Lesbian Movie Ife: Òṣèré méjì yìí ń fi ẹ̀wọ̀n runmú tóríi fíìmù "Ife" táwọn obìnrin ń bá ara wọn lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, PAMELA Adie
Awọn oludari fiimu agbelewo meji n fi ẹwọn runmu ti wọn ba kọ lati tẹti si ikilọ ajọ to n ri si bi sinima ṣe n jade ni Naijiria wi pe fiimu ọhun ko gbọdọ jade si igboro nitori pe o niṣe pẹlu ibalopọ abo si abo.
Ọrọ ajọ to n risi bi fiimu ṣe n jade (NFZCB) ati awọn oni fiimu gan to ki wọn fo wọn ṣe fiimu pẹlu.
Olukotan ere ọhun, Pamela Adie ati oludari ere rẹ Uyaiedu Ikpe-Etim ti ni dandan afi ki fiimu agbelewo ti awọn n ṣe lọwọ ko jade fun iworan awọn ọmọ Naijiria ṣugbọn Ajọ NFVCB ni laye ko ni foju kan igboro ati pe awọn ko ni buwọlu u nitori o lodi si ofin ibalọpọ akọsakọ tabi abo si abo ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe gbogbo ọna ni awọn olukọtan ati adari ere yii n wa lati jẹ ki fiimu naa jade sori ayelujara ti awọn ajọ naa ko ni mọ, ṣugbọn ajọ ọhun pẹlu n ṣe oju ni alakan fi n sọri lati maa fi imu finlẹ lori gbogbo ayelujara pe fiimu naa ko gbọdọ lu síta.
Gẹgẹ bi ọga ajọ naa ṣe sọ, Adebayo Thomas Adie ati Etim n fi ẹwọn ọdun mẹrinla ṣere fun mimu igbelarugẹ ba ibalopọ abo si abo ni ilu to ni ofin to lodi si iru aṣepọ bẹẹ.
Awọn oṣere naa n ṣeto wiwo idakọnkọọ fiimu ọhun ni ilu Eko ni opin ọdun yii nitori pe wọn nigbagbọ pe awọn o nilo aṣẹ ijọba.
Bakan naa ni wọn yoo fi fiimu naa han ni oke okun paapaa julọ ni Canada ninu oṣu kẹwa ọdun.
Gẹgẹ bi Pamela Adie ṣe sọ, erongba rẹ ni lati ṣe afihan ibalopọ abosabo ati awọn obinrin to wa niru ipo yii ni Naijiria lagbo osere.
O sọ fun BBC pe bi wọn se maa n fi awọn obinrin ti wọn nifẹ si obinrin han ninu ere Nollywood, ni ọpọ igba wọn maa n fi wọn han bii ẹni to lẹgbẹ tabi to n ko ọrẹ kọrẹ tabi wọn tilẹ mu u ni tulasi lati se iru nkan bẹẹ ni.
" Ẹ o le ri ere agbelewo Nollywood kankan to sọrọ nipa LGBT, ko si nkan nipa iriri awọn obinrin wọnyi loju aye gangan.
"Ifẹ ṣe afihan yii lati di alafo to wa laarin rẹ ati lati mọ bi nkan se n lọ lori ọrọ yii ni Naijiria."
Ọrọ ibalopọ akọ si akọ tabi abo si abo jẹ ọrọ to le koko ni ọpọ orilẹede ni Africa, eyi ko si yatọ ni Naijiria naa, nitori pe awọn ẹlẹsin ati awọn to ka asa ati ișẹse ni gboogi niwọn ni awujọ wọn.
Bi awọn ẹlẹsin Musulumi ṣe lodi si i naa ni awọn onigbagbọ ko fara mọ ọ.
Orilẹede Naijiria jẹ ọkan lara awọn orilẹede ọgbọn to tako o to si ri i gẹgẹ bi iwa ọdaran labẹ ofin pẹlu ijiya to lagbara bi ẹnikẹni ba taṣẹ agẹrẹ.














