Lagos State Assembly: Ó takò òfin kí àwọn obí jẹ̀yà ti ọmọ ba darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ajafẹtọ ọmọniyan ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Ile Igbimọ Aṣofin ni ipinlẹ Eko lati buwọlu abadofin ti yoo faaye gba ki awọn obi pin ninu iya ti ọmọ wọn to ba n ṣe ẹgbẹ okunkun yẹ ko jẹ.
Eyi ko ṣẹyin bi abadofin naa ṣe kọja ipele kika kẹta ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.
Agbẹnusọ fun Ile Igbimọ Aṣofin nipinlẹ Eko, Mudashiru Obasa to fi idi ẹ mulẹ wi pe lootọ ni wọn n gbe abadofin naa yẹwo.
- Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka
- Joe Biden kéde Kamala Harris, obìnrin aláwọ̀ dúdú gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ nínú ìdíje sípò Ààrẹ Amẹrika
- Wo ìdí tí Risikat Moromoke Azeez n'Ilorin fi ní "Blue Eyes" - Dókítà
- NCDC kéde èèyàn 423 míràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà, 263 gbàwòsàn
Obasa ni ijọba lo kọkọ gbe abadofin naa wa fun wọn, ki ọmọ ile kan to da a laba pe ki awọn obi ni ipin ninu ijiya to tọ si ọmọ, nitori awọn obi naa kọ lati tọ awọn ọmọ wọn daradara.
O ni obi gbọdọ ma a mọ ohun ti ọmọ rẹ ba n ṣe ni gbogbo igba, nitori naa ni wọn gbọdọ pin ninu iya.
Kinni ofin sọ lori eyi?
Ṣe awọn obi yoo fi iṣẹ silẹ ati gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe lọna ati ri i pe wọn bojuto ọmọ?
Agbẹjọrọ to tun jẹ ajafẹtọ fun awọn ọmọde, Arabinrin Elizabeth Udeh ni ko si ofin kankan to sagbatẹru igbese ti ijọba ipinlẹ Eko fẹ gbe naa.
Udeh ni lọpọ igba, awọn obi kii mọ ohun ti awọn ọmọ wọn n ṣe ni ileewe giga nitori naa wọn ko le e pin ninu iya ẹṣẹ ti ọmọ ba ṣẹ.
‘Awọn ọmọ to wa ni fasiti ti dagba to lati mọ iyatọ laarin iwa rere ati iwa buburu.’

Oríṣun àwòrán, Others
Agbẹjọrọ Elizabeth ni: ‘Ki ni yoo ṣẹlẹ si obi to ba n gbe ni jina rere si ibi ti ọmọ rẹ ti n kẹkọ, ṣe iru awọn obi bẹẹ yoo tun fi oju wina ofin ti awọn ọmọ wọn ba ṣẹ?’.
‘Ṣe awọn obi yoo fi iṣẹ silẹ ati gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe lọna ati ri pe wọn bojutọ ọmọ?
Amọ, Agbẹjọrọ to tun jẹ ajafẹtọ fun awọn ọmọde naa, Arabinrin Elizabeth Udeh fikun un pe idi ti awọn obi fi le jẹbi ni ti wọn ba kọ lati bojuto ọmọ wọn,
Abi ti wọn ba fi ẹjọ ọmọ wọn sun pe wọn hu iwa buruku, amọ ti iya gbe lẹyin ọmọ rẹ lai ṣe iwadii to tọ lori ẹsun naa.
Ti iru eleyii ba ṣẹlẹ, wọn le fi iru awọn obi bẹẹ jofin nitori wọn kọ lati sa ipa wọn fun awọn ọmọ wọn.
‘Ijọba yẹ ki wọn kọ awọn obi ni ọna ti wọn yoo fi tọ ọmọluwabi lawujọ’
Bakan naa ni AgbẹjọroTaiwo Akinlami naa bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko naa to n da a laba lati ma a jẹ ki awọn obi pin ninu iya ti o tọsi ọmọ to ba n ṣe ẹgbẹ okunkun.
Taiwo Akinlami ni ẹnikẹni to ba ti ju ẹni ọdun mejidinlogun lọ lẹtọ labẹ ofin lati jẹjọ ẹsun ni ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Akinlami ni ika to ba ṣẹ naa lo yẹ ki ọba ge, nitori naa ti ko ba ti jẹ obi lo wuwa ibajẹ, obi ko gbọdọ jẹya ẹsẹ ti ko ṣe.
O ni kii ṣe obi nikan lo n tọ ọmọ lawujọ, iṣẹ gbogbo eniyan ni, nitorinaa gbogbo wa lo jẹbi.
Ti wọn ba ti mu awọn obi naa, wọn gbọdọ mu awọn Alfa, pasitọ, olukọ ati imaamu pẹlu awọn alabagbe ọmọ to ba ti wu iwa ibajẹ lawujọ tabi darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Bakan naa lo fikun pe ijọba yẹ ki wọn sa ipa wọn fun awọn obi nipa lila wọn lọyẹ nipa bi wọn ṣe le tọ ọmọluwabi lawujọ.
O ni jijẹ, mimu, ile ati idagbasoke ọmọ ṣe koko, eleyii ti ijọba kọ lati fi ṣe iranwọ fun awọn obi.
Amọ, Agbejọro naa fikun wi pe ari iru awọn obi bẹẹ ti ko bojuto ọmọ wọn, iru awọn yẹn le gba idajọ lọwọ ijọba.
- Àmọ̀tẹ́kùn gbéra! Kò séwu nínú ìdìbò tó ń bọ̀ l'Ondo àfi gìrì àparò- Akeredolu
- ‘Àwọn òlóṣèlú kò ní ìwà ọmọlúwàbí ló jẹ́ kí wọ́n má a lọ láti ẹgbẹ́ òṣèlú kan lọ sí òmìràn’
- Òògùn ìtura dé fún Coronavirus! Ọ̀dọ̀ fásitì jànkàn Oxford ló ti jáde
- NCDC kéde èèyàn 423 míràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà, 263 gbàwòsàn
- À kò gba owó kankan lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí ISWAP- MURIC













