Coronavirus updates and palliative: Gomina Dapo Abiodun ti APC kéde àdínkù owó orí nípinlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, others
Gomina Dapo Abiodun to n tukọ ipinlẹ Ogun labẹ akoso ẹgbẹ oṣelu APC ti kede ẹdinku si awọn owo orí kan nibẹ.
O ni oun ti buwọlu awọn igbesẹ kan lori ọrọ owo ori ni eyi ti yoo mu irọrun de sii fun awọn ti oun n dari.
O ni lẹsẹkẹsẹ ni awọn igbesẹ naa di mimuṣẹ lati ileeṣẹ to n ri si ọrọ owo ori nipinlẹ Ogun, iyẹn Ogun state internal revenue services.
Bayii, wọn ti ṣafikun si gbedeke asiko too le san owo ori lai san ele sii fun oṣu mẹfa.
Ko ni si ele idiyele to yẹ ni sisan lori aitete san owo ori ẹni tabi ti ileeṣẹ fun oṣu mẹjọ sẹyin.
Ko ni si owo ori ọlọsọọsẹ fawọn ileeṣẹ to n te tẹtẹ lati oṣu kẹrin ọdun si oṣu kẹfa.
Dapo Abiodun tun ṣalaye pe o ṣeeṣe lati ṣe ipade pẹlu ileeṣẹ to n mojuto ọrọ owo ori lati ori ayelujara laidaamu wa sileeṣẹ wọn rara.
O tun kede ọna ijiroro ajọsọ lori ọna ti yoo rọrun fawọn to jẹ owo ori tẹlẹ lati tele ọna ti ko ga ju ara lọ.
Iru igbesẹ yii wo ni ipinlẹ Eko gbe ṣaaju asiko yii?
Gomina Sanwo-Olu náà dín owọ́ orí lórí ilé àti ilẹ̀ kù nítorí Covid 19

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu/others
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti bu ọwọ lu yiyọ owo ori ọdun mẹta kuro fun awọn onile ti won ko san owo ori lori ilẹ̀ ati ile wọ́n ni ipinlẹ́ Eko.(LUC Charges)
O si tun yọ ida mẹẹdọ́gbọn ninu ọgọrun un kuro fun awọn to ba tete san ti won lasiko yii.
Sanwo-Olu sọ wi pe owo ti wọn yọ kuro ninu owo naa wa fun riran awọn onisowo ati awọn to ni dukia lọwọ lati din inawo wọn ku nitori bi eto ọrọ aje se ri ni akoko corona yii ni Ilu Eko
ati agbaye.
Fifi ọ́wọ si adinku owo ori yii wa ye lẹyin osu kan ti Sanwo-Olu ti wọ́n ti n gbe ee yẹ́wo.
Sisan owo adinku ori yii bẹrẹ lati ọdun 2018.
Gomina Sanwo-Olu kede ibuwolu yii ninu ipade pẹlu awọn olori onisowo ati onise Aladani keekeeke (MSMEs) ni Lagos Corporate Assembly to jẹ́ ile okowo ijọba, ni Alausa .
Sanwo-Olu sọ pe oun gbe igbesẹ naa lati le fi ran awọn onisẹ aladani lọwọ ati lati le fi sun ọrọ aje siwaju ni akoko idẹnukọlẹ ọrọ aje ati koni le gbele ti arun Coronavirus yii.
- Àlàyé rèé lóríi àjọṣepọ̀ tó wà láàrin èmi àti MC Oluomo - Ronke Oshodi Oke
- N kò ri ipa ẹ̀jẹ̀ lára ọmọ mi tó kú sí iléeṣẹ́ ọṣẹ, èjò lọ́wọ́ nínú - Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ UI
- Ọmọ Nàìjíríà di agbábọ́ọ̀lù Áfíríkà tí iye owó tí wọ́n rà à ga jù nínú ìtàn!
- Akpata di aàrẹ àjọ àwọn agbẹjọ́rò ní Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ èèyàn kíi kú oríire
Gomina salaye siwaju si pe wọn sagbekalẹ ofin tuntun yi lati fi dena ija lori ilẹ ati awọ̀n ohun ini to ku.
Gomina sọ wi pe ijoba buwọlu yiyọ owo ori ọdun mẹta kuro bẹ́rẹ́ lati ọdun 2017, 2018, ati 2019.
Sanwo Olu ni : " idi ti a fi gbe igbesẹ yii ni ki awọn eniyan ipinle Eko le mo pe a mo riri eto ọrọ́ aje to dẹnukole nitori ajakalẹ arun Coronavirus yii ni gbogbo agbaye.
O tun fi da wọn loju pe didun lọsan a so fun awọn onile ise Aladani nipinlẹ Eko laipẹ
- Ọmọ Nàìjíríà di agbábọ́ọ̀lù Áfíríkà tí iye owó tí wọ́n rà à ga jù nínú ìtàn!
- Ẹ bá mi wá nọ́ńbà ìpè òbí ọmọ Mummy Calm Down jáde - Yinka Ayefele
- Ìpalẹ̀mọ́ ọdún Ileya kò rọgbọ ní Maiduguri, ojo ado oloro n rọ leralera
- N kò ri ipa ẹ̀jẹ̀ lára ọmọ mi tó kú sí iléeṣẹ́ ọṣẹ, èjò lọ́wọ́ nínú - Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ UI
- Akpata di aàrẹ àjọ àwọn agbẹjọ́rò ní Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ èèyàn kíi kú oríire
Ipinle Oyo lo kọkọ́ bẹrẹ bayii:
Ìpínlẹ̀ Oyo kéde àdínkù owó orí nítorí Covid 19
Coronavirus Updates in Oyo: Seyi Makinde kéde àdínkù owó orí nítorí Covid 19- Akinola Ojo

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Dreamstime
Komisọnna eto ẹnawo ni ipinẹ Oyo lo kede bẹ́ẹ̀ lorukọ Gomina Seyi MAkinde.
Ogbeni Akinola Ojo to jẹ Kọmisọnna fun eto ẹnawo ni ipinlẹ̀ Oyo lo ni ijọba gbe igbesẹ yii ki ara o le tu awọn onile ile isẹ nlanla ati keekeeke ni ipinlẹ Oyo.
Lasiko to n sọrọ lori igbesẹ ijọba lori owo ori nibi apero lori owo ori aladani ati onile isẹ lo sọ eyi di mimọ.
Akinola ni ohun to jẹ gomina Seyi Makinde lọkan ni lati mu igbe aye irọrun ba awọn eeyan ipinlẹ Oyo.
- Ìkúnlẹ̀ abiyamọ, ìkókó mẹ́jọ kú nílé ìwòsàn lálẹ́ ọjọ́ kàn
- Mamman Daura rí ìjà ọmọ Nàíjíríà torí ó pè fún wíwọ́gilé pínpín ipò ààrẹ lẹ́lẹ́kùn jẹkùn
- Oríire dé! Sanwo-Olu fẹ́ fojú-rinjú pẹ̀lú ọmọ tó ní kí ìyá òun ‘Calm down’
- Keisha sàlàyé ìdí tó fi sunkún ní ìyàrá ìrántí nílé ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà, ayé pariwo
- Ìjọba Èkó yóò fi òfin dè títà afẹ́fẹ́ gáàsì létílé láti dènà ìbúgbàmú láwùjọ
Bakan naa ni Ogbeni Akinola Ojo tun salaye idi ti ijọba fi sun ọjọ fifopin si owo ori sisan sẹyin fun awọn eeyan ati onile isẹ nlanla ati keekeeke.
Lara awọn ọna ti ijọba fi mu nkan dẹrun sii fawọn olugbe ipinlẹ Oyo to tun mẹnuba ni yiyọ́ kuro owo itanran to yẹ ki ẹni to ba lugbadi ofin aitete san owo ori yẹ ko san lasiko yii.
Awọn to ni ileesẹ to nii se pẹlu ohun ọgbin, isẹ́ agbẹ, ọ̀sìn ẹja, eto irinna, iwakusa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Kọmisọnna naa tun fi kun ọrọ rẹ pe ijọba gomina Seyi Makinde ti fọwọ si adinku ida marindinlọgọ́rin ninu ọgọ̀run un fun awọn osisẹ to kuna lati san owo ori tẹ́lẹ̀ nitori wahala Covid 19 ti ko jẹ́ ki agbaye ri isẹ́ se yii.
Awọn ti eyi kan julọ ni awọn osisẹ ile itura, ile iwe, ibudo igbafẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ to yẹ ki wọn ti seto sisan owo ori wọn saaju ọjọ kọkandinlọgbọn, osu kẹjọ, ọdun 2020.
Koda, o tun ni iye osisẹ́ ti koowa ba ni ati iye owo to ba n san fun wọn lasiko Covid 19 yii ni ki wọn san owo ori wọn le lori lai jẹ gbese.
O ni awọn ileesẹ to ba tun tete san owo ori wọn saaju ọgbọn ọjọ, osu kẹsan an a tun ri ẹdinwo ida mẹẹdọgbọn gba sii.
O tun ni aaye wa lati pe tabi sọrọ ni kikun lori ayelujara pẹlu awọn osisẹ to n risi ọ̀rọ̀ owo ori lai rinrin ajo wa si ilu Ibadan ni olu ileeesẹ wọn bii ti atijọ
O pari re pe awọn ti kọwe ransẹ si awẹn onile ise kaakiri lori igbesẹ ijọba yii.
Awọn onileesẹ to n se ipese ounje agolo, nkan mimu bii tii, omi inu ike ati omi inu ọ̀rá to ba tete san owo ori saaju ọjọ kọkanlelọgbọn, osu kẹjọ yoo ri ẹbun ida aadọta gba ninu owo ori wọn.
- 'Kò ní sí ìdíwó mó nínú ìṣàmúló ètò ìṣúná ìpínlẹ́ Oyo'
- Ejò wo ló mi ₦118m láàrin UCH àti ìjọba Oyo?
- Aláàfin ìlú Oyo, Ikú Bàbá Yèyé tún bímọ tuntun làǹtì lanti
- Ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun, Ondo buwọ́lu àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn
- Akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà, ìjọba Oyo kò pèsè ìbòmú lòdì sí ìlérí rẹ̀
- Ilé aṣòfin Oyo àti Ogun buwọ́lu àbádòfin ikọ̀ aláàbò Amotekun
















