Ondo 2020 Election: Ọmọlúwàbí ṣọ̀wọ́n láàrín àwọn òlóṣèlú ló jẹ́ kí wọ́n má a lọ láti ẹgbẹ́ òṣèlú kan sí òmìràn - Gbenga Abimbola

Oríṣun àwòrán, Others
Onimọ nipa eto oṣelu lorilẹede Naijiria, ọmọwe Olugbenga Abimbola ti ni aini iwa ọmọluwabi lo n mu ki awọn oloṣelu ma a kuro ni ẹgbẹ oṣelu kan lọ si omiran.
Ọmọwe Abimbola sọ eyi lasiko to n fesi si bi eto oṣelu ṣe n lọ ni ipinlẹ Edo ati Ondo saaju idibo sipo gomina ti yoo waye nibẹ.
O ni iwa ọmọluwabi sọwọn laarin awọn oloṣelu ni wọn ṣe n kaakiri ẹgbẹ oselu ati wi pe awọn ẹgbẹ oṣelu naa ko ni afojusun ohun ti wọn fẹ ṣe fun ilu, eleyii ti wọn ma n pe ni ''party ideology''.
- Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi tẹ bàbá àti ìyàwó rẹ̀ méjì fún pé wọn so ọmọ pọ̀ mọ́ ewúrẹ́ fún ọdún méjì
- Orílẹ̀-èdè Chad pé ọgọ́ta ọdún, àwọn ara ìlú ń pariwo lábẹ́ Aàrẹ Deby tó gba 'Field Marshal'
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
''Íwa inu awọn oloṣelu ni ko dara, kii se pe eto iṣejọba Naijiria ko i tii dagba to lẹyin ọdun mọkanlelogun.''
''Ọpọlọpọ awọn oloṣelu n tan awọn araalu jẹ ni wọn ṣe n kuro ni ẹgbẹ oṣelu kan lọ si omiran.''
O ni Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo ni lọkan lati di gomina ni o ṣe lọ darapọ ẹgbẹ oṣelu ZLP ti yoo fun ni anfaani lati dije dupo, eleyii ti o lẹtọ si labẹ ofin.

Oríṣun àwòrán, Others
Onimọ nipa eto oṣelu lorilẹede Naijiria, Dokita Olugbenga Abimbola naa ni awọn oludije mẹta gboogi lo ti suyo ninu idibo ipinlẹ Ondo bayii.
Eleyii to fihan gbangba pe Gomina Akeredolu ti ẹgbẹ Oṣelu APC yoo di ariwa ipinlẹ Ondo mu nibi ti o ti wa, Jegede ti ẹgbẹ oṣelu PDP yoo di gbungun mu ni ibi ti o ti ṣẹ wa, nigba ti Agboola Ajayi ti ẹgbẹ oṣelu ZLP yoo di guusu mu ni ibi ti o ti wa.
- Àjọ JAMB kéde ìlànà ìgbà ni wọlé tuntun fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga
- Ọwọ́ ikọ̀ aláàbò STF tẹ afurasí mẹ́jọ tó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn lemọ́-lemọ́ọ Gúúsù Kaduna
- Èèyàn 290 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ fara káásá àrùn Covid-19 ní Nàìjíríà, 160 gbàwòsàn
- Ọwọ́ ikọ̀ aláàbò STF tẹ afurasí mẹ́jọ tó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn lemọ́-lemọ́ọ Gúúsù Kaduna
Amọ o ni ipolongo ẹlẹkundẹkun ni yoo fihan bi awọn eniyan ṣe fẹran awọn oludije naa si.
Nitori naa ko si ẹni to le e sọ ẹni ti yoo bori eto idibo ipinlẹ Ondo, afi esi idibo ti ko ni magomago ninu ni yoo fi ero awọn eniyan han.
Ṣaaju ni Ogbeni Agboola ti sọrọ lori bi ZLP ṣe tẹwọ gba oun:
Ẹgbẹ́ òṣèlú ZLP gbàmí tọwọ́tẹsẹ̀ láti díbò gómínà ní Ondo- Agboola Ajayi
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi ti ni ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party gba oun tọwọ-tẹsẹ ni oun fi fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati lọ dije dipo gomina ninu idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo.
Agbẹnusọ fun Agboola Ajayi, Allen Sowore lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.
Sowore ni awọn oloye ẹgbẹ oṣelu ZLP ni apapọ ti fun Agboola ni anfaani lati dije sipo gomina labẹ ẹgbẹ naa.
- Wo bí ìgbéyàwó ọmọ bàbá olówó, Adama Indimi àti Prince Malik Ado ọmọ Ọba Ohinoyi ilẹ̀ Ebira ṣe lárinrin tó
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200
- Ìyàwó Bukola Saraki fún tìyá-tọmọ olójú búlúù ní N250, 000!
- Makinde júwe ilé fún Kọmíṣọ́ná iṣẹ́ òde, ó ṣe pàsípàrọ̀ àwọn kọmíṣọ́nà méjì míì
O ni awọn eniyan lo paṣẹ fun oun lati lọ si ẹgbẹ miran lati lọ dije dupo fun gomina nitori oun ni awọn fẹ.
Bakan naa ni Sowore ni lilọ kuro lẹgbẹ oṣelu kan lọ si omiran ko le e nipa buburu lori ati debi ipo gomina rẹ, nitori nkan ti awọn eniyan fẹ ni o ṣe.
''Iru ẹ ko ṣẹṣẹ ma a ṣẹlẹ ninu oṣelu Naijiria nitori eto oṣelu ni Naijiria ṣe n dagbasoke ni, nitori naa ni awọn oloṣelu ṣe n kaakiri lati ẹgbẹ kan si omiran.''
'' Oloṣelu ko le e duro si ojukan naa. Bakan naa ni kikuro to kuro lati APC lọ si PDP lọ si ZLP ko le e ni ipa buburu ninu irinajo naa.''
Agbẹnusọ fun Agboola Ajayi, Allen Sowore ni awọn araalu lo ma a yan ẹni ti wọn fẹ ko ṣe adari fun wọn ninu idibo to n bọ.
Sowore fikun pe awọn nigbagbọ wi pe awọn yoo bori ninu idibo to n bọ ninu awọn ololufẹ rẹ ni APC, PDP ati ZLP yoo dibo fun un.
Ìdí rèé tí igbákejì Gómìnà Ondo Agboola Ajayi tún ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀
Ti iwaju ko ba ṣe lọ, ẹyi a ṣe e pada si. Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi tun fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.

Oríṣun àwòrán, @Agboola
Ninu atẹjade kan ti oludamọran Ọgbẹni Agboola fi sita, igbakeji Gomina Ondo kọwe fipo rẹ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ PDP lọjọ Aje, ọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun yii(2020).
Ajayi to kuna ninu idibo abele fun ipo gomina ninu eyi ti Eyitayo Jegede ti jawe olubori mu iwe to fi ẹgbẹ naa silẹ lọ si olu ileeṣẹ ẹgbẹ PDP to wa ni wọọdu Apoi keji niluu Kiribo, ijọba ibilẹ Ese Odo.
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Buruji Kashamu jẹ́ ènìyàn tó nífẹ̀ aráàlú- Gómínà Dapo Abiodun
- Baba Obasanjọ kò ní àrùn Coronavirus- NCDC
- Kí ló mú Obasanjo ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹbí, òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ ní ibi òkú àna rẹ̀?
- Funke Akindele fún mi lówó tí mo fi gba ilé, kò ra ilé fún mi o - Ajirebi
- Mínísítà fún ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá tí fi ẹ̀bùn owó ránṣẹ́ si ìyá Kausara, ó tún jẹ́jẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ f'áwọn ọmọ rẹ̀
Nigba to n ki awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP fun atilẹyin niwọn igba ranpẹ ti o fi jẹ ọmọ ẹgbẹ naa, Ajayi ni oun gbe igbesẹ lati fi ẹgbẹ naa silẹ nitori awọn eeyan ipinlẹ Ondo fẹ ki oun dije fun ipo gomina ninu ibo to n bọ.
Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu Apoi keji, Ọgbẹni Festus Oboro ti tẹwọ gba ikọwefiposilẹ igbakeji gomina Ondo gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ naa.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹfa, ọdun yii ni Ọgbẹni Ajayi darapọ mọ PDP niluu rẹ, Kiribo nibi to ti dije ninu ibo abẹle fun ipo gomina ipinlẹ Ondo.
Ọgbẹni Ajayi rọ awọn alatilẹyin rẹ pe ki wọn ma ni ọkan, o ni oun yoo kede igbesẹ to kan fun oun laipẹ.
Àwọn alágbára ni mo bá díje ṣùgbọ́n mo ti gbà f'Olọrun- Agboola Ajayi
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi ti ṣalaye idi ti o fi fidirẹmi ninu idibo abẹle lati yan oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ naa lẹgbẹ oṣelu PDP.
Ninu atẹjade to fi sita lẹyin ibo abẹle naa, Agboọla ni awọn alagbara ti ko lẹgbẹ loun dojukọ lo jẹ ki oun fidirẹmi.
Amọṣa, o ni bi o ti wu ko ri, oun ti gba ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ sọ ati ẹni ti wọn yan.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, laipẹ yii ni Agboọla fi ọga rẹ tẹlẹ, Rotimi Akeredolu silẹ ti o si ṣi wa si ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi ara ọna lati dije fun gomina ni ipinlẹ naa.
Kii ṣe iroyin tuntun mọ bayii pe Eyitayọ Jẹgẹdẹ ni wọn dibo yan gẹgẹ bii ẹni ti yoo gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa lasiko idibo gomina ipinlẹOndo ti yoo waye lọjs Kẹwaa oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Ninu awọn aṣoju ọmọ ẹgbẹ ẹgbẹrun meji ati mọlakanlelaadọfa to dibo abẹlẹ naa, Jẹgẹdẹ ni ọrinlelẹgbẹrin o le mẹjọ, 888, Agboọla to tẹlee ni ibo ọtalelẹgbẹta ati meje.

Oríṣun àwòrán, @Eyitayo
Eyitayọ Jegede (PDP) ló máa gbéná wojú Rotimi Akeredolu (APC) nínú ètò ìdìbò Ondo tó ń bọ̀!
Oṣù kẹwàá ọdún 2020 ní INEC à ṣetò ìdìbò míì ní ìpínlẹ̀ Ondo
Ni ìgbẹyin ohun gbogbo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ondo. Abajade wọn ti dori igba bayii.
- Wo bí ètò ìsìnkú Tolulope Arotile ṣe lọ nílùú Abuja
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano tí wọ́gilé ayẹyẹ lẹ́yìn ìrun ọdún Iléyá!
- Èmi Ọba tí wọ́n ń kó jẹ nígboro- Oluwo ti ilú Iwo
- Ta ni Yusuf Satia ti iku mu lọ?
- Wo àwọn Gómìnà Naijiria tí àrùn Covid-19 ti bá fínra
- Bàbá mi Aláàfin, ẹ ṣeun ẹ̀bùn owó tí ẹ fún èmí àti ọkọ mi- Lizzy Anjọrin
Ni ana, ọjọ kejilelogun, oṣu keje ni wọn bẹrẹ eto idibo naa nibi ti awọn Oludije mẹjọ ti pàda wako lati mọ ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ninu idibo to m bọ.
Loru mọju oni, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje ni awọn alamojuto idibo abẹlẹ naa kede abajade esi idibo ẹni to maa gba tikẹẹti PDP lati le di gomina Ondo.
Esi naa ree:
Eddy Olafeso - 175Ajayi Agboola - 657Banji Okunomo - 90Ayorinde Olabode - 95Boluwaji Kunlere - 33Ebiseni Olusola - 29Erewa Godday - 14Eyitayo Jegede - 888
Lẹyin ti wọn kede esi idibo yii ni wọn fa Eyitayọ Jegẹde kalẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe ko dide giri bi ọmọkunrin lati koju Arakunrin APC ati awọn aṣoju ẹgbẹ to ku ti wọn jọ maa dije idibo to m bọ naa.
- O ti lé ní ènìyàn mẹ́wàá tí ina jó gúrúgúrú nínú ìjàmbá tó wáyé ní Delta
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Hushpuppi ti kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n l'America? Ẹ wo àbájáde ìwádìí wa
- Donald Trump ti gbà pé Coronavirus yóò burú jáì kí ǹkan tó dára fún Amẹ́ríkà
- Wo bí ètò ìsìnkú Tolulope Arotile ṣe lọ nílùú Abuja
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano tí wọ́gilé ayẹyẹ lẹ́yìn ìrun ọdún Iléyá!
Ta ni yóò kojú Akeredolu fún ipò gómìnà Ondo?
Wo bí ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òṣẹ́lú PDP ṣe ń lọ ní ìlú Akure
Idibo ọhun waye lati ori ijọba kan si omiran.

- Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bá àwọn tí a jọ díje nínú ìdìbó abẹ́lé sọ̀rọ̀ kí àláàfíà léè jọba - Akeredolu
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa 'Awawa Boys', ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú
- Adarí àjọ NDDC, Pondei ṣetán láti sọ ohun tó mọ̀ nípa ìwàdíì tó bá ti gbádùn- NDDC
- Ọkùnrin kan pa ara rẹ̀ sínú ọgbà àjọ TRACE tó n mójútọ ìrìnnà ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Ogun
O le lẹgbẹrun meji awọn ọmọ oṣelu PDP to n kopa ninu idibo abéle naa.

Eyitayo Jegede, igabkeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi atawọn mii lo n kopa ninu idibo abẹle naa lati le e dupo dije ninu idibo sipo gomina ti yoo waye loṣu kẹwaa ọdun 2020.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Wọ́n ti fẹ̀sùn kan Agboola Ajayi pé ó tẹ ayédèrú ìwé ìdìbò níbi ìdìbò abẹ́lé PDP ní Akure

Awọn ọmọleyin ọkan lara awọn oludije, Eyitayo Jegede, ti sọ pe awọn alatilẹyin rẹ fariga pe, igbakeji gomina, Agboola Ajayi tẹ ayédèrú ìwé idibo wọle.
Wọn ni igbesẹ yii da rugudu silẹ lojuko ti eto idibo abẹle naa ti n waye, ṣugbon awon ti pana aawọ naa.
Ni bayii, iforukọsilẹ awọn oludibo ni wọn n ṣe lọwọ ki idibo gangan to bẹrẹ.
Eto iforukọsilẹ yii wọn n ṣe ni ijọba ibilẹ kọokan.


Ki lo ti nṣelẹ sẹyin?
Ondo PDP Primaries: Ìjà bẹ́ sílẹ̀ làsikò àyẹ̀wò àwọn olùdìbò láti yan ẹni tí yóò díjé fún PDP nií Akurẹ

Akọroyin BBC to wa nibi eto idibo naa to n waye ni Dome ni ilu Akurẹ ni ipinlẹ Ondo ti fidiẹ mulẹ pe edeaiyede bẹ silẹ nibudo idibo naa.
O ṣalaye pe eyi ko ṣẹyin awọn oludibo to jẹ aṣoju kan ti wọn yọ bébà idibo sita lati fi dibo.

Akọrọyin BBC ni awọn to n mojuto eto idibo naa kọ lati gba awọn ti ko ni ojulowo bébà idibo da ni nitori wọn ni ko tọna ni eyi to si fa ariwo nla.
S\ugbọn bayii, o ni awọn agbofinro ti pẹtu si aawọ naa ni eyi ti awọn to ni kaadi idibo si ti lọ gbaojulowo bébà idibo bi o ti yẹ.

Lọwọlọwọ ni awọn to ni ojulowo ohun eelo idibo ti bẹrẹ ayẹwo kaadi awọn ọmọ ẹgbẹ ati aṣoju bo ṣe yẹ
Eto ididbo yii ni yoo yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ PDP ti yoo si koju APC ati awọn oludije ẹgbẹ to ku ninu eto idibo fun ipo gomina to m bọ lọna

Wo bí PDP ṣe fẹ́ yàn olùdíje fún ipò gómìnà l'Ondo
Ta ni yóò kojú Akeredolu fún ipò gómìnà Ondo?
Eto idibo ipinlẹ Ondo yoo waye ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, others
Awọn oludije mẹwaa ni yoo maa dije du aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP loni fun idibo sipo gomina nipinlẹ Ondo ti yoo maa waye loṣu kẹwaa, ọdun 2020.
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi yoo maa wọ ṣokoto kan naa pẹlu kọmiṣọnna nigba kan ri fun eto idajọ ni ipinlẹ naa, Eyitayọ Jẹgẹdẹ atawọn eekan oludije miran.
Amọṣa awọn mejeeji yii ni awọn onwoye n foju si lara gẹgẹ bii irin meji ti ikan ko ni fẹ tẹ fun ọkan bọrọ.
Awọn miran to tun n dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu naa ni igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP fun ẹkun Iwọ Oorun Gusu orilẹede Naijiria, Eddy Olafẹsọ, Sola Ebiseni, Bọde Ayọrinde, Boluwaji Kunlere, Bamidele Akingboye, Banji Okunọmọ ati Godey Erewa.
Ṣaaju idibo naa lawọn kan lara awọn oludije naa ti fi ẹsun kan igbakeji gomina ipinlẹ naa, Agboọla Ajayi pe o ti ọwọ bọ iwe awọn aṣoju ọmọ ẹgbẹ ti yoo dibo ti o si ti rọpo rẹ pẹlu awọn ayederu aṣoju.
- Adarí àjọ NDDC, Pondei ṣetán láti sọ ohun tó mọ̀ nípa ìwàdíì tó bá ti gbádùn- NDDC
- Wo bí ètò ìsìnkú Isa Funtua ṣe wáyé ní ìlú Abuja
- Kí ló dé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kéde fífagilé Sáà ètò ẹ̀kọ́ kẹta fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́?
- Wo àwọn gómìnà Nàìjíríà tó tí lùgbàdì Covid-19 àti ipò tí ìlera wọ́n wà
- Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bá àwọn tí a jọ díje nínú ìdìbó abẹ́lé sọ̀rọ̀ kí àláàfíà léè jọba - Akeredolu
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, laipẹ yii ni Ajayi kogba kuro lẹgbẹ oṣelu APC lọ si PDP laarin wahala ati ede aiyede laarin oun ati gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu.
- Wo àwọn òṣìṣẹ́ kólẹ̀-kódọ̀tí tó ń fi ẹ̀mí wọn wéwu kí Abuja leè mọ́ tónítóní
- Ènìyàn 653 míràn tún kún iye àwọn tó ní COVID-19 ní Nàìjíríà
- Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bá àwọn tí a jọ díje nínú ìdìbó abẹ́lé sọ̀rọ̀ kí àláàfíà léè jọba - Akeredolu
- Èèyàn 576 míràn tún kún àwọn tó ní àrùn COVID-19 ní Nàìjíríà
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa 'Awawa Boys', ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú


















