Funke Akindele: Ajirebi ní Funke Akindele f'óun lówó t'óun fi gba ilé ni, kò ra ilé f'óun

Ajirebi ati Kunle Afod

Oríṣun àwòrán, Instagram/kunleafod

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Odu, ti kii se aimọ fun oloko ni Kayode Olaseinde lagbo tiata lede Yoruba nitori awọn awada adẹrinposonu to maa n se.

Ọpọ ololufẹ rẹ si lo mọ si Pa Ajirebi nitori orukọ to fun ara rẹ ree ninu ere tiata, ti awọn eeyan si mọ mọ.

Yatọ si awọn ere itage ti Ajirebi ti se, eyi to fun ni okiki, awọn isẹlẹ kan to maa n waye nipa rẹ lasiko ojo lọdọọdun gan tun n mu ki Ajirebi wọnu iroyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Isẹlẹ naa ni ti ẹkun omi to maa n wọnu ile rẹ to kọ si adugbo Ikorodu nilu Eko, eyi to maa n daa laamu ni ọdọọdun.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Asiko ojo naa si ni Ajirebi maa n lọgun fun araye pe omi tun ti ya wọnu ile oun, to si ba awọn dukia oun jẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan maa n kaanu rẹ lawọn oju opo ayelujara sugbọn ibẹ lo mọ.

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣe pàtàkì kí obìnrin gbádùn ìbálòpọ̀ nítorí...'
Kayode Olaseyinde, Ajirebi

Oríṣun àwòrán, Ajirebi1 instagram

Amọ ọrọ yipada ni ọdun 2020 ta wa yii nigba ti oriiire gbe awọn alawo rere ko Ajirebi lasiko ti ọmọ rẹ, Samuel kigbe sori ayelujara pe ẹkun omi tun ti wọnu ile baba oun.

Ni kete ti iroyin naa balẹ ni ọgọọrọ awọn osere tiata lede Yoruba ti dide si ọrọ naa, ti wọn si n bẹbẹ fun awọn ẹlẹyinju aanu ati awọn akẹẹgbẹ wọn to rijẹ sẹku, lati gba ọrọ agba osere naa ro.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Koda, wọn tun fi apo asunwọn ile ifowopamọ Ajirebi soju opo Istagram wọn lati beere iranwọ owo fun osere tiata naa, ko le tete bọ lọwọ ajalu ọhun.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Sugbọn nigba ti yoo fi di ọwọ ọsan ni iroyin miran tun ti gbalẹ kan pe Ọlọrun ti gbe alawore pade Ajirebi, ti onitọun si fun ni ile ti yoo maa gbe.

Kia tun ni awọn osere tiata naa tun ya bo oju opo Instagram wọn lati dupẹ lọwọ awọn alaanu to gba ọrọ ẹdun Ajirebi naa ro.

Koda, osere tiata kan, Kemi Korede kede pe osere tiata lobinrin miran Funke Akindele ti fun Ajirebi ni ile ti yoo maa gbe.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 4

Amọ ninu fidio kan ti Ajirebi se pẹlu osere tiata miran, Kunle Afod, o sẹ lori iroyin naa, to si ni Funke Akindele ko fun oun ni ilegbe rara.

Ajirebi, ẹni to dupẹ pupọ lọwọ awọn ololufẹ rẹ atawọn osere tiata lorisirisi ti wọn dide iranwọ fun wa gbadura pe Ọlọrun yoo wa pẹlu wọn.

Kayode Olaseyinde, Ajirebi

Oríṣun àwòrán, Ajirebi1 Instagram

"Mo dupẹ pupọ lọwọ Funke Akindele fun iranwọ owo to fun mi. Mo n salaye fun gbogbo aye pe Funke Akindele ko fun mi ni ile gẹgẹ bi awọn eeyan kan se maa n sọ.

Amọ o fun mi ni owo lati gba ilegbe miran ti maa gbe titi ti ojo yoo fi lọ, mo si n dupẹ pupọ lọwọ rẹ."

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Bakan naa lo tun mọ riri Toyin Abraham ati ọkọ rẹ fun iranwọ owo ti wọn fun, to si gbadura pe gbogbo awọn eeyan to se iranwọ owo fun oun, ni ọba oke yoo fi ọpọ rọpo fun.

Nibayi ti gbogbo eeyan n ba Ajirebi yọ pe o ni ibi tuntun ti yoo maa gbe, awa naa n ba dawọ idunnu pe, o ku oriire.