Oyo Party Politics: Lanlehin kéde ìparí gbogbo ètò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Olufemi Lanlehin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Lanlehin

Lẹ́yìn ìpàdé àwọn adari, ololufẹ àti alatilẹyin rẹ̀, Sẹneto Olufemi Lanlehin (SOLAN) ti kéde ìparí gbogbo ètò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC)

O fẹ kuro láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress (ADC), ìyẹn ẹgbẹ́ òṣèlú ọlọwọbọwọ, tó wà tẹlẹ.

Lanlehin figba kan jẹ oludije sípò gómìnà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, nínú ìdìbò ọdún 2019.

Bẹ lo tun jẹ aṣòfin àgbà fún ẹkun Gúúsù Òyó láàrin ọdún 2011 sí 2015.

Nígbà tó n sọrọ nínú ìpàdé tó wáyé nílé rẹ̀ nibadan,Lanlehin sàlàyé gbogbo ìpàdé ipẹtusaawọ tó ti lọ, latari ìgbésẹ rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

O fi kun pe oun lọ ṣe ipade labuja lójóbọ̀, ọjọ Kẹwàá, oṣù Kesan-an, ọdún 2020.

Àkọlé fídíò, Ladoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Nibi ipade yi, o loun sọ gbogbo ipa tí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC n sa, láti ríi pé gbogbo aawọ dopin nínú ẹgbẹ́ àti láti fa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ti lọ, padà wọlé.

"Aayan ipẹtusaawọ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Jigawa, Alh. Mohammed Badaru Abubakar n lewaju rẹ̀, pẹlu iranlọwọ lat'ọdọ Gómìnà mẹrin mìíràn, nínú èyí tí Gómìnà Kayode Fayemi tipinlẹ Èkìtì gbé wà, ti n ṣe àṣeyọrí gidi lórí iṣẹ tí ẹgbẹ́ gbé lé wọn lọwọ," Lanlehin ṣàfikún.

Nígbà tó n fi ọkàn àwọn ololufẹ rẹ̀ tó wá láti gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹtalelọgbọn ìpínlè Òyó balẹ̀ pé òhun kò níí yẹsẹ kúrò nínú òṣèlú tó nifẹẹ ìlú, Lanlehin sọ fún gbogbo àwọn tó wá sipade náà pé iṣisẹ sinlu ni òpó kan pàtàkì tí òṣèlú ohun dálé lórí, tó sì fi kun-un pé òhun o máa ṣe ohun gbogbo láti ran ọmọnìyàn lọwọ.

Nínú ọrọ tí wọn sọ, Ẹni-ọwọ Ezekiel Adeniran, Olóyè E. O. Láoyè, Hon. Bili Ajana, Yeye Yetunde Ajibola, Hon. Gaphar Ojetola, Hon. Habib Balogun, Alh. Muraina Kakako, at'awọn mìíràn, kí Sineto Lanlehin ku ọkàn akin àti òṣèlú tó koni móra t'oun ṣe.

Bákannáà, àwọn aṣojú ìjọba ìbílẹ̀ mẹtalelọgbọn to fèsì sàlàyé pé pipada sí ẹgbẹ́ òṣèlú APC fun Lanlehin ṣe e fi we ọmọwale, nítorí igun ibè ló ti bẹrẹ òṣèlú.

Nínú ìpàdé ohun, ni àbá ti wá pé kí Lanlehin at'awon alatilẹyin rẹ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ti ẹnikẹni ko sì kọ sí àbá náà.

Lára àwọn tó wà níbi ìpàdé náà ni Olóyè Sunday Ajadi (Abeebo) lati Ogbomoso, Alh. Rafiu Afuku láti Ìséyìn, Alh. Adebayọ Waheed (Adwas) lati Atisbo, Erelu Funkẹ Olayanju láti Ìlà-Oòrùn Ìbàràpá, àti Omowe Akintola láti Àríwá Ìbàràpá.

Àwọn mìíràn ni Hon. Adedokun láti Àríwá Ìbàràpá, Alh. Suara Ogunyemi pelu Hon Adeoye Sobaloju (Lord Moro), àti Otunba Bode Ashiru lati Ìbàdàn, Otunba Kunle Folarin láti Afijio, Alhaja Omotunde Lawal láti Egbeda, Hon. Tiri Olowoake láti Oluyole, Hon. Adekunle Adeolu (Ultimate) láti Ido, pẹlu Hon. Gbenga Aluko àti Hon. Kayode Oladele lati Ìbàdàn.

Hon. Tolani Adigun, Salami Dikko àti Sunday Babatunde náà wà nikale.