Ń ko dúró ṣe ìdánwò WAEC nílé ẹ̀kọ́ gírámà, kí n tó bẹ̀rẹ̀ tíátà - Kamilu Compo

kamilu kompo

Oríṣun àwòrán, kamilu kompo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ilumọọka osere tíátà kan, Tijani Adekola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Kamilu Compo àbí Gọlugọ, tí kesi àwọn olólùfẹ́ rẹ láti má ṣe bá ẹnikẹ́ni dá àṣà pé ko si ohun tó ń jẹ àrùn Coronavirus.

Kamilu Compo, lásìkò to ń kópa lórí ètò BBC Yoruba ṣàlàyé pé, àrùn Covid-19 kii se ohun ti a n fi ọwọ yẹpẹrẹ mú nítorí kò tíì sí òògùn fún ìwòsàn rẹ.

Kamilu, ẹni tó kéde pé òun ti ṣètò iranwọ fáwọn olólùfẹ́ òun lásìkò igbele Covid-19 náà, tún rọ wọn láti máa tẹle àwọn ìlànà tó ń dènà itankalẹ àrùn bíi fífi ọ̀sẹ̀ fọ ọwọ, lilo ìbòjú àti títa kété síra ẹni.

Nígbà tó ń ṣàlàyé nípa ohun tó fi ń pa ọwọ dà lẹ́yìn ere tíátà, Gọlugọ ní òun sì ibùdó kan tí wọn ti ń ta bàbá Ìjẹ̀bú taa mọ si Lotto, àmọ́ ajakalẹ-arun Coronavirus tí mú kí òun gbé ilẹkun ibùdó náà tí pá.

Kamilu, ẹni tó sàlàyé bo se de ìdí ere tíátà, sísọ lójú rẹ pé, ile ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ni òun ti bẹ̀rẹ̀ si ní ìfẹ́ si eré tíátà, tí òun sì darapọ mọ ẹgbẹ́ osere Seyi Adeoye.

"Ọmọ bíbí ìlú Oyo ni mí, bi mo ṣe jáde kúrò nílé ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ, ní mo darapọ mọ ère tíátà ni ọdọ ọga mi n'ilu Oyo, ibẹ sì ni mo ti pàdé Afonja Olaniyi, tá mọ sì Sanyeri."

51328924 - Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣ'ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Bíṣọ́ọ́bù Oyedepo pé kò sí ìdí tí iléèjọ́sìn láti wà ní títì pa

Oríṣun àwòrán, Sanyeri ati kamilu kompo

"Ń kó ṣe idanwo WAEC tí mo fi di òní tíátà, àwọn òbí mi yín mi nù, mo bẹ̀rẹ̀ si gbe ni ọdọ ọga mi, tí mo sì ń lọ nù agolo nileesẹ búrẹ́dì láti rí owó jẹun, ebi pa mi, ìyá jẹ mi àmọ́ mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run lonii"

Kamilu wa gbà àwọn èèyàn tó kú díẹ̀ kaato fún ní ìmọ̀ràn pé tí wọn ba ni sùúrù, yóò dára, kí wọn sá ni Ọlọ́run, kí wọn sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.

"Èmi àti Sanyeri tí tọrọ oúnjẹ jẹ nílé oninawo rí, wọn tí fi ada lè wá lójú agbo ìnáwó rí, tí oro si ti lè wá ni abule kan lẹba Oyo rí, ṣùgbọ́n loni, a dúpẹ́ pé Ọlọ́run gba àdúrà wa."

Kamilu ni ọdún 1996 ni òun kọ́kọ́ kópa nínú eré sinima, tí òun sì ti ṣe fíìmù méjìlá jáde, pẹ̀lú afikún pé gbogbo eka tó nii ṣe pelu fíìmù ṣíṣe ni òun mọ nípa rẹ.

"Èmi àti Sanyeri nìkan là dá ṣe fíìmù ni Malaysia, àwa ní osere ati a yàwòrán, kò sì nkankan tó wà nínú ṣíṣe sinima jade, tí ń kó mọ."

Sanyeri ati Kamilu kompo

Oríṣun àwòrán, kamilu-kompo

O ṣàlàyé pé, ó dára kí èèyàn ni ẹkọ tó ye kooro nínú gbogbo ohunkóhun ta bá fẹ́ ṣe, ẹnikẹ́ni tó bá di fẹ́ lu aluyọ nínú isẹ tíátà gbọ́dọ̀ ni Ọlọ́run, kò ní ìtẹríba àti apọnle àwọn ọga tó bá lẹ́nu isẹ pẹ̀lú ìfaradà àti aforiti.

Kamilu wá rọ awon eeyan tó ń sọ ahesọ ọ̀rọ̀ kiri pé òun ni ìyàwó mẹrin, pé kí wọn dẹkun sísọ ohun tí ojú wọn ko tó nítorí èyí kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, ìyàwó kan soso ni òun ni.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣepọ̀ rẹ pẹlu gbajumọ oṣere tíátà míì, Odunlade Adekola, Gọlugọ ni onirẹlẹ ẹ̀dá ni, tí kìí fi ojú pá ẹnikẹni rẹ, tó si máa ń fi ọwọ sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹẹgbẹ rẹ nígbà kuugba.

Okunnu: Ẹnu Ayinde Barrister ni mo ti gbọ́ orúkọ 'Okunnu' kí n tó máa jẹ́ẹ

Wale Akorede

Oríṣun àwòrán, Instagram/Okunnu

Gbajugbaja adẹrinpoṣonu oṣere tiata, Wale Akorede, ti ọpọ mọ si Okunnu sọ pe ọjọ ti pe tawọn eeyan ti n sọ pe orilẹede Naijiria yoo dara.

Ọgbẹni Akorede ni lori wi pe Naijiria yoo dara naa ni baba to bi oun lọmọ ku si, Naijiria yoo dara naa lo jẹ ki oun ko idile oun lọsi oke okun.

Okunnu ni Eleduwa ti kọ ni kadara fun idile oun pe, oke okun ni wọn yoo fi ṣe ibugbe lo jẹ ki wọn wa loke okun bayii.

Ifọrọwerọ BBC Yoruba ati Akorede Okunnu ree:

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Ọgbẹni Akorede ni iṣẹ oun ni ko fun oun naa lanfaani lati maa gbe oke okun pẹlu idile oun.

Wale Akorede

Oríṣun àwòrán, Instagram/Okunnu

''Lati igba ti mo ti wa nile iwe alakọbẹrẹ ni mo ti bẹrẹ ere tiata ni ṣiṣe, ṣugbọn ko si ọkan ninu baba ati iya mi to fọwọ sii pe ki n ṣiṣẹ tiata,''

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Sajẹ: Mo n rọ awọn akẹẹgbẹ mi lati se suuru de asiko Ọlọrun

Ṣugbọn lẹyin ti baba mi papoda tan, mo beere iyọnda lọwọ mama mi pe, ki wọn jẹ ki n ṣe ere tiata.

Okunnu to jẹ ọmọ ile Olokiti, Ijẹru ọja niluu Ogbomoṣo ni, ilu Ibadan ni wọn bi oun si, nibi ti oun ti dagba.

Ọgbẹni Akorede ṣalaye pe, ifẹ ni iyawo oun ni to fi fẹ oun, kii ṣe owo lo wo, to fi duro ti oun di oni.

Wale Okunnu

Oríṣun àwòrán, Instagram/Okunnu_1

Nigba to n sọrọ lori ija to maa n waye laarin awọn oṣere tiata to jẹ obinrin, Okunnu ni abuda awọn awọn obinrin ni lati maa ba ara wọn ja, o ni ko si iru rẹ laarin awọn ọkunrin oṣere.

''Ẹnu Ayinde Barrister ni mo ti gbọ orukọ Okunnu, ṣugbọn okun nu ni itumọ orukọ naa lẹyin ti mo ṣe iwadii lori rẹ,'' Okunnu lo woye bẹẹ.

O ni ti oun naa ba n wo 'Okunnu' ninu ere, emi gan maa n rẹrin arin takiti, amọ Wale Akorede maa n tiju gan an ti ko baa tii ri ẹrọ kamẹra.

Àkọlé fídíò, World Radio Day: Àwọn òṣìṣẹ́ rédíò ní àwọn ń pa ìsòro àwọn mọ́ra ni láti mú inú aráàlú dùn

Ọdun mẹtala ni Okunnu fi gbe orilẹede Saudi Arabia, amọ o ni isẹ tiata ko gba oun laye lati wọ eyin Mecca, ati pe ọṣọ lasan ni eyin Mecca.

Okunnu ni wọn le sọ pe ki oun ṣe ọmuti tabi ki oun gba obinrin lọ sile itura, eleyi to tako wiwọ eyin Mecca.

Ninu esi rẹ si ọrọ ti minisita fun ọrọ iṣẹ ati ileegbe, Babatunde Fashola sọ pe ohun tawọn ọdọ n wo ninu ere tiata lo jẹ ki wọn maa ṣoogun owo, Okunnu ọrọ ko rii bẹẹ.

Wale Akorede

Oríṣun àwòrán, Instagram/Okunnu_1

''Ẹni to lọ ṣoogun owo kẹyin to wo ere tiata tan ti fẹ ṣe oogun tẹlẹ ni, kii ṣe pe ninu ere tiata lo ti rii,'' Okunnu lo woye bẹẹ.

O ni lati oun jogun ba awada ṣiṣe lati ọwọ mama oun ni, bakan naa lo sọ pe iwe ere awada lo ṣoro kọ ju laye.