Shan George: Àgbàọ̀jẹ̀ òṣèré Nollywood ṣetán láti ṣègbéyàwó pẹ̀lú ọkọ kẹẹ̀rin lẹ́ni ọdún 50

Shan George

Oríṣun àwòrán, Instagram/shan george

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lootọọ ni pe ọrọ ifẹ bi adanwo ni. Ati pe ohun to dara ni ifẹ jẹ gẹgẹ bi awọn eeyan ti maa n sọ.

Eyi lo difa fun agbaọjẹ oṣere Nollywood ẹni aadọta ọdun, Shan George to kede pe oun ṣetan lati ṣe igbeyawo fun igba kẹẹrin lẹyin ti igbeyawo rẹ mẹta akọkọ ti fori ṣanpọn.

Ṣebi Yoruba bọ, wọn ni ti ẹṣin ba da ni, aa tun un gun ni.

Adia fun George to sọ loju opo ayelujara Instagram rẹ pe "bi o tilẹ jẹ pe ẹru n ba mi, mo ṣi n ṣiyemeji nitori awon iriri mi at'ẹyin wa, ṣugbọn o dabii pe eleyii yoo san, ko yẹ ki n bẹru."

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

"Nitori naa, mo sọ pe mo gba lati fẹ ọrẹ korikosun mi, ọmọ iya mi, alabaṣiṣẹpọ mi ati ọmọ ipinlẹ Cross River bii temi naa," Shan George lo sọ bẹẹ.

George ni "ẹ jẹ ki n gbiyanju rẹ lẹẹkan sii fun igba to kẹyin. Ko tii ju fun mi. Bẹẹ ni, emi naa nifẹ rẹ."

Awọn ọrọ ifẹ ti gbajugbaja oṣere naa kọ soju opo Instagram rẹ ree koda o tun fi oruka alawọ idẹ sibẹ eyi to ṣafihan pe o ti gba lati ṣegbeyawo pẹlu ọkunrin mii.

Ẹru n bami lati ṣe igbeyawo mii- Shan George

Gbajugbaja oṣere naa ni ti oun ba ti ro ọrọ igbeyawo, niṣe loun maa n gbe pati nitori o maa n mu ẹru ba oun.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

''Emi nikan ni awọn obi bi, ni gbogbo aye mi, emi ni mo maa n daabo bo ara mi lọwọ awọn to ba ti fẹ dunkoko mọ mi,'' George lo sọ bẹẹ.

George ni ''nitori naa, ẹni ti o ba fẹ fẹmi sile gẹgẹ bi iyawo gbọdọ mu mi bi ọmọ iya rẹ, bi bẹẹ kọ, n ko le ṣe iyawo pẹlu ẹnikan mọ,

Shan George ni o tẹ oun lọrun ki oun da duro ju ki oun lọ ko si ọwọ ọkunrin kan ti ko ni fun oun ni ibalẹ ọkan lọ.

Nigba to sọrọ lori boya o maa n ronu nigba to ba da wa, o ni iṣẹ ti oun n ṣe gan an ko faye gba pe ki oun maa da wa nikan.

O ni ọpọ igba loun maa n ka iwe ti oun ko ba wa lẹnu iṣẹ tiata ti oun yan laayo.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Ọmọkunrin meji ti wọn ti dagba bayii, Delnoi ati Jaga ni Eleduwa fi jinki Shan George.Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹẹrin ọdun 1970 ni wọn bi oṣere Shan George.Fasiti ilu Eko, UNILAG lo ti kẹkọọ gboye akọkọ ninu ẹkọ ere ori itage.Lẹyin to kẹkọọ gboye tan lo bẹrẹ si ni ṣee iṣẹ to yan laayo, iṣẹ tiata.Oṣere ni, oludari ati olootu ere tiata si ni pẹlu. George di ilumọọka lọdun 1997 lẹyin to kopa ribiribi ninu ere ti akọle rẹ n jẹ "Thorns of Rose."