Alaafin: Olori Aanu Adeyemi aya Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo ní ohun tó bá kúkú wu ọmọ láti jẹ kìí...
Gbogbo ohun ti mo fẹ́ ni mo n ri laafin Oba Lamidi Adeyemi- Olori Aanu
Ohun to wu mi ko wu ọ ni ọrọ Ayaba Aanuoluwapọ Adenike Adeyemi nigb ati BBC kan si Aafin Kabiesi ni ilu Oyo.
Olori yi wa lara awọn Olori to kere julọ ni aafin ti ọpọ maa n pe ni òló ẹlẹjẹ tutu ti Baba fi n mi lasiko yii.
O jẹ ọmọ ipinlẹ Osun (Ile Ife ati Ede) o si gbe ni ilu Ibadan dagba.
Olori Aanu ṣi n kawe lọwọ ni fasiti ọlọgba ẹranko nibi ti sanmọnti gbe dunlẹ ni ilu Ibadan UI nibi to ti n kọ imọ ijinlẹ nipa oṣelu.
- Èèyàn 290 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ fara káásá àrùn Covid-19 ní Nàìjíríà, 160 gbàwòsàn
- Wọ́n ti sún ọjọ́ ìjà Mike Tyson pẹ̀lú Roy Jones Jr síwájú
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter

Olori Aanu ṣalaye pe oun pinnu pe oun gbọdọ ni ifọkanbalẹ nile ọkọ lo jẹ ki oun fẹ Alaafin ti ọpọ maa n sọ pe o ti dagba ju oun lọ pupọ ju.

Olori Aanu ṣalaye fun BBC gbogbo nkan to wu oun ti ọkan oun n fẹ ni Alaafin n pese fun oun ati pe gbogbo olori ni Oba fẹ ki wọn kawe lo ṣe n ran gbogbo wọn nile iwe.

Olori ni ooreọfẹ Olorun loun n jẹ laafin.
O sọrọ lori ajọṣepọ awọn olori keekeeke ati agba pe ibọwọfagba ati irẹlẹ ni oun n kọ sii lojoojumọ ni aafin.
Olori Adenikẹ tun sọ nipa ẹkọ asa ati iṣe ati oriki ti oun ti gba ni aafin ati pe oun yoo fi kọwe nipa eto idajọ Alaafin lọjo ọla.

Olori ni onikaluku lo mọ idi to fi fẹ ọkọ rẹ ati pe oun ko kabamọ pe oun fẹ Kabiesi.
Ohun to ba wu kaluku ni ko fi ẹnu rẹ sọ lori ayelujara.
- Nítorí pé mo gba ẹ̀há kò ní kí ń ṣọlẹ̀ tàbí ṣagbe- Ẹ̀lẹ́hàá Amina
- Èdè Yorùbá dùn lẹ́nu àwọn ọmọ òyìnbó yìí ní Michigan!
- Mo ti buwọ́lu àdínkù owó orí nítorí ìrọ̀rùn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun lásìkò Covid 19- Dapo Abiodun
- Iná sọ nínú ilé Big Brother tó ń lọ lọ́wọ́ ní Cameroon
- Buruji Kashamu jẹ́ ènìyàn tó nífẹ̀ aráàlú- Gómínà Dapo Abiodun
- Iná jó àwọn ènìyàn 10 tó ń gbà ìwòsàn arùn Coronavirus níbùdó ìtọ́jú