Foluke Daramola: Òfin El-Rufai láti tẹ àfipábánilòpọ̀ ní ọ̀dá gbọ́dọ̀ di mímúṣẹ

folukedaramolasalako

Oríṣun àwòrán, Instagram/folukedaramolasalako

Gbajumọ oṣere tiata lobinrin, Foluke Daramola ti kede pe oun fara mọ titẹ awọn afipabanilopọ ni ọda.

Daramola ni iroyin to tii dun mọ oun ninu julọ ni ikede ofin ti ijọba ipinlẹ Kaduna ṣe, eyi to ni ki wọn maa tẹ awọn afipabanilopọ ni ọda.Lasiko to n ba akọroyin Punch sọrọ ni Foluke Daramola fi ero rẹ yii han sita.

Bakan naa ni oṣere tiata naa ni, oun tun dunnu si abala ofin naa to salaye pe, ki wọn yọ ẹyin ile ọmọ obinrin to ba fipa ba ọkùnrin lopọ.

Daramola wa n tẹnumọ pe, yoo dara ki ijọba ri daju pe ofin naa di mimuṣẹ, nitori ọtọ ni ki ijọba ṣe ofin, ọtọ ni ki wọn mu ṣẹ."

Aimọye ofin la ti ṣe ni Naijiria, ti a ko ṣe amusẹ rẹ. Boya wọn kan n ṣe ofin yii fáwọn mẹkuunu ni, ko si fáwọn alagbara.

Amọ tijọba ba ṣe amusẹ ofin titẹ awọn afipabanilopọ ni ọda bo ṣe yẹ, eyi yoo nipa lori ironu awọn eeyan to ba fẹ huwa buruku yii.

"Bẹẹ ba gbagbe, Foluke Daramola ti sọ saaju ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba pe, ọdọ ni oun wa nigba ti ayalegbe awọn kan fi tipa ba oun lopọ.

O ni ọpẹlọpẹ awọn ọrẹ oun to gba oun nimọran lati ke gbajare ọrọ naa sita, eyi to mu ki ẹru wiwo aya oun di fifuyẹ.