Kano lack of burial ground: Àìtó ibójì ti ń fa awuyewuye ní ìpínlẹ̀ Kano- Àwọn òṣìṣẹ́ ibojí

Kano

Awọn oṣiṣẹ iboji ni ipinlẹ Kano ti bẹrẹ si n ke sita nitori aito iboju ni ipinlẹ ọhun.

Lara awọn oṣiṣẹ naa ni iboji Abbatuwa ati Gidan Gona sọ fun BBC pe awọn ile iboji naa kere to bẹẹ ti wọn fi maa n sin oku meji papọ soju kan ṣoṣo.

Akọroyin ileeṣẹ BBC to ṣabẹwo si awọn iboji naa jabọ pe pupọ lara awọn ibi isinku ọhun lo fun papọ mọ ara wọn, koda ko si ibi ti eeyan le e gbe ọkọ gba wọle sibẹ.

Alakoso iboji Abbatuwa, Malam Danbaba Muhammad ni o yẹ ki ijọba ipinlẹ Kano kọ awọn iboji tuntun.

Danbaba ni "Nigba miran ti a ba fẹ sin oku, ni ṣe ni a maa n sin oku tuntun le eyii to ti wa nibẹ tẹlẹ."

O tẹsiwaju pe, "Nigba miran ẹwẹ, ti a ba ri oku to ti jẹra tan, niṣe ni a maa ko ẹgungun rẹ sapa kan, ti a o si sin oku miran le e lori."

Bakan naa lọrọ ri nile igbokusi Gidan Gona, to wa ni ijọba ibilẹ Tarauni, ti oṣiṣẹ rẹ kan ti ko ba fẹ ki BBC darukọ oun ni, ọku pọ ju iye iboji to wa lọ.

Ẹwẹ, igbimọ to n risi ọrọ iboji ni Kano sọ pe oun mọ nipa ipo ti awọn iboji ipinlẹ naa wa, oun si ti fi ọrọ naa to ijọba leti.