Ooni ile Ife: Iná sọ láàfín Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Ọọ̀ni ilé ifẹ̀ ní kò sí ẹ̀mí tó báa lọ

aafin Ọọni ile ifẹ

Oríṣun àwòrán, Ile oodua

Ina sọ ni ile Oodua tii ṣe afin Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi l'Ọjọbọ.

Atẹjade kan to jade lati aafin Ọọni Adeyẹye Ogunwusi fi idi iṣẹlẹ ijamba ina naa mulẹ.

Ile to jona ni aafin naa ni wọn sọ wi pe o jẹ ile Saarun Oodua, ẹni to jẹ ẹṣọ iṣẹdalẹ fun Ọọni ile Ifẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Bakan naa ni akọwe iṣakoso ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Ọṣun , Fatai Arẹmu pẹlu fi idi ijamba naa mulẹ to si tun ṣalaye pe awọn panapana ti bomi pa ina naa.

Amọṣa Ọọni ni ko si giri lori ina to jo naa nitori pe gbogbo nnkan ṣi wa ni sẹpẹ ati pe ko si ẹmi to ba iṣẹlẹ ijamba ina naa lọ.

Ooni

Oríṣun àwòrán, Others

Ooni Ifẹ bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lú ètò BBNaija nítorí ó tàbùkù àsà YorubaOoni ti Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja II ti ni ki ijọba Naijiria gbekile eto Big Brother Naija, ki wọn si fi eto miran rọpọ rẹ.

Ooni sọ eyi lẹyin ti o gbalejo ẹgbẹ ọdọ National Youth Council of Nigeria ni aafin rẹ to wa ni Ile Ifẹ, ni ipinlẹ Osun.

Ooni to bu ẹnu atẹ lu eto Big Brother Naija naa ni eto naa n fihan pe orilẹ-ede Naijiria ko ni awọn ọdọ to jẹ ọmọluwabi ati oninu irẹ.

Oba Ogunwusi wa rọ ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣe ada nipa wiwa eto miran ti yoo safihan asa ati iṣe ni orilẹ-ede Naijiria ati awọn ihuwasi to buyi kun eniyan lawujọ.

O ni ki wọn pe akọle eto tuntun naa ni "The Big Nigeria Reality Show"

''Eto naa yoo ma a ṣe afihan awọn ọdọ lorilẹ-ede Naijiria ti wọn n sisẹ ọwọ, awọn ọdọ akọṣẹmọṣẹ ati awọn oṣiṣẹ to wa ni awọn ẹka iṣejọba ni Naijiria, lọna ati le de ipele to gajulọ ninu iṣẹ ti wọn yan laayo."

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Ọọni ṣalaye pe: ''Eyi yoo fun awọn oluworan lanfaani lati le ma a ri wọn gẹgẹ bi awokọṣe ni awujọ.''

Ooni ti ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja II ni o ṣeni laanu pe lasiko idibo gbogboogbo to waye ni Naijiria ni ọdun 2019, eniyan miliọnu mẹtadinlọgbọn lo jade lati dibo, amọ, eniyan ẹgbẹrun lọna aadọrin lo dibo lasiko eto Big Brother Naija ni ọdun 2019.

Ooni ni eleyii fihan pe awọn ọdọ lorilẹede Naijiria fẹran afẹfẹyẹyẹ ati ohun ti ko ni bun iyi kun iṣẹ ọwọ wọn.

Oba Adeyeye Ogunwusi ni pe gbogbo igba ti oun ba ti sọ iru ọrọ yii, awọn eniyan a fi ṣe awada, wọn a si gbagbe nipa ẹ.

Ooni ti ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja II ni iṣẹ gbogbo wa ni lati mu idagbasoke ba awọn eniyan, paapaa ọdọ lorilẹ-ede Naijiria.