Henry Fajemirokun: Olókoòwò yíká àgbáyé tó bẹ̀rẹ̀ ètò okoòwò lábẹ́ Ecowas

Henry Fajemirokun

Oríṣun àwòrán, Funeral Programme of Fajemirokun

Bi ẹ ko ba mọ erin, se ẹ ko gbọ ohun erin ni, bi ẹ ko ba si mọ ọsa, se ẹ ko jiyọ lọbẹ, bi ẹ ko ba mọ Henry Oloyede Fajemirokun, ẹ sa mọ awo orin kan.

Orin naa ni: "Awọn ẹda kan lo wa, ti wọn n fẹ ki ẹnikeji jẹ, iru wọn ni ti Fajemirokun,

To fi owo mọ Oluwa, to tun fi mọ eniyan, ile isẹ rẹ, aimọye eniyan ni wọn n jẹ, ti wọn n mu."

Ti a ba n sọrọ okoowo ati isẹ aje, bi kanhun se jẹ ọga ni awujọ okuta, naa ni Henry Fajemirokun jẹ ọga lawujọ ọrọ aje lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A si lee se apejuwe Henry Fajemirokun bii atapata dide, to de ibi giga, lati ipasẹ okoowo eyi to yẹ kawọn ọdọ fi se awokọse rere.

Gẹgẹ bi a se ka itan igbe aye akọni olokoowo naa loju opo Wikipedia lori itakun agbaye, Fajemirokun ko ipa ribiribi si agbega ọrọ aje lẹkun Iwọ Oorun ilẹ Afirika.

Fajemirokun n kọ iwe, eeyan meji wa ni ẹgbẹ ọtun ati osi rẹ

Oríṣun àwòrán, @YorubaHistory

Bi itan igbe aye rẹ si se lọ ree:

Ibẹrẹ aye, eto ẹkọ ati isẹ oojọ ti Henry Fajemirokun se:

  • Daniel Famakinwa ati Felicia Adebumi Fajemirokun ni orukọ awọn ọlọkọ to wa Henry Oloyede wa sile aye.
  • Ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu Keje, ọdun 1926 ni a bii, Ile Oluji nipinlẹ Ondo si ni wọn ti wa.
  • Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Peteru Mimọ ni ilu Ile Oluji ati Luku Mimọ nilu Oke Igbo lo ti ka eto ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ.
Àkọlé fídíò, Oladapo Adu: Nàíjíríà já mi kulẹ̀ torí wọn kò wá gbé mi
  • Bakan naa, Henry Fajemirokun lọ sile ẹkọ girama CMS nilu Eko fun eto ẹkọ girama rẹ.
  • O si pari rẹ si Ondo Boys High School laarin ọdun 1942 si 1944
  • Lẹyin eyi lo dara pọ mọ ileesẹ ologun RWAFF lẹni ọdun mejidinlogun, to si bawọn ja ogun agbaye keji
  • Bakan naa lo sisẹ bii akọwe nileesẹ ifiweransẹ Post Office lẹyin ogun agbaye keji, to si tun di aarẹ fun ẹgbẹ awọn ajagunfẹyinti lọdun 1948
  • Oun yii naa si tun ni aarẹ ẹgbẹ awọn akọwe nile ifiweransẹ lọdun 1952.

Awọn okoowo nlanla ti Henry Fajemirokun dawọle:

  • Niwọn igba to jẹ pe ọna kan ko wọ ọja, Henry bẹrẹ isẹ okoowo aladani tiẹ lọdun 1955 lati inu owoya to gba lọwọ mọlẹbi rẹ kan ni idile iya rẹ
  • O bẹrẹ okoowo kiko awọn ire oko lọ soke okun, okoowo egungun maalu lo kọkọ fi bẹrẹ, ko to tun fi awọ maalu kun un.
  • Lẹyin naa lo n ko koko, rọba, kọfi, ati eso ori lọ soke okun, to si n ko simenti pada wa sile lati ta
  • Gbogbo awọn onibara rẹ lo ni igbẹkẹle nla ninu rẹ, to si tun ri owoya gba lati fi se amugbooro eto okoowo rẹ
Àkọlé fídíò, Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran
  • Nigba to di ọdun 1960, Henry ti di ọkan lara awọn ilumọọka olokoowo simẹnti eyi to n ko wọle lati orilẹ-ede Egypt ati Poland
  • Ile ifowopamọ kan ni London si lo n fun un ni owoya lati mu ki okoowo naa rọrun, ko si fẹju sii.
  • Lati ipasẹ okoowo to burẹkẹ yii ni Fajemirokun ti da ileesẹ olokoowo Henry Stephens silẹ, ti ileesẹ naa si gbọrẹgẹ-jigẹ
  • Henry yapa sidi oniruuru okoowo bii tita simenti ati eroja ikọle, imọ ẹrọ, ile ifowopamọ, eto adojutofo, kiko ọja lọ soke okun ati gbigbe ọja wọle
  • Awọn okoowo miran to tun dawọle ni eto irinna ọkọ oju omi, ati epo rọbi, to si jẹ gbajugbaja laarin awọn olokoowo nigba naa
  • Laarin ọdun mẹwaa, Ileesẹ Fajemirokun ti gbooro debi pe o n se katakara pẹlu awọn ileesẹ ilẹ okeere nilu Ọba, Amẹrika, Poland, Japan, Belgium, Egypt, Germany and Brazil.
Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Bi ileesẹ Fajemirokun se gbọrẹgẹ-jigẹ:

  • Nigba ti yoo fi di ọdun 1977, ileesẹ Fajemirokun ti n dawọle isẹ kikọ awọn ile itura, ileesẹ to n se mọto nla-nla ati ọkọ akẹru.
  • Koda, o ti bẹrẹ ileesẹ to n se ọti lile ati bia, to fi mọ isẹ idagbasoke awọn ibudo iwakusa lorisirisi bii kuari to n pese eroja ti wọn fi n se simẹnti
  • Henry Oloyede Fajemirokun tun lewaju ijiroro lori agbekalẹ awọn banki olokoowo fawọn onileesẹ aladani laarin Naijiria ati Amẹrika, NAMBL
  • Oun yii kan naa si ni ẹni akọkọ to sedasilẹ ẹka ileesẹ akoso oju omi ni Naijiria, to si tun kọkọ ni ọkọ oju omi to n gbe ẹru lọ soke okun.
Àkọlé fídíò, Itan Omi Erin
  • Ileesẹ Fajemirokun tun lo kọkọ jẹ ileesẹ aladani akọkọ to gba asẹ lati wa epo rọbi loju omi lọdun 1970, to si tun jẹ oludari banki First Bank
  • Ileesẹ rẹ naa lo tun kọkọ gba iwe asẹ lati pin ẹrọ Rank Xerox, to si tun jẹ ara awọn oludasilẹ to kopa to giriki ninu agbekalẹ banki ajọ ECOWAS, bi o tilẹ jẹ pe oun gan an ti jade laye ki agbekalẹ banki naa to bẹrẹ
  • Ileesẹ Henry Fajemirokun yii naa jẹ oludokoowo gboogi nileesẹ Johnson Wax ati Fan milk, pẹlu ileesẹ nla meji mii to nimọ nipa ẹrọ abanikọle.
Àkọlé fídíò, Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí

Awọn ipa manigbagbe ti Henry Fajemirokun ko si iranwọ ọmọniyan:

  • Gẹgẹ bi orin ti Ebenezer Obey kọ fun Fajemirokun, ilumọọka ọlọrọ naa fi owo rẹ mọ Oluwa, to si tun fi mọ eniyan nitori nile isẹ rẹ, aimọye eniyan ni wọn n jẹ, ti wọn n mu
  • Bo si se n sisẹ aanu rẹ labẹle lorilẹ-ede Naijiria, naa lo tun n se nilẹ okeere.
  • Paapaa lorilẹ-ede South Africa, eyi to fidi rẹ mulẹ pe bo ti n se fun alejo, naa lo n se fun onile
  • Lasiko ogun abẹle ni Naijiria, ipa nla lo ko lati se atilẹyin fun ẹgbẹ alaanu Red Cross.
  • Fajemirokun tun n se iranwọ fun ọpọlọpọ eeyan miran to nilo atilẹyin rẹ nigba naa
  • Owo ribiribi lo n gbe kalẹ fun amugbooro ẹka eto eto ati idagbasoke awujọ ati awọn ileẹkọ giga wa ni Naijiria.
Àkọlé fídíò, Ẹ̀mí kan náà ló n darí ìrìnàjò wa táa fi jọ kọ́lé papọ̀- Ìbejì

Awọn oye ati ami ẹyẹ ti wọn fi da Henry Fajemiloku lọla:

  • Awọn eeyan mọ riri ipa ribiribi ti Henry Fajemirokun ko si idagbasoke awujọ ati iran ọmọniyan, ti Jegun Ile Oluji si fi oye Yegbata da a lọla lọdun 1968
  • Ọdun 1972 ni Fasiti Obafemi Awolowo tilu Ile Ife fi oye Ọmọwe (PHD) ninu imọ nipa akoso okoowo, Business Administration da a lọla, lati mọ riri ipa nla to n ko si eto ẹkọ ati okoowo lawujọ wa
  • Bakan naa ni wọn tun fi jẹ Asiwaju ilu Oke Igbo lọdun 1971, Lijoka ti Ondo ni 1973.
  • O tun je Orunta tilu Ifewara ni 1974 ati Obaloro tilu Ado Ekiti ni 1977
  • Bakan naa, lẹyin ọdun marun un to ti jade laye, ijọba apapọ tun fun un ni ami ẹyẹ CON (Commander of the Order of the Niger).
  • Eyi ni ijọba se lati mọ riri ipa ribiribi to ko si idagbasoke eto okoowo ati ileesẹ nlanla ni Naijiria.
Henry Fajemirokun ati aya kan

Oríṣun àwòrán, Others

Idile Henry Fajemirokun:

Baba ọlọla yii fẹ iyawo, oloogbe Comfort Oseboade Fajemirokun, ẹni to papoda lọdun 2019.

Ọlọrun fi awọn ọmọ si aarin awọn mejeeji, lara awọn ọmọ rẹ ni ilumọọka olokoowo kan to kalẹ silu Eko, Dele Fajemirokun.

Dele naa lowo bii baba rẹ, o lọla, to si jogun ileesẹ baba rẹ nilu Eko.

Àkọlé fídíò, Wo itan omi gbigbona ati tutu ni Ikọgosi Ekiti

Iku Henry Oloyede Fajemirokun:

  • Ọjọ nla ni ọjọ Kẹẹdogun, osu Keji, ọdun 1978 ti wọn tufọ iku gbajumọ olokoowo naa pe o ti jade laye.
  • Igi oko dori kodo, ojojo n se ewebẹ ọja, omi n bọ loju alawọ dudu ati funfun, ti koowe si ke lai ha.
  • Ilu Abidjan nilẹ Cote D'ivoire si ni Henry Fajemirokun ku si lasiko to lọ se ipade okoowo kan nibẹ.
  • Iroyin kan ti ko fidi mulẹ ni ilẹ lo yọ ẹlẹyinju aanu naa ni baluwẹ, to si subu, to ki aye pe o digbo se, oku rẹ si ni wọn ba nile itura to wa.
Henry Fajemirokun ati aya rẹ, Comfort

Oríṣun àwòrán, Comfort Fajemirokun

Ẹni ọdun mọkanlelaadọta pere ni Henry Oloyede Fajemirokun nigba to lọ sọrun ọsan gangan.

Yoruba ni ka ku ni ọmọde ko yẹ ni san ju ka dagba lai ni adiẹ irana lọ.

Osu Keje, ọdun 2020 yii si ni oloogbe naa ko ba pe ẹni ọdun mẹrinlelaadọrun.

BBC Yoruba wa gbadura pe Ọba oke yoo dẹ ilẹ fun oloore to lọ.

Pẹlu imọran pe ki onikaluku tete ja itanna rẹ to n tan nitori a ko mọ igba ti ọlọjọ maa de.

Àkọlé fídíò, Awọn Obinrin Dahomey: Awọn obinrin ilẹ Afirika ti wọn yii itan pada re e