Local Flight: Àyípadà tó bá pápákọ̀ òfurufú Abuja rèé bí ìrìnà òfurufú abẹ́lé ṣe bẹ̀rẹ̀

Ẹ fójú lóunjẹ bi pápákọ̀ òfurufú Abuja olu ilu orilẹede Naijiria ṣe ri lasiko ti ijọba ni ki wọn bẹrẹ irina abẹle pada.

Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Ẹ káàbọ̀! Ẹ sanwo ẹ gba turọli yin o. Ko sẹni ti yoo baa yin gbe ẹru kankan afi tẹ o ba san asanle
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn ṣi irina ọkọ ofurufu labẹle ree ni papakọ ofurufu ti Abuja
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Lati ẹnu ibode gan lẹ o ti gba apẹrẹ onirin ẹlẹsẹ mẹta too fi ti ẹru rẹ funraraa rẹ
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Lara eto ti ijọba gbekalẹ fun imọtoto ni pe waa fọ ọwọ rẹ tonitoni koo to wọ inu gbọngan papakọ ofurufu
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Iṣẹ ko pọ rara fun awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu ti awọn naa ṣẹṣẹ wọle iṣẹ
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Akọle ti wa kaakiri ibi ti ẹ ba n lọ tabi gba kọja pe ki ẹ maa tẹle ofin injinasiraẹni, lilo ibomu, ati oogun apakokoro fi pawọ.
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, To ba ti kan ẹru kiko, ọwọ ara ẹni la fi n tun iwa ara ẹni ṣe
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Àwọn ẹṣọ pápákọ̀ òfurufú Abuja gan n fi pẹlẹ kutu ṣiṣẹ ni
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Diẹ diẹ lawọn ọkọ ofurufu to n rinrinajo. Abuja si Eko nikan si ni ijọba fun wọn laṣẹ
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Ilumọka oṣere Zack Orji naa ba wa rinrinajo lati Abuja si Eko
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Ọwọ ara rẹ loo fi mu omi ninu apo ẹyin aga to ba wa niwaju rẹ
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Ẹnikẹni ko lee ran ẹ lọwọ lati gbe ẹru rẹ soke koda ko danu, ọwọ ara rẹ loo fi ko o afi bi ẹni naa ba kan fẹ yoo si fi sanitizer pawọ
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Fọto lati oju ferese ọkọ baalu bi ẹni n loṣo wo awọn ọkọ baalu to ku
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Aye o le, ibi to ba ti ba wa, ẹ́ jẹ ka jẹ ẹ
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Ofin iijinasiraẹni lasiko ijoko
Pápákọ̀ òfurufú Abuja
Àkọlé àwòrán, Lọkọọkan lẹ o to jade tẹ o si jina si ara yin - ofin ijọba ree ṣugbọn ṣe bẹẹ lo ri ninu aworan yii?