Yoruba Film: Baba Ijesha sọ bí ọ̀tá ṣe sún un bá iré gẹ́gẹ́ bíi aláwàdà òṣèré Yorùbá

James Omiyinka

Oríṣun àwòrán, @BabaIjesha

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Wọ́n gba "Scene" mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lọ́wọ́ mi, wọ́n gbé òfo lé mi lọ́wọ́ ni mo fi di òṣèré fíìmù Yorùba.

James Omiyinka Olanrewaju gangan ni orukọ abisọ Baba Ijesha ṣugbọn ọpọlọpọ ni ko mọ ọ ju orukọ ori itage rẹ lọ.

Baba Ijesha bẹrẹ ifọrọwanilẹnuwo rẹ pẹlu gbajugbaja ọrọ to maa n sọ ninu ere "Oyinbo sọrọ o fi Psychology sinu rẹ..."

"Ọmọ bibi ilu Ijẹfẹ ni mi tori wi pe Ile Ifẹ ni mama mi, Ijesha ni Baba mi. Awọn Yoruba ni a kii nilee baba ka ma nile iya ni mo ṣe da mejeji pọ si ilu Ijefẹ".

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀
Àkọlé fídíò, Àwọn fíìmì òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú
Àkọlé fídíò, Niyi Akinmolayan tó ṣe fíìmu àwòrán-dèèyàn Cartoon nípa COVID-19 tó la ayé já ní N

Ṣe abinibi ni ede Ijesha ninu fiimu ni tabi "ability"?

Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Baba Ijesha

James ni igba mii ogun tabi ọta lo maa n ti eeyan de ọdọ oloore eeyan. O fi eyi ṣalaye bo ṣe bẹrẹ ere Tiata.

O ni ere kolekole bii adigunjale loun fi bẹrẹ ere Tiata ṣugbọn lọjọ ti o yẹ ki oun kopa ninu ere Saheed Balogun kan to yẹ ki oun ti kopa gẹgẹ bii adigunjale ni ọkan lara awọn aṣaraloge ba ni awọn ti wọn koun tunraṣe fun ti pe.

Ẹẹmẹẹdọgbọn lo yẹ ko fara han ṣugbọn ko pada ri anfani kankan lati sọ fawẹli A lasan ninu ere naa.

Baba Ijeṣha ni Wọn pada ni ki oun kan duro soju kan lẹgbẹ Fathia Balogun to yẹ ko fọwọ leran lori itage, wọn ni ko ma sọ ọrọ kankan ko kan maa jo.

Baba Ijesha ni: Ọlọrun wa kọ si mi nibi ti mo dede jokoo si mo ni (léde Ijesha) "Anti mi...

Fathia: Ki lo de?

Baba Ijesha: Ọkan mi kan baa yin sọ̀rọ̀ nii

Fathia: What for?

Baba Ijesha: Nigba ti ọga mi ti dide lọ la toosti ọrẹ rin, ẹ jẹ ki emi naa ti mo jẹ mọnija ki mo mọ nipa owo gan ka jọ maa fi kii, ka maa fi lu pọ

Fathia: Are you mad?

Baba Ijesha: Afi ki e fọọlu o, bẹẹ ba i le fọọlu, iya laa jẹ yin... Oyinbo sọrọ o fi Saikọlọji sinu rẹ...

Bi ede Ijesha ṣe sun James Omiyinka de bi ire to di gbajugbaja alawada oṣere Yoruba.

Àkọlé fídíò, Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

"Mo bọ̀wọ̀ fún Fathia Balogun púpọ̀, ẹ̀dá ọ̀tọ̀ táwọn èèyàn ò fura sí ni".

O ni awọn kan wa laye to jẹ pe tẹẹ ba rọra fọwọ kan wọn lasan, aye ẹ maa dara gidi gan.

Baba Ijesha mẹnu ba a pe Alagbe ni Yoruba oni Tiata ka ma fi nkankan bo o loju o si ṣalaye idi to fi sọ bẹẹ pe iṣẹ awọn jẹ iṣẹ igba tori naa ẹni to ba pe eeyan si ere naa ni eeyan le ba ṣere. O ni awọn ẹya kan wa to maa n dide iranwọ si ẹbun ẹni.

Lọwọlọwọ, akẹkọọ ni James Omiyinka ni ipele aṣekagba ni fasiti ilu Eko nibi to ti n kọ imọ ẹkọ Tiata to si sọ ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo wa pẹlu rẹ awọn nkan tuntun ti ẹ o maa reti latọdọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀
Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post