Fuel Price Hike: Onímọ̀ ní oṣooṣù ni owó lítà epò kan yóò máa yàtọ̀, ó le léwó tàbí dínwó

Oríṣun àwòrán, The guradian nigeria
Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ti ni yẹkini kan ko lee yẹ iwọde apapọ jakejado orilẹede Naijiria ti yoo waye lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan an.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ n pe fun iwọde gbankọgbi kaakiri orilẹede Naijiria lati tako igbesẹ ti ijọba gbe laipẹ yii lati fi owo kun owo epo bẹntiro ati ina mọnamọna.
- Òṣèré méjì yìí ń fi ẹ̀wọ̀n runmú tóríi fíìmù "Ife" táwọn obìnrin ń bá ara wọn lòpọ̀
- Ilé ìtajà kan ni àwọn afurasí ọmọ Yahoo ti n bọ̀, kí ọlapàá SARS tó lé wọn sí ẹnu ikú l'Osogbo
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà gbarata lóríi fọ́nrán tí Tinubu fi síta lóríi dídìbò f'ún Obaseki ti Edo
- Lanlehin kéde ìparí gbogbo ètò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, akọwe agba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ TUC lorilẹede Naijiria, Comrade Musa Lawal ṣalaye pe ijọba apapọ labẹ iṣejọba Muhammadu Buhari ko ṣe bi ẹni to mọ pe ara n ro araalu rara paapaa pẹlu atunbọtan ajakalẹ arun COVID-19 to da ọrọ aje ọpọlọpọ eeyan ati orilẹede ru, ninu eyi ti ọpọ di alainiṣẹ lọwọ.
Ẹgbẹ TUC ni ọna abayọ meji pere ni awọn fun ijọba apapọ ki alaafia to lee jọba. Awọn ọna abayọ naa si ni akọkọ, ki wọn da owo epo pada si iye to wa tẹlẹ, iyẹn naira marundinlaadọjọ N145 lori jala kan; ikeji ki wọn si da owo ina pada si iye to wa tẹlẹ.
Ẹgbẹ naa ni eyi fihan pe bi ijọba ba ti kuna lati ṣe ohun meji yii, ko si ijiroro kankan to lee waye nitori pe o yẹ ki ijọba fi ọrọ naa lọ araalu ki wọn to da iru aṣọ bẹẹ ṣoro.
O fi kun un pe o yẹ ki ijọba o ronu pe ajakalẹ arun COVID-19 ṣe ọpọẹọpọ ijamba fun awọn ọmọ Naijiria, bẹẹni gbogbo awọn ohun itura ti ijọba ṣeleri rẹ , ni araalu o ri, bi o tilẹ jẹ pe ijọba n pariwo pe awọn na ẹgbẹlẹgbẹ owo lori rẹ.
Amofin Lawal ṣalaye pe bi ijọba ba wa kuna lori awọn agbekalẹ rẹ wọnyii ko si ohun to n di awọn lọwọ iwọde awọn niyẹn.

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba orilẹede Naijiria ti ni awọn ti jawọ ninu dida Iye le owo ti awọn elepo yoo ma ta epo bẹntirol lorilẹede Niajiria.
Nibayii, awọn to n ta epo bẹntirol ni yoo ma sọ iye ti wọn ba fẹ ta epo bẹntirol naa loore-koore.
O ti le ni oṣu mẹta bayii ti ijọba ti bẹrẹ si ni yọ ọwọ kuro lori iye ti awọn elepo n ta epo ni Naijiria, ti wọn ko si fi kede iye ti wọn yoo ta epo ni Osu Kẹjọ ati Oṣu Kẹsan an, ọdun 2020.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí nǹkan ọkùnrin bá há sójú ara obìnrin, kìí ṣe Mágùn, ẹ má páyà
- Owó tí Kiddwaya bá rí ní BB Naija, ìdá kan fún Erica, ìkejì fọ́mọ aláìníyàá - Baba Kiddwaya
- Kí ló le è mú kí agbábọ́ọ̀lù subú, kó sì kú lásìkò ìfẹsẹ̀wọ̀nsẹ̀?
- Ọlọ́pàá rí òkú ọ̀gá àgbà iléèṣẹ́ ńlá kan tí wọn ń wá, lójú omi l‘Eko
- A gbé òfin 1960 jáde, màálù tó bá jẹ oko àgbẹ̀, tí olówo rẹ̀ kò sanwó, títà ni - Buhari
- Ìjọba fẹ́ kọ́lé 300,000, pẹ̀lú ìrànwọ́ fún àgbẹ̀ 4m láti mú àdínkù bá ìṣẹ́ - Osinbajo
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
Adari ileeṣẹ Petroleum Products Pricing Regulatory Agency, PPPRA, Abdulkadir Saidu ni lati igba yii lọ, bi awọn eniyan ṣe n ta epo sii ati iye ti wọn ta epo rọbi lagbaye, ni yoo ma sọ iye ti awọn elepo yoo ma ta lita epo.

Amọ, o ni ijọba orilẹede Naijiria yoo ri wi pe iye ti wọn ta a, ko kọja agbara awọn ti yoo ra a.
''Owo bentirol yoo lọ soke si lasiko ti ijọba ni ki awọn elepo maa diye le owo epo."
Onimọ nipa eto ọrọ aje, Temitọpẹ Kolawole ti salaye ohun ti igbesẹ ijọba tunmọ si fun awọn ọmọ Naijiria.
Kolawọle ni iye ti wọn ba ra a ni yoo ma a sọ iye ti wọn yoo ma a ta, nitori naa iye owo epo bẹntirlo yoo lọ soke si.
Amọ, bi igba ba ṣe n lọ, owo epo yoo walẹ si, ti iye ti wọn yoo ma ta a yio si yatọ si ara wọn bi igba ba ṣe n lọ.
O fikun wi pe yiyọ ti ijọba yọ owo iranwọ epo naa, yoo mu ibugbooro ba ọrọ aje ni Naijiria.
'' Íye owo bẹntirol le goke to N250 si N300 lati igba yii lọ''
‘Apẹẹrẹ ni Sim Card ti a n ra bayii ni ọgọrun naira, amọ nigba ti o kọkọ jade, ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni wọn n ta."
Nitori naa, onimọ nipa eto ọrọ aje ni Naijiria, Temitope Kọlawole wa rọ awọn ọmọ Naijiria, lati bẹrẹ si ni ṣe ipesẹ ounjẹ wọn labẹle nitori ọwọngogo ti yoo gori awọn eroja ounjẹ lasiko yii.
Kolawole fikun wi pe, asiko ti ijọba gbe igbesẹ naa ni ko rọrun fun awọn ọmọ Naijiria, nitori ọrọ aje to dẹnukọlẹ ati arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra.
Owó lítà epo ní Nàíjíríà ló kéré jùlọ l'Áfíríkà - Lai Muhammed
Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti sọ wi pe naira mejilelọgọjọ ti wọn n ta lita epo pẹtiro kan lo kere julọ ni ilẹ Afrika.
Minisita fun eto iroyin ati asa, Lai Mohammed lo sọ bẹẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Ìjà ẹgbẹ́ òṣèré TAMPAN àti ANTP ni kò jẹ́ kí wọ́n pe Baba Legba sínú eré mọ́, kó tó kú - Owolabi Ajasa
- Tí mo bá kú lónìí, Pásítọ̀ Ibiyeomie ló pa mi - Daddy Freeze kébòòsí
- Àwọn afurasí lórí ẹ̀ṣùn jíjí ìbejì Akeugbagold gbé yọnú sílé ẹjọ́ láì ní agbẹjọ́rò
- Aṣòfin méje yarí mọ́ Akeredolu lọ́wọ́ torí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí kò pín fún wọn
- Aya gómìnà Kwara gba ilé fún Risikat olójú búlúù àti ọkọ rẹ̀
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
Lai Mohammed ni, bi o tilẹ jẹpe awọn yọ owo iranwọ to wa lori epo, iye ti awọn n ta lo kere julọ ni iwọ oorun ilẹ Afrika.

Oríṣun àwòrán, Others
O fi iye owo ti wọn n ta a ni awọn orilẹede yii lede bayii;
- Nigeria -N162
- Ghana -N332
- Benin -N359
- Togo - N300
- Niger - N346
- Chad -N366
- Cameroon -N449
- Burkina Faso -N433
- Mali -N476
- Liberia - N257
- Sierra Leone -N281
- Guinea -N363
- Senegal - N549
Minisita naa fikun wi pe, ti a ba kuro ni ẹkun iwọ oorun Afrika lọ si awọn orilẹede bii Egypt ati Saudi Arabia, oye ti wọn n ta a ni N211 ati N168.
Lai Mohammed ni iye owo epo yii fihan pe, iye owo ti wọn ta epo bẹntirol ni Naijiria lo ṣi kere ju ni ilẹ Afrika, bi o tilẹ jẹ pe awọn ti yọ owo iranwo kuro lori rẹ.

Mohammed ni Naijiria ko ri owo pa wọle mọ bii ti tẹlẹ, nitori naa awọn ko ni le san owo iranwọ lori epo bẹntirol ati mọnamọna mọ.
Bakan naa lo ni ajọ to n bojuto ọrọ epo bẹntirol ni Naijiria, NNPC gbe jade pe, iye owo to le ni triliọnu mẹwaa naira ni awọn ti na lori owo iranwọ epo lati ọdun 2006 si 2019.
- 2007-N272bn
- 2008 -N631bn
- 2009 -N469bn
- 2010 -N667bn
- 2011 -N2.105trn
- 2012 -N1.355tn
- 2013 -N1.316tn
- 2014 -N1.217tn
- 2015 -N654bn
- 2016 -Ko si akọsilẹ fun iye ti wọn na
- 2017 -N144.3bn
- 2018 -N730.86bn
- 2019 -N595bn.
Amọ, inú àwọn èèyàn kò dún rárá lásìkò yii tí Ààrẹ Buhari gbé owó lé owó epo àti iná mọ̀nàmọ́ná nigba kannaa, nitori nnkan nira fun awọn eniyan lasiko arun Coronavirus yii.
Mo fòpin sí àjẹbánu lórí owó ìrànwọ́ epo àti iná ọba, ní èlé ṣe wáyé - Buhari
Ijọba Aarẹ Buhari ti ni o pọn dandan fun oun lati gbe igbesẹ to gbe nipa fifi owo le owo epo bentirol ati ina mọnamọna.
Ijọba ni eyi ri bẹẹ ki idagbasoke nla lee ba ọrọ aje lorilẹede Naijiria ni.

Oríṣun àwòrán, Others
Atẹjade ti oluranlọwọ pataki feto iroyin fun aarẹ Buhari, Mallam Garba Shehu fi lede lo ti salaye idi ti Aarẹ Buhari fi gbe igbesẹ naa.
Ijọba ni awọn yọ owo iranwọ to wa lori epo bẹntirol ati awọn ẹka miran, lọna ati le lo owo ori ti awọn eniyan ba san lọna to tọ, yatọ si sise afikun owo epo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìdí tí wọ́n ṣe lé Erica dànù kúrò nílé BBNaija l'ọ́sẹ̀ yìí
- Kí ló ṣe Ibrahim Chatta tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Ọlọ́pàá wú òkú obìrin tó ń múra ìgbéyàwó lọ́wọ́ tí 'gate-man' rẹ̀ ṣekúpa
- "A fẹ́ yọ ààrẹ ẹgbẹ́ Yorùbá YCE nípò torí àwọn ìwà tí kò bójúmu"
- Wo àànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Ẹ fura o, Boko Haram ti pàgọ́ sí Abuja, yóò ṣe ìkọlù láìpẹ́ - Iléèṣẹ́ Aṣọ́bodè lọgun
Atẹjade naa ni yiyọ ti aarẹ yọ owo iranwọ naa yoo fopin si iwa ibajẹ ati iwa jẹgudujẹra, ti awọn kan n ṣe lori owo iranwọ to wa lori epo bẹntirol, ina mọnamọna ati awọn ohun elo to n mu nkan ọgbin gbooro si.
ijọba ni oun gbe igbesẹ naa, ki awọn ọlọja yii fun ara wọn gbe owo le awọn ọja yii, lọna ti yoo pe awọn ara ilu.
O fikun wi pe awọn ijọba to ti wa tẹlẹ ti gbiyanju lati ṣe eyi, amọ wọn ko ni igboya lati ri wi pe o wa si imuṣẹ.
Oluranlọwọ pataki fun naa ni awọn eniyan yoo ranti aarẹ Buhari si rere ni ọjọ iwaju.
O ni biotilẹjẹpe o lera fun awọn eniyan lasiko yii, awọn igbesẹ naa pọn dandan lati le mu itẹsiwaju ba orilẹede Naijiria, ati lati le mu ilọsiwaju ba ọrọ aje to dẹnu kọlẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Garba Shehu fikun wi pe, nigba ti ẹgbẹ oṣelu APC gba iṣejọba ni ọdun 2015, awọn ṣeleri ati mu igbe aye rọrun fun awọn eniyan, ọdun marun si igba ti awọn wọle, awọn si n n gbe igbesẹ lati mu ohun gbogbo pada si ipo lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni wọn fi lede wi pe, ijọba Aarẹ Buhari nilo ifọwọsowọpọ awọn araalu, ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ati awọn ẹgbẹ oṣelu to ku ni Naijiria lati le mu Niajiria de ilẹ ileri.
Fuel Price Increase: Ìjọba Buhari ń fi ara ní àwọn èèyàn púpọ̀ jù
Awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ gbarata lori alekun owo epo bẹntiro

Gbogbo awọn eniyan to n lo epo bẹntiro fun iṣẹ oojọ ati igbokegbodo ọkọ ti gbarata lori aleekun ti ijọba mu ba iye ti wọn n ta jala epo kan jakejado orilẹede yii.
BBC Yoruba rin kaakiri ilu Ibadan olu ilu ipinlẹ Ọyọ lati ṣe amojuto awọn ayipada to rọ mọ alekun naa.
Arabinrin kan ti a ba sọrọ ni agbegbe Orita ṣe alaye wi pe epo ẹgbẹrun kan naira ni oun maa n ra sinu ọkọ tẹlẹri ki ijọba to mu alekun ba owo epo.

O tẹsiwaju pe epo ẹgbẹrun kan naira ko le de ibi kankan mọ ninu ọkọ nibayii ti epo ti gbowo lori.
Arọwa arabinrin yii si ijọba ni pe ki wọn ja owo epo pada wa silẹ nitori pe o ti pọ ju.
O ni, "gbogbo nnkan lo wọn tẹlẹ, Owo ti wọn fi kun epo yoo kan jẹ ki nnkan tun wọn si i ni ti ara yoo si maa ni gbogbo ara ilu."
- Wo ohun tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n ṣe fún Sunday Shodipe, afunrasí ìṣekúpani l'Akinyele
- Gbajabiamila balẹ̀ sí Ghana láti pẹ̀tù sááwọ̀ láàrin Nàìjíríà àti Ghana
- Isiaka Busari, Mighty Joe tó jẹ́ adigunjalè tó rọ́pò Ọyenusi lẹ́yìn tí wọ́n pa á
- E wo ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
- Ọmọ Nàìjíríà kan gbé Fásitì Oxford lọ sílé ẹjọ́ tàko oríkí ọrọ 'Mortgage' nínú ìwé àtúmọ̀ ọrọ
A tun rinrin ajo de agbegbe Tipper Garrage nilu Ibadan:
Awakọ ero kan ti o ba wa sọrọ nibẹ fi ẹhonu han wi pe awọn adari orilẹede yii ko nifẹ ara ilu bo ti n wu ko mọ.

O ni ti wọn ba ni aanu mẹkunu lọkan ni, wọn ko ni fi kun owo epo rara.
O rawọ ẹbẹ wi pe ki ijọba tun ero rẹ pa.
Kini BBC ba bọ ni agbegbe New Garrage?
Alamojuto ile epo kan ni agbegbe New Garrage ṣe alaye fun ikọ BBC News Yoruba wi pe ara ko rọ okun - ara ko rọ adiye ni ọrọ aleekun to de ba owo epo.

O ni bi awọn ṣe n ta epo ni owọngogo naa n kopa buburu lori eto iṣuna awọn nitori yoo kan ẹbi, ara ati ọrẹ awọn to n ta epo naa.
O tẹsiwaju wi pe epo to wọn ki i ṣe ẹbi awọn onile epo bikoṣe awọn alaṣẹ to n be loke.
Awọn to n ta epo bẹntiroo naa tun ba akọroyin BBC sọrọ pe:
Ontaja epo mii to ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe ọwọ ijọba ni gbogbo rẹ wa nitori ko si ẹni kan to iredi ti ijọba fi gbe igbesẹ naa.

O ni awọn kan ṣa dede ji ni awọn gbọ iroyin wi pe owo epo ti sun lọ soke pe iye bayii ni epo tun un ba jade.
O ni, "boya owo dollar lo gbẹnusoke ni o tabi nnkan. Aarin yẹn ko ye wa.
Ṣugbọn ẹ mọ pe nnkan ti awa ontaja epo aladani ba ra naa ni a maa ta."
- Gbajabiamila balẹ̀ sí Ghana láti pẹ̀tù sááwọ̀ láàrin Nàìjíríà àti Ghana
- Isiaka Busari, Mighty Joe tó jẹ́ adigunjalè tó rọ́pò Ọyenusi lẹ́yìn tí wọ́n pa á
- E wo ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
- Ọmọ Nàìjíríà kan gbé Fásitì Oxford lọ sílé ẹjọ́ tàko oríkí ọrọ 'Mortgage' nínú ìwé àtúmọ̀ ọrọ
- Wo ohun tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n ṣe fún Sunday Shodipe, afunrasí ìṣekúpani l'Akinyele

Ki lo kọkọ ṣẹlẹ?
Wo ohun tó ń fa àfikún epo lóòrèkóòrè ní Nàìjíríà
Èyí ni bí ojú ọjà epo lágbáyé ṣe ń fa àfikún epo lóòrèkóòrè ní Nàìjíríà
Kaakiri oju ayelujara ni iroyin ti gbode pe ijọba ti fi owo kun iye owo jala epo bẹntiroo ni Naijiria lọjọru.

Ijọba apapọ nipasẹ ileeṣẹ epo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC ti kede afikun owo epo lorilẹede Naijiria leyi to gbe owo ori epo bẹntiro soke sii.
Eyi si ti fa ọpọlọpọ awuyewuye laarin awọn ẹgbẹ, ọgba, ileeṣẹ lajọlajọ ati mutumuwa.
Amọṣa ki lo n fa afikun epo loorekoore lẹnu ọjọ mẹta yii na?
Idahun si eyi wa ninu atẹjade kan eleyii ti ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si idiyele owo epo rọbi lorilẹede Naijiria, (PPPRA) tẹ jade ni Ọgbọn ọjọ, oṣu kẹta ọdun 2020
Ṣugbọn ti o bọ si gbangba iwoju araalu ni ọjọ kẹrin, oṣu karunun, ọdun 2020 yii kan naa eleyii ti wọn pe akọle rẹ ni "Ofin lilo idunadura oju ọja epo lati fi diyele epo bẹntiro t'ọdun 2020".
Akọwe agba ajọ naa, Abdulkadir Saidu ṣalayekikun ni pa igbeṣe inu fifi owo sori epo.
O ni wi pe ajọ oludiyele owo epo lorilẹ-ede Naijiria yoo maa boju wo bi nnkan ṣe n lọ si lọja epo rọbi lagbaye lati lee ma fun ajọ elepo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC atawọn ontaja epo ni amọran loṣooṣu lori ibi ti owo ori epo de duro
Ki ni eyi tumọ si?
Pẹlu eleyi, o fihan pe awọn alagbata epo ni anfani bayii lati diye le ori epo bẹntiro ki wọn si lee taa ju iye ti ajọ PPPRA ba gbe kalẹ lọ.
Eyi fihan pe ohun ti awọn oniṣowṣo epo ba ra ni ọja epo agbaye ni wọn yoo fi ṣe odiwọn iye ti wọn yoo taa lọja abẹle fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.
Idi niyi ti owo ori epo fi n wa soke-wasilẹ lẹnu ọjọ mẹta yii nitori segesege to n waye lori owo epo lọja agbaye.
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
- Bàbá ẹni ọgọ́ta ọdún dèrò ilé ẹjọ́ nítorí ó wọ inú oko Obasanjo láì gba àṣẹ
- Mi ò fẹ́ ìrànwọ́ ẹgbẹ́ òṣèré, àwọn kọ́ ló kóbá mi- Chief Kanran
- Kí ló wá nínú àbádòfin pínpín omi àti àwọn ǹkan inú omi tó ń mú awuyewuye wa?
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, PDP, MAN fọnmú lórí epo bẹntiró tó dí N162
Ijọba apapọ n kede afikun owo epo bẹntiro lẹyin ọjọ kan ti wọn kede ẹkunwo owo ina mọnamọna jakejado orilẹede Naijiria.
Lati jọru ti iroyin afikun yii si ti jade lawọn eeyan lẹkajẹka gbogbo lawujọ si ti n fi ero wọn han lori rẹ.
Ninu ọrọ tirẹ, ẹgbẹ awọn oludaleeṣẹ silẹ lorilẹede Naijiria,, MAN ṣalaye pe igbesẹ naa yoo mu inira ba awọn ileeṣẹ kerejekereje to ṣẹṣẹ n gbimọran ati ri ẹsẹ walẹ.
Ijọba apapọ nipasẹ ileeṣẹ epo rọbi lorilẹ-ede Naijiria, NNPC ti kede afikun owo epo ni Naijiria leyi to gbe owo ori epo bẹntiro soke sii.
Bi ọrọ ṣe n lọ bayii, o ṣeeṣe ko jẹ pe naira mejilelọgọta ni wọn yoo pada naa taa nitori ohun ti alaga awọn agbepo lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, Dele Tajudeen sọ fawọn akọroyin kan ni wi pe iye ti awọn yoo maa ta epo niyen niori pe ijọba pẹlu ti gbe owo sisan ni ibdu igbepo gbogbo ti di naira mọkanlelaadọta, (N151.56).
Awọn MAN ni ohun to yẹ ki ijọba o ṣe ni lati rii pe ina ọba duro deede lati mu ki awọn eeyan o dẹkun rirọgbọku le epo.
Ninu ọrọ tirẹ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria NLC ṣalaye pe n ṣe ni ijọba n mu awọn ọmọ Naijiria ni suẹgbẹ pẹlu igbesẹ naa.
"Igba kẹta ree laarin oṣu mẹta. lana ode yii (Ọjọ Iṣẹgun) ni wọn ṣẹṣẹ bu owo le owo ina mọnamọna o."
NLC ni awọn kọ afikun owo epo yii nitori ara n ni awọn ara ilu

Oríṣun àwòrán, others
IPMAN kéde àfikún iye owó epo bẹntiróòlù di ₦162 wọ́n ni kìí ṣe #151.56k
Ẹgbẹ alagbata epo aladani lorileede Naijiria IPMAN ti paṣẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ wọn jakejado Naijiria maa ta jala epo kan ni naira mejilelọgọjọ.
Afikun ti wọn kede ọhun yoo wa jẹ lati naira márùndínláàdọ́jọ (N145) lita kan ti o wa tẹlẹ si iye tuntun yi.
Ninu alaye rẹ Alhaji Bashir Dan Malam to jẹ alaga IPMAN ni Kano sọ pe iye yi di dandan ki awọn baa le ri owo tawọn naa yọ lẹyin gbogbo isiro to ba iye owo epo de.
Bẹẹ lo ni igbesẹ ijọba to sọ iye owo epo bẹntiroo di Naira mọkanlelaadọjọ lo mu ki awọn naa fi owo kun.
Igba ẹlẹẹkẹta ree ti ijọba Naijiria yoo fi owo kun owo bẹntiroo lẹnu oṣu meloo sẹyin.
- ‘Ìṣúnsíwájú ìbò: Àdínkù yóò bá owó epo bẹntiróòlù
- Ààrẹ Buhari pọ́n ọ̀dọ́ Nàíjíríà lé, ó ya Nov 1st sọ́tọ̀ fún àyájọ́ ọ̀dọ́
- Àṣírí tú! Wo àwọn tó ń jí owó Covid-19 tí Ìjọba ní wọ́n yóò káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ padà sí iléèwé
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
Ki lawọn ọmọ Naijiria sọ si alekun yi?
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic party ti kesi ijọba Naijiria labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lati da owo jala bẹntiroo ati ina mọnamọna ti wọn lekun pada walẹ ni kiakia.
Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa Kola Ologbọndiyan lo fi ọrọ yi sita loju opo Twitter lọjọru.
Ologbondiyan ni o jẹ iyalẹnu pe ijọba APC le gbe iru igbesẹ yi lasiko ti ara n ni awọn ọmọ Naijiria to si kesi ile aṣofin Naijiria lati da si ọrọ naa.
- Gbajabiamila balẹ̀ sí Ghana láti pẹ̀tù sááwọ̀ láàrin Nàìjíríà àti Ghana
- Dáa padà Buhari, èmi kìí s'ọ̀lẹ
- Ẹ fọkànbalẹ̀, kọ́bọ̀ kò ní gun owó epo pẹtiró - NNPC
- Iléeṣẹ́ ìròyìn Daily Trust gbọdọ̀ san N6 bilion nítorí ìbanilórúkọjẹ́- Femi Fani Kayode
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC
Ẹwẹ, Ayodele Fayose to figba kan jẹ Gomina ipinlẹ Ekirti naa ti bẹnu at lu ẹkunwo owo jala epo ti ijọba Naijiria kede.
O sọ ọrọ yi loju opo Twitter rẹ .O ni ohun ti kilọ fawọn ọmọ Naijiria paapa awọn to kopa ninu iwọde lati tako ijọba PDP nigba ti wọn fi owo kun owo epo bẹntiroo
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ọmọ Naijiria ti n ke irora lori bi iroyin ṣe gbode pe alekun ti ba iye owo ti wọn yoo maa san lati fi ra jala epo bẹntiroo.Àìní sí iná mọ̀nàmọ́ná ní Eko ló ń kọ áwọn èèyàn lóminú
Ti iroyin naa ba jẹ́ ootọ, o kere tan ekunwo epo bẹntiroo lati naira marundinlaadọjọ si naira mọkanlelaadọjọ,₦151.56k, ni awọn ọmọ Naijiria yoo bẹrẹ si ni lo nibẹrẹ oṣu Kẹsan an, ọdun 2020.
Ikede yi ti ọpọ ileeṣẹ iroyin ni Naijiria ti gbe lọjọru jẹ eyi ti BBC ko ti ribi fidi rẹ mulẹ.
Ṣugbọn awọn eeyan Naijiria ko tilẹ jẹ ki iroyin naa balẹ ki wọn to ma lọgun pe ẹkunwo yi yoo mu inira ba ara ilu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ padà sí iléèwé
- Iléeṣẹ́ ìròyìn Daily Trust gbọdọ̀ san N6 bilion nítorí ìbanilórúkọjẹ́- Femi Fani Kayode
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
Kini iroyin naa sọ ati pe bawo lo ṣe bẹrẹ?
Iwe tawọn akọroyin n lo lati fi kin ọrọ lẹyin nipa alekun yi ni wọn sọ pe o wa lati ọdọ arakunrin kan ti o n ṣiṣẹ pẹlu PPMC ọgbẹni D.O Abalaka.
Gbogbo igbinyanju BBC lati ba awọn alakoso PPMC sọrọ nipa ikede yi ko ti seso re.
Ni kete ti a ba ri aridaju ọrọ yi fi mulẹ, a o jẹ ki ẹ gbọ.

Oríṣun àwòrán, others
Níbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, jálá epo bẹtiróò fò fẹ̀rẹ̀ sí ₦143.80
Ijọba ti kede ẹkunwo epo bẹntiro lati ọgọrun un nairia le ni naira mọkanlelogun àbọ̀ (N121.50) si naira mẹtalelogóje le ni ọgọrin kọ́bọ̀(N 143.80).
Ajọ PPPRA to n ṣamojuto owo epo rọbi lo ṣe ikede naa ninu atẹjade kan to fi sita lọ́sàn Ọjọrun.
Àjọ náà ni "lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò kíkún àti nǹkan ti ọjà epo bẹtiróò ń sọ lágbàyé nínú oṣù kẹfa, àwọn ṣe àmójútó ìyé tó to gbé epo jáde tí ẹnikẹni kò sì ni pàdánì owó"
"Nítorí náà, a rọ àwọn ilé epo láti máa ta jálá epò bẹtiróò ní ogóje náìrà sí náírà mẹ́tàlélógóje ó lé ọgọ́rin kọ́bọ̀, fún oṣù keje ọdún 2020."
A rọ gbogbo àwọn ilé epo aládani kí wọ́n ta ọjà wọ́n ni gbèdéke iye ti PPPRA pè é.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Alaafin, MC Oluomo, Ejiogbe àti ọmọ Tinubu wà lára àwọn tí yóò pèsè iṣẹ́ 774,000
- Baba Suwe bọ́ lọ́wọ́ àìsàn, ó bẹ̀rẹ̀ tíátà padà
- Jàndùkú yabo ilé ìwòsàn ìjọba sáájú ìpàdé akọ̀ròyìn táwọn dókítà pè
- Ojú Shagbada Erigga rèé lẹ́yìn tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ l'Akinyele ní Ibadan
- Ìdí tí lílọ Yúrópùù fi di èèwọ̀ fún Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè adúláwọ̀ míì
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
Ẹgbẹ́ àwọn aladani tó n ta epo bẹtiró ní Nàìjíríà (IPMAN) ti sàlàyé pé, gbogbo ìlànà ti ìjọba là sílẹ̀ ni àwọ́n ń tẹ̀lé nípa títa epo bẹtiró.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ààrẹ ẹgbẹ́ IPMAN ní Nàìjíríà Chinedu Okoronkwo sàlàyé pé, ẹ̀dínwó epo látọ̀dọ̀ ìjọba tí kásẹ̀ nílẹ̀, síbẹ̀ àjọ tó n rí si iye owó ti wọ́n n ta epo lábẹle náà n fi gbédéke iye tí ilé epo aladáni gbọdọ̀ ta epo síta.
Ó ní gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ló ń tẹ̀lé àṣẹ́ ijọba nípa títà á ni ìye ti ijọba sọ, tí àwọn míràn tilẹ̀ ń tà á ni ìye tó tún kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Okoronkwo ní ọ̀pọ̀ ló ń fi náírà méjì, mẹ́ta tà á nítorí wọ́n fẹ́ padà lọ ra òmíràn lásìkò, kí wọ́n sì pa owó wọ́n kí wọn sì kó èrè wọ́n jọ.
Nígbà ti BBC Yoruba beere lórí ìdí tí àwọn alagbata míràn fí n ta jálá epo kan ní náírà márùndínláàdójé, nígbà tí ìjọba ni kí wọ́n máa tà á ni náírà mọ́kànlélọ́gọ́fà àbọ̀, Okonkwo sọ pé àsìkò péréte náà ló kù tí irú wọ́n kò fì ni lé ṣe bẹ́ẹ̀ mọ nítorí tí ará ìlú bá rí ibi ti epó ti dínwó, wọ́n kò ni lọ sí ibi ti ó ti wọ́n.
Naira mọ́kàndínlọ́gọ́fà ní àwọn ilé epo míràn ń tà á ní ìpínlẹ̀ Porthacourt, sùgbọ́n láìpẹ́ nǹkan ti olúkúlùkù bá rà, ni wọ́n ó tà, ẹni tó bá sì rà ọjà ọ̀wọ́n, náà ni yóò wá bí yóò ṣe tà á.

Kíní ìtúmọ owó ìrànwọ lórí epo (Fuel Subsidy) tí ìjọba yọ báyìí
Ǹkan tí o túmọ sí náà ni pé, ètò ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní, nítóri àsìkò yìí ní àwọn ojúlówó onísòwò epo yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ rí tajé ṣe.
Okonkwo sàlàyé pé, sáájú àsìkò yìí, àwọn ti kò ṣòwò epo máa ń gbà owó ìrànwọ́ ìjọba lọ́nà àìtọ́, sùgbọ́n nísìnyí kò ni sí gbogbo ìyẹn mọ́.
O fí kún-un pé, gbogbo àwọn ibi ti wọ́n tí n fọ epo lórílède Nàìjíríà náà yóò le ṣiṣẹ́, èyí yóò sì mú àdíkù báa ìbéèrè fún níná owó dọla nígbàgbogbo, nítórí pé èyí gàn ló n kóba ètò ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà.
Ó ní tí eyí bá wáye ǹkan yóò túbọ̀ rọrùn ni Nàìjíríà ní.
Sáájú ni àjọ PPPRA ti sọ pé oṣooṣù ni àwọn yóò maa kéde iyé ti wọ́n yóò ma tepo lábẹ́lé ni Naijiria.
Láti inú oṣù kẹta tí owó epo ti jáwálẹ̀ lágbàyé ni PPPRA ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tuntun yìí ti àwọn ilé epo aládàni míràn sì ketí ọ̀gbọin sí ikéde olóṣooṣù náà.

Oríṣun àwòrán, Twitter/PPPRA
Epo bẹntiró ti di N121.50 ní Nàìjíríà báyìí- Àjọ PPPRA
Fuel Price: Àjọ PPPRA epo bẹntiró ti di N121.50 ní Nàìjíríà báyìí
Ijọba ti kede ẹkunwo epo bẹntiro lati ọgọrun un nairia le ni naira mẹtalelogun aabọ(N123.50) si ọgọrun un nairia le ni naira mókanlelogun aabọ(N121.50).
Ajọ PPPRA to n ṣamojuto owo epo rọbi lo ṣe ikede naa ninu atẹjade kan to fi sita.

Oríṣun àwòrán, OSatuyi
Ajọ PPPRA ṣalaye ninu atẹjade naa wi ẹdinwo epo bẹntiro naa wa ni ibamu pẹlu idasilẹ ṣiṣe ayẹwo owo epo rọbi oṣu kẹta ọdun yii.
Bi owo epo rọbi ṣe walẹ lọja agbaye lo jẹ ki adinku ba owo tawọn alagbata epo fi n gbepo wọ Naijiria lati oṣu kẹta ọdun 2020 nitori ajakalẹ aarun coronavirus.
Ijọba ti kọkọ ṣe edinwo epo bẹntiro lati naira marunlelogoje si naira marunlelọgọfa lọjọ kejilogun oṣu kẹta.
Lati oṣu kẹta naa ni ijọba ti sọ pe loṣooṣu ni ajọ PPPRA yoo maa ṣe ayẹwo owo epo bẹntiro ni Naijiria.
- Pásítọ̀ Adeboye ṣelérí àti fojú aṣebi hàn lórí ikú Omozuwa, Amnesty International pẹ̀lú kọminú
- Ènìyàn 307 ló lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Ọjọ́ Aiku
- Mo parí iṣẹ́ àṣepatì 239, iṣẹ́ 236 míì ń lọ lọ́wọ́- Seyi Makinde
- Kàyééfì BBC News Yorùbá gbé òtítọ́ òògun owó yẹ̀wò
- Nǹkan oṣù obìnrin le jáde ní imú tàbí ìdodo yàtọ̀ sí ojú ara - Dókítà
Ẹ̀dínwó epo bẹntíró tí NNPC kéde kò kan ará ìlú
Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ti gbàlù gbájó lẹ́yìn ti wọ́n gbọ́ ìkéde pé ilé iṣẹ́ to n rí si epo rọ̀ọ̀bì ni Nàìjíríà (NNPC) tí mú àdínkù bá owó epo rọ̀ọ̀bì.
Sùgbọ́n oo àlàyé láti ẹnu olùdarí ìjáde àti ìwọlé epo nínú ẹgbẹ́ IPMAN to tún jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ náà tẹlẹ̀ Mike Osatuyi, sàlàyé pé, èdinwó náà ko tii sí fún ará ilú.
O ní gẹ́gẹ́ bi àjọ NNPC ṣe ti kéde láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ epó bẹntiro tí n já wálẹ̀ l'Ágbàyé pé oṣooṣù ni àwọn yóò ma sọ iye ti àwọn ará ilú yóò maa ra epo.
Osatuyi ni lóòyọ́ ni wọ́n kéde, sùgbọ́n lẹ́yìn ìkéde wọ́n ó yẹ ki àjọ PPMC náà fi ikéde tirẹ̀ sita láti mọ iyé ti o tọ́ fún ará ilú láti maa ràá.
- Ẹ ṣílẹ̀kùn ọjà àmọ́ ẹ ti ilẹkun ilé Ọlọ́run, ejò lọ́wọ́ nínú - Oyedepo pariwo
- Àjọ NCDC kéde ènìyàn 195 míràn tó ní ààrùn Covid-19 l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà
- Ìjọba dín owó epo bẹntiró sí N108
- Kòkòrò coronavirus sì wà lára mi títí mo fi kúrò ní ibùdó ìtójú àwọn alárùn covid-19 l'Eko- Motosinoluwa Afolaranmi
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
"Ọ̀rọ̀ epo kìí ṣe bi iṣu àti ata lọ́ja, wọ́n maa n pé olúkúlúkù láti wá gbé epo ni, iyé ti ẹni náà ba si báa ni yóò ràá, nítori náà iye ti olúkúlúkò yóò si taa yoo yàtọ̀ si ara wọ́n"
Ẹkúnrẹ́rẹ́ àlàyé Mike Osatuyi rèé
Ìjọba dín owó epo bẹntiró sí N108
Fuel price: Ìjọba dín owó epo bẹntiró láwọn ibùdó ìjápo (depot) sí N108 láti N113

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede adinku owo epo bẹntiro kuro ni naira mẹtalelaadọfa naira to wa tẹlẹ si naira mejidinlaadọfa naira gẹgẹ bi iye ti wọn yoo maa ta jala epo lawọn ibudo igbepo gbogbo lorilẹede Naijiria.
Atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si karakata owo epo lorilẹede Naijiria, PPMC fi sita ṣalaye pe igbesẹ naa wa lati tubọ mu ki ọja rẹ tubọ ta si ni ibamu pẹlu aṣẹ ajs to n ri si idiyele owo epo lorilẹede Naijiria, PPPRA gbe kalẹ lori iye ti wọn yoo maa ta epo lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, NNPC/Twitter
Ọgbẹni Musa Lawan, oludari agba ileeṣẹ to n ri si idunadura epo lorilẹede Naijiria, PPMC, ti atẹjade naa kede o fi ọrọ naa sita nio igbesẹ adinku owo epo lawọn ibudo ijapo gbogbo naa yoo mu ki wọn lee tete ta omilẹgbẹ biliọnu jala epo ti waọn ni kaakiri aka wọn sita lowo ti ko ga ju ara rọ fawọn onibara rẹ.
O fi kun pe lẹyin ti wọn fojuwo bi oju ọjọ ṣe ri lọja epo ni wọn fi gbe ẹdinwo naa kalẹ.
Amọṣa, ẹdinwo tuntun yii ko kan epo disu.

Nigeria lockdown: Báyìí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe dá ìrìnkèrindò ọkọ̀ dúró l'Abuja
Iroyin lati Abuja, to jẹ Olu ilu orilẹede Naijiria ti fi han pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to waye nibẹ ko ṣẹyin iṣẹ takuntakun awọn agbofinro lati ri pe awọn eeyan tẹlẹ ilana ti ijọba gbe kalẹ lasiko yi.
Ọpọ awọn eeyan to n kọja lati ipinlẹ Nasarawa to wa lẹba ilu Abuja ni ko raye kọja, ni bi awọn agbofinro ọhun ṣe n da awọn ti ko ba wọ ibomu pada lẹnu ibode ilu naa.

Oríṣun àwòrán, Osatuyi
Iroyin ni wamuwamu ni awọn ọmọ ologun, awọn oṣiṣẹ abo ararẹni labo ilu, NSCDC ati ajọ to n risi igboke gbodo ọkọ, FRSC ro lẹnu ibode ọhun.
Bi wọn ṣe n ṣayẹwo gbogbo awọn to ba fẹ kọja naa ni wọn n da ẹnikẹni ti ko ba wọ ibomu pada, tabi ki irufẹ ẹni bẹ jẹ bulala.

Ayẹwo ti awọn agbofinro naa n ṣe ti fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ, ti ko si dun mọ awọn eeyan naa ninu nitori wọn ni awọn mii ma n lo wakati mẹrin lojukan.
Ṣaaju ni minisita olu ilu naa ti sọ fun awọn olugbe agbegbe bi Nyanya lati joko sile wọn, ṣugbọn ọpọ ninu awọn eeyan ọhun sọ pe wọn ni lati jade si igboro nitori atijẹ.
Lara awọn eeyan ọhun to ba BBC sọrọ ni ti Coronavirus ko ba pa wọn, ebi lo ma pa wọn sile, nitrori naa ko si ohun miran ti wọn le ṣe ju ki wọn jade.
Ni kete ti ijọba apapẹ dẹwọ igbele naa lọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 2020, ohun akọkọ tawọn eeyan naa ṣe ni abẹwo sile ifowopamọ ti wọn n lo lati gba owo wọn.
Coronavirus symptoms and treatment: Bí Eko ati Abuja ṣe rí rèé lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n dẹ ọwọ́ igbele Coronavirus
Ní báyìí tí ìjọba àpapọ̀ tí dẹ okun lọrun àṣẹ kònílé ó gbélé, ó dàbí ẹni pé àwọn aráàlú Èkó àti Abuja tí gbàgbé òfin títa kété síra ẹni.Irinke-rindo ikọ BBC làwọn ojú pópó n'ilu Eko lónìí ọjọ́ Ajé, ṣàkíyèsí pé, ní agbègbè Ojodu-Berger, ṣe ni àwọn aráàlú ń du ọkọ wọ, tí wọ́n ko si bọ̀wọ̀ fún òfin ìtakété síra ẹni, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọkọ èrò ń gbé èrò
kún inú mọto wọn dẹnu.
Ṣáájú sì ni ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko ti kede pé ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún èrò táwọn ọlọkọ ń gbé sínú ọkọ wọn tẹ́lẹ̀, ní kí wọ́n máa gbé báyìí, kí àwọn èrò leè ráyè takete síra wọn.Kódà, ní ibùdókọ̀ ọkọ èrò ìjọba, BRT to wá ní Berger, àwọn èrò tó fẹ́ wọnú àwọn ọkọ náà kò bọ̀wọ̀ fún òfin ìtakété síra ẹni lórí ila tí wọn tó sì, láti wọ ọkọ náà.Bi o tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn yìí ló aṣọ ibomu tó jẹ́ atọwọda, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera ti kede tẹ́lẹ̀ pé èyí kò tó láti dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ Coronavirus.

Ní olú ìlú ilẹ wá, Abuja, ẹwẹ, àwọn òṣìṣẹ́ nibẹ ya bo ojú pópó láti lọ síbi isẹ koowa wọn lọ́jọ́ Aje.Ní agbègbè Nyanya-Mararaba tí ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ń gbé, ṣe ni àwọn agbofinro gbé igi dabu ọna, láti tọpinpin lílọ bibọ ọkọ sí Ìpínlẹ̀ Nasarrawa, tíì ṣe Ìpínlẹ̀ miran to mule tí Abuja, tí wọ́n si ń rí dájú pé àwọn èèyàn náà wọ aṣọ ìbòjú.Kódà, àwọn agbófinró ń yẹ ara àwọn èrò àti ọlọkada wo pẹ̀lú ẹ̀rọ, kí wọ́n tó kọjá, tí wọn sì n da àwọn ọlọkọ tó bá lòdì sí òfin pada.

Wàyí o, bi aibọwọ fún òfin ìtakété síra ẹni ṣe ń wáyé n'ilu Eko, naa lo ṣe ri ni Abuja, nítorí báwọn èrò àti ọlọkada ṣe tó fún ayẹwo ọlọ́pàá, lòdì sí òfin ìtakété síra ẹni, ṣe ni wọn to si ẹyin ara wọn lai fi ààyè
kankan silẹ.
Ẹnikan nínú wọn tiẹ̀ sọ fún ikọ ìròyìn BBC pé, àǹfààní ńlá ni ìjáde wọn òní jẹ láti gba atẹgun sára.

Coronavirus: Ijọba ìpínlẹ̀ gbé òfin jáde fún àwọn tó n padà sẹ́nú iṣẹ́ lẹ́yìn k'ónílé o gbélé
Oni ọjọ Aje ni orilẹ-ede Naijiria bẹrẹ si ni dẹ okun ofin konile-o-gbele to fi sita nitori coronavirus nilu Abuja, ipinlẹ Ogun, ati ipinlẹ Eko lati le din ipa buruku ti aarun naa le ni lara ọrọ aje ku.
Lootọ Aarẹ Buhari lo paṣẹ naa, ṣugbọn gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fi awọn ilana ti awọn eeyan gbọdọ tẹle sita.
Lara awọn ilana naa ni pe awọn oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele 'Level 15' soke nikan ni yoo pada sẹnu iṣẹ.
- Isede yoo maa wa lati aago mẹjọ alẹ si mẹfa idaji. Awọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn ṣe koko bi i ẹka epo bẹtiro, ounjẹ, iṣẹ agbẹ ati bẹẹbẹ lọ nikan ni ofin yii ko de.
- Awọn ọja ti wọn ti n ta ounjẹ yoo ma jẹ ṣiṣi lọjọ Iṣẹgun, Ọjọbọ ati Abamẹta laarin aago mẹsan owurọ si mẹta ọsan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Awọn ọja ati ṣọọbu ti kii ṣe ti ounjẹ yoo maa ṣi ilẹkun wọn laarin aago mẹsan owurọ si mẹta ọsan ni ọjọ Aje, Ọjọru ati ọjọ Ẹti. Gbogbo awọn ontaja lo si gbọdọ lo ibomu-bẹnu, ki wọn o si tun ṣeto sanitaisa ni ọja wọn.
- Dandan ni fun araalu lati lo ibomu-bẹnu lasiko ti wọn ba wa ni ita gbangba.
- Awọn banki ati ileeṣẹ aladani ko gbọdọ faaye gba ju ìdá ọgọta oṣiṣẹ wọn lẹẹkan naa, wọn si gbọdọ maa ṣiṣẹ laarin aago mẹsan owurọ si mẹta ọsan.
- Fun awọn ile ounjẹ, gomina Sanwo-Olu sọ pe wọn le maa taja laarin aago mẹsan aarọ di aago meje alẹ nitori awẹ Ramadan to n lọ lọwọ. Ṣugbọn, onibara wọn kankan ko gbọdọ joko jẹun nile ounjẹ.
Ṣugbọn ṣa, ofin ṣi de ipejọpọ ọpọ eniyan, awọn ile ijọsin ati ileewe.
Awọn to ni aarun coronavirus ni Naijiria pọ si lọsẹ to kọja, pẹlu bi eniyan 2,558 ṣe ni aarun naa bayii, mẹtadinlaadọrun si ti ku.

Gómínà ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu ti kede pé pé kí gbogbo òṣìṣẹ́ ìjọba láti ipile kejila si isàlẹ̀ jòkó silé wọn fún ọsẹ̀ méji.
Sugbọ́n ó ni ikéde yìí yọ àwọn to ṣe àwọn osiṣẹ́ eleto ààbò, awọn panapana àti àwọn onimọ iṣegun.
Bakan náà ni Gomina ni ìjọba ti ṣe àfikún àwọn ilé iwosan ti wọ́n le ko àwọn ènìyàn si.
" a mọ bi ǹkan to wà ni ìwáju wa ṣe toni tó a si ti ṣetan láti koju rẹ, a ti n ba àwọn asoju àwọn ọlọja sọ̀rọ̀ àti àwọn olóri awakọ láti ri dáju pé wọ́n tẹle ìlàna jijina si ẹnikeji."
"Ri dájú pe o wà ni ìgbéle fun ọjọ mẹrinla ti o ba ṣẹsẹ tirin ajo dé si Naijiria. Eyi ni ǹkan to tọna láti ṣe."
" A ni láti ji giri si idojukọ wa. A o bori ti ifọwọsowọpọ ba wa láàrin àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko, a ti ri irú idojukọ bayiìí tẹlẹ".
Ẹ̀wẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara náà ti ni ki gbogbo oṣiṣẹ tirẹ maa siṣẹ́ láti ilé.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Nínú àtẹjade kan ti Gomina ìpínlẹ̀ Kwara Abdulrahman Abdulrazaq fọwọ́ si lo ti sàlaye pé botill jẹ́ pé ìpínlẹ̀ Kwara ko tii gba nipa ẹnikẹni to ni à[run náà sibẹ̀, iná ko se fi sori orule sùn.
Gomina fi kún pé igbẹ́sẹ̀ ti n lọ lọ́wọ́ lóri eto la'ti mu ki àwọn ilé iwosan ipinlẹ Kwara lé sàmójú to ààrun náà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
Ní báyìí eniyan ọgbsn lo ti ni ààrun náà ni orill èdè Naijira
























