii, ṣugbọn a n rọ ẹyin eeyan wa lati ma dalu ru tabi ba dukia jẹ nitori pe ẹ n ṣefẹhonuhan lori iṣẹlẹ yii."
Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan agbegbe Akinyele lati máa ba iṣẹ oojọ wọn lọ nitori awọn ọlọpaa yoo ṣe ojuṣe wọn lati tun ọdaran ọhun mu ati lati daabo bo awọn eeyan ọhun.
- Iná sọ lóòtọ́ láàfin mi, ṣùgbọ́n kò sí gìrí- Ooni Ile Ife
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
- Wo ibùdó arẹwà tí ọ̀pọ̀ èrò ń ya lọ ní Abuja
- Olólùfẹ́ mi ṣèèsì fi ọkọ́ gbá mi sí gọ́tà, mo rò pé ọlọ́jọ́ dé ni - Iya Osogbo
- Ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gíga n‘Ibadan ṣèwọ́de lọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórí afurasí tó dàwátì

Oríṣun àwòrán, others
Ìpànìyàn tún wáyé ní Akinyele, àwọn ará àdúgbò ṣe ìwọ́de
Àwọn afurasí elétùtù ọlà ṣá obìnrin kan yánna-yànna nítosí Olorunkole
Rogbodiyan bẹ silẹ ni agbegbe Akinyele ni ọjọ Ẹti nitori iku arabinrin kan ti iroyin sọ pe awọn kan fi àdá ṣa yanna-yanna ni agbegbe naa nirọlẹ Ọjọbọ.
A gbọ pe ni agbegbe Ori-Oke Olorunkole ni iṣẹlẹ naa ti waye ni Ọjọbọ, ti awọn kan si gbagbọ pe awọn to n fi eeyan sẹ oogun owo lo ṣa obinrin naa.
Iroyin sọ pe wọn sare gbe obinrin naa digba digba lọ si ileewosan UCH nilu Ibadan, ṣugbọn o pada gbẹmi mi.
Eyi la gbọ pe o bi awọn ọdọ adugbo ninu, ti wọn si bẹrẹ si ni ṣe iwọde.
Ṣugbọn iwọde wọn naa di wahala, debi i pe wọn kọlu awọn ọlọpaa.
Ipaniyan to n lọ si bi i meje lo ti waye ni agbegbe Akinyele laarin oṣu mẹta, ti ọpọ si n sọ pe awọn to n fi eeyan ṣe oogun owo lo n pa awọn eniyan naa.
Ninu oṣu Kẹfa nikan, eeyan bi i marun un ni wọn pa, lara eyi ti ọmọdekunrin, ọmọ ọdun marun un kan wa.
- Lẹ́yìn tí wọ́n fi kakata hú gbogbo iṣú àti ẹ̀gẹ́ mí, wọ́n tún ṣá àwọn ọmọ mi ládàá-Guru Maharaj Ji
- Àwọn aṣekúpani tún ti pa ọmọ ọdún 16 ní Akinyele nípìnlẹ̀ Oyo
- Ìyá Barakat fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí gbogbo àwọn tó nawọ́ síi lẹ́yìn ikú ọmọ rẹ̀
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
Bẹẹ naa ni Barakat Bello, ọmọbinrin ọdun mejidinlogun, ti wọn fi ipa balopọ, ki wọn o to o pa si ile awọn obi rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa kede laipẹ yii pe ọwọ tẹ awọn afurasi kan lori awọn ipaniyan naa, ipaniyan ko ti i dawọ duro.
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìjàmbá láì gbé ìbọn!
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ìjọ tó fi ìpá bá ọmọ pásítọ̀ rẹ̀ sùn ní ìpínlẹ̀ Ondo sí ẹ̀wọ̀n gbére
- Àwọn ẹgbẹ́ Tijjaniyya ti yọwọ́ kílàńkó Yahaya Sharif kúrò láwo ẹgbẹ́ wọn ní Kano
- "Mi ò ní wọ Uber mọ́ tí wọ́n bá leè fi owó lée nítorí àfikún owó orí tí Sanwo Olu ṣe"
- Ilé ayé mi ti d'ojú bolẹ̀ pẹ̀lú ikú àfẹ́sọ́nà mi- àfẹ́sọ́nà Immaculate Okochu
- Ogundipe gbé fásitì Unilag ló sí iléẹjọ́ nítórí wọn yọ́ ní ipò VC



















