Sotitobire: Adájọ́ sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìdájọ́ fún Wòlíì Sotitobire Alfa Babatunde

Sotitobire

Adajọ to n gbọ ẹjọ ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan gbajugbaja wolii ijọ Sọtitobirẹ Praising Chapel ni ilu Akurẹ, Alfa Babatunde ti ọpọ mọ si sọtitobirẹ atawọn mẹfa miran ti sọ ọjọ ti yoo gbe idajọ kalẹ.

Wọn n fi ẹsun kan wolii Sọtitobirẹ ati awọn oṣiṣẹ ijọ naa mẹfa pe wọn lọwọ si bi ọmọ ọdun kan, Kọlawọle Gold ṣe poora ni ileejọsin naa ni oṣu kọkanla ọdun 2019.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa kede bi idajọ ẹjọ naa yoo ṣe lọ lẹyin ti gbogbo awọn agbẹjọro fun igun gbogbo ti ọrọ kan ti fi ẹnu awijare ati atotonu wọn lori ẹjọ naa jona sibi kan.

Àkọlé fídíò, 'Búrẹ́dì tí wọn ó fi jẹ ẹ̀wà ni wọ́n lọ rà ni wọ́n pàdé ikú gbígbóná'

Ni oṣu keji ọdun yii ni igbẹjọ bẹrẹ lori ẹsun ijọmọgbe ati igbimọpọ hu iwa ijọmọgbe ti wọn fi kan awọn meje naa.

ẹlẹri mẹsan ni awọn agbẹjọro ijọba pe nigba ti awọn agbẹjọro fun Wolii Sọtitobirẹ atawọn ọmọ ijọ rẹ naa si pe ẹlẹri marundinlogun ati ọpọlọpọ ẹri.

Awọn agbẹjọro, Wolii Sọtitobirẹ Oluṣọla Oke n fẹ ki ile ẹjọ wọgile ẹjọ naa. O fi kun un pe iṣẹ arumọjẹ lasan lawọn agbofinro DSS ṣe lori iwadii wọn.

O ni yatọ si pe wọn fi ọrọ wa Pasitọ naa lẹnu wo, ko si nnkan kan gboogi ti wọn lee mu jade gẹgẹ bi ẹri lẹyin ti wọn yẹ ile ẹjọ naa wo.

Bakan naa lawọn amofin yoku naa gbee nidi lori eyi.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀nà àtijẹ kan ṣoṣo táa ní ni Màálù àwọn Fúlàní ti bàjẹ́'

Amọṣa, agbẹjọro ijọba, ti amofin agba ipinlẹ Ondo, Adekọla Ọlawoye lewaju fun rọ ile ẹjọ naa lati fi iya to ba tọ jẹ wọn nitori awọn ẹri to ṣarajọ lori ẹjọ yii.

Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣọla wa ṣalaye fun awọn agbẹjọro naa pe idajọ oun lo kan. O kede pe oun yoo fi ọjọ idajọ ṣọwọ sawọn igun mejeeji laipẹ.

Titi di igba naa, o ni ki wọn da awọn afunrasi ọhun pada si ọgba ẹwọn Olokuta.

Ó yẹ kí Sotitobire gbọ́ ìdájọ́ lónìí ṣùgbọ́n ẹ wo bí ilé ẹjọ́ ṣe tún ṣe é

Sotitobire

Gẹgẹ bi igbejọ ṣi ṣe n lọ lọwọ lori ẹsun ti wọn fi kan oludasilẹ ijọ Sotitobire Praising Chapel l'Ondo, Wolii Alfa Babatunde atawọn ọmọ ijọ rẹ mẹfa tun ti farahan nile ẹjọ lonii lati lọ jẹwọ pe awọn sọ ọrọ ti wọn kọ silẹ.

Ẹwẹ, ko pẹ rara ni adajọ kede pe wan tun ti sun ẹjọ naa siwaju.

Ọsẹ kẹfa ree ti wọn ti gbọ ẹjọ wọn gbẹyin nigba ti wọn pa oju ẹjọ eyi ti agbẹjọrọ afurasi gangan n wi de ni ọjọ kejilelogun oṣu keje, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Oludari ẹka idajọ ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ idajọ, Grace Olowoporoku lo n lewaju ifarahan fun olupẹjọ nigba ti Agbẹjoro Olusola Oke ati Akinyemi Omoware n duro fun olujẹjọ.

Nitori bi ọmọ kekere kan, Gold Kolawole se dede poora ni Sọọṣi Wolii yii ni Akure ninu oṣu kọkanla ọdun 2019 ni ẹjọ ti wọn ṣi wa lori rẹ bayii.

Ẹwẹ, o yẹ ki awọn olujẹjọ wa sọ pe "bẹẹ ni a sọ ọrọ ti a sọ ti wọn gba ohun wa kalẹ" lonii ṣaaju idajọ ti adajọ Olusegun Odusola yoo da ṣugbọn wọn ti ni ko tun ri bẹẹ mọ.

Eyi lo mu ki wọn sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọbọ ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan yii.

Ọmọ kekere naa, Gold Kolawole yẹ ko ṣe ayẹyẹ ọdun meji lọjọ Abamẹta to kọja.

Àkọlé fídíò, Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí
Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Ó mà ṣe o! Gold Kolawole, ọmọ tó sọnù ní ṣọ́ọ́ṣì Sotitobire kò bá pé ọdún méjì ni 12/09/2020

Kọlọrun jẹ ki abiyamọ o jeere ọmọ.

Ọjọree bi ana yii lọdun meji sẹyin nigba ti ọmọ tuntun jojolo, Gold Kolawole dele aye, lai mọ ohun to n duro de oun.

Oni yii gan-an, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan, si ni Gold, ọmọ kekere to sọnu ninu ijọ Sotitobire Miracle Centre nilu Akure, ko ba pe ọdun meji.

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun 2019, ni iroyin jade pe, ọmọ naa deede poora ninu ṣọọṣi naa ni ẹka awọn ọmọde ti iya rẹ gbe e lọ, lọjọ isinmi naa.

Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Gbogbo igbiyanju awọn obi rẹ lati ri lo ja si pabo, koda ọrọ ti di tileeṣẹ ọlọpaa.

Iya ọmọ naa, Modupe Kolawole ṣalaye fun BBC Yoruba pe, inu oṣù kẹfa lawọn ṣẹṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ sí ṣọọṣi naa, ki iṣẹlẹ yii to o waye.

Iya Gold salaye bi ko ṣe ki n fẹ fi ọmọ rẹ silẹ ati bi awọn ẹṣọ ijọ ṣe ni o yẹ ko maa gbe ọmọ rẹ lọ si yara ti wọn n ko awọn ọmọ wẹwẹ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa, lo tun sọ nipa bo ṣe pada gbe ọmọ naa lọ si yara awọn ọmọ wẹwẹ, ati bo se wa di ohun to n kọ ni lẹnu lati sọ bi ọmọ ọdun kan ti ko tii le rin tabi sọrọ ṣe poora.

Iṣẹlẹ yii mu ki awọn agbofinro mu Pasitọ ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde, ti wọn si fi ẹsun kan oun ati awọn ọmọ ijọ rẹ bi i mẹrin, pe wọn mọ nipa bi ọmọ naa ṣe sọnu.

Àkọlé fídíò, Sotitobire church: Ẹgbẹ́ CAN ní kí ìjọba ṣe ohun tó yẹ

Lara awọn ẹsun ti awọn obi Gold fi kan Alfa ni pe, ko ja ọrọ ọmọ naa kunra lasiko ti wọn fi to o leti pe o sọnu.

Koda, Deji ti ilu Akurẹ, naa pe awọn obi, pasitọ ati awọn miran lati bura nidi oriṣa nipa nkan ti wọn mọ lori bi ọmọ naa ṣe sọnu.

Lati asiko naa si ni Pasitọ Alfa Babatunde ati awọn ọmọ ijọ rẹ ti wọn mu ti wa ni ọgba ẹwọn Olokuta nilu Akurẹ, nibi ti wọn n gba lọ sile ẹjọ fun igbẹjọ.

Ko tan sibẹ o, lasiko ti ọrọ bi ọmọ naa ṣe sọnu ṣi n gbona janjan, ni awọn eeyan kan dana sun ṣọọṣi Sotitobire, "nitori wọn fura pe ori pẹpẹ inu ṣọọṣi naa ni wọn ri Gold Kolawole mọlẹ si".

Àkọlé fídíò, 'Aràrá bíi tèmi, kó má rò pé kò sì ǹkan tó lè ṣe láyé ju iṣẹ́ agbe lọ'

Ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe ko si nkan to jọ nkan bẹ ẹ.

Koda, awọn eeyan naa pa ọkan lara awọn ọlọpaa to lọ ọ doola ṣọọṣi naa.

gbogbo bi igbẹjọ pẹlu Alfa Babatunse si se n lọ si lati sawari ọmọ naa ni BBC n mu wa fun yin.