Alaafin Aole: Ṣé òótọ́ ni pé èpè Alaafin Aole ń ja Yorùbá títí di òní?

Oríṣun àwòrán, Others
Ni ọpọ igba ti aigbọraẹniye ba waye laarin awọn ọmọ Yoruba, ọpọ eeyan lo maa n mẹnuba a pe 'epe Aole lo n ja wa, ni isọkan ko ṣe wa ni aarin wa.'
Ọpọ ọdọ lode oni si lo fẹ mọ ohun ti iran Yoruba ṣe fun Aole, to fi ṣẹ epe naa.
Ati pe, ṣe lootọ ni epe naa n ja ẹya Yoruba, eyi to mu ki ifẹ, isọkan ati igbọraẹniye sọnu laarin ọmọ Oodua.
Idi ree ti BBC Yoruba fi ṣe akojọpọ itan nipa igbe aye Alaafin Aole, ija rẹ pẹlu Afonja, titi de ori iku ati epe ti wọn lo ṣẹ fun Yoruba.
Awọn itan manigbagbe mii ti ẹ le nifẹ si lati ka:
- ₦35,000 ni mò ń gbà bíi Adelé ọba, kò sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ - Adelé Olúbọ̀rọ̀pa
- Ìrántí Sani Abacha, apàṣẹ wàá tó tún kó owó Nàìjíríà mì
- Àwọn 'ẹ̀bùn' tí ikú George Floyd fún àgbáyé
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, ó kọ́ wa láti máa ni ìtẹ́lọ́rùn
- Sanusi Adebisi Idikan rèé, olówó tó ń san owó orí fún gbogbo ọkunrin ilẹ̀ Ibadan
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
Gẹgẹ bi a ṣe ka a loju opo itakun agbaye ati ninu awọn iwe itan lorisirisi, ọba ilu Oyo ni Alaafin Aole, Afonja si ni aarẹ ọna Kakanfo rẹ, ohun to si fa aawọ laarin awọn mejeeji, ti Aole ṣe binu ṣẹ epe ree:
Ija Alaafin Aole ati Afonja:
Ni igba ijọba Oyo ijọhun, asẹ ti Alaafin ba pa laarin ilu, abẹ lo gee nitori lẹyin asẹ Ọba, ko si ọrọ miran mọ, Ọba lo ni ilẹ, Ọba lo ni ohun gbogbo.
Iru aṣẹ bẹẹ ko si yọ awọn ijoye Alaafin, eyiun Oyomesi silẹ, to fi mọ awọn olori ilu to wa labẹ isejọba ni Oyo ati olori ikọ ologun, tii ṣe Aarẹ Ọna Kakanfo.
Itan sọ fun wa pe ọmọ Alaafin Abiodun ni Aole, o si jọba nilu Oyo laarin ọdun 1789 si 1796,
Alaafin Ajagbo si lo ṣe ifilọlẹ oye Aarẹ Ọna Kakanfo ti Afonja jẹ, bi o tilẹ jẹ pe Alaafin Abiodun lo fi Afonja jẹ oye naa.
Ọmọ bibi ilu Iwere ile, to wa ni ẹba ilu Iganna ni agbegbe Oke Ogun ni ẹkun ariwa ipinlẹ Oyo, ni iya Alaafin Ajagbo ati Abiodun.
Amọ Ajagbo ti ge ègún pe aarẹ ọna Kakanfo kankan ko gbọdọ ko ogun ja ilu naa laelae.
Ki lo fa epe ti a n sọ yìí?
Ni ọjọ kan, Aole ke si Afonja, tii ṣe Aarẹ Ọna Kakanfo rẹ pe ko gbe ogun lọ si awọn ilu kan, ninu eyi ti ilu Iwere ile wa, ti Afonja si yari pe ko ni ṣeeṣe nitori egun ti Alaafin Ajagbo ti fi lelẹ saaju.
Alaafin Aole ri iwa Afonja lati tapa si asẹ oun bii igberaga ati ọyaju,
Ọrọ naa si di isu ata yan-yan laarin awọn mejeeji, ija nla to gbona gidi dIde lati ibẹ ni eyi ti awọn Akọni mejeeji si gba lati doju ogun kọ ara wọn tabi fija pẹẹta.
Akoko ti aawọ wa laarin Afonja ati Aole yii ni Shehu Alimi ati awọn eeyan rẹ, tii ṣe ẹya Fulani ja ogun itankalẹ ẹṣin Islam de ilu Ilorin níbi ti Afonja n gbe
- Fásitì Ibadan pohùndà lórí àdíkùn tí wọ́n mú bá iye ọjọ́ tí àwon òṣìṣẹ́ yóò máa fi lọ ibi isẹ́
- Ìjọba ti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ 500 tó ń ṣiṣẹ́ lọ́nà àìtọ́ pa
- Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì FUTA jáde láyé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fárígá, wọ́n ní àìbìkítà àwọn aláṣẹ ló ṣokùnfà ikú rẹ̀
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbéyàwó 'Auren Zaurawa' tí ìjọba Kano fẹ́ ná N854m lé lórí
Afọnja ko gbe Ọyọ nitori pe eewọ ni ki Aarẹ Ọna Kakanfo ba Alaafin gbe nilu Oyo, agbo meji ko lee mu omi ninu koto kan ṣoṣo.
Afonja gba awọn Fulani naa tọwọ tẹsẹ, to si beere iranwọ Alimi lati jagun sẹgun lori ogun Apomu, nitori onitọHun naa ni ọmọ ogun pupọ ati oogun abẹnu gọngọ to daju.
Nigba ti Afonja n bọ lati Apomu, o fi ẹsẹ kan ya nilu Oyo, to si pa aroko si Aole pe ko si igbá wo, eyi to tumọ si pe ko gba ẹmi ara rẹ, to si fi igba ademu ransẹ si i.
Aroko yii ni agbara pupọ nitori bi Aole ba kọ, to ṣe bii ojo lai si igba wo, awọn ọmọ ogun Afonja yoo papa pa a ni.
Amọ ko baa le ṣe bi Akọni eyi ti a mọ awọn Ọba alaye mọ, Afonja pinnu lootọ lati si igba wo, ko si fi aye silẹ.
Ṣugbọn itan naa fi ye ni pe ki Aole to gba lati ku gẹgẹ bi Afonja ti paṣẹ fun, Alaafin Aole ṣẹ epe nla fun iran Yoruba,
Epe yii ni eyi ti awọn kan gba pe egun naa lo n ja iran Yoruba titi di oni, ti imọ wọn ko fi ṣe ọkan.
Epe ti Alaafin Aole ṣẹ fun iran Yoruba:
Gẹgẹ bi iwe itan ti ẹni-ọwọ Samuel Johnson ti sọ ninu iwe Itan Ẹya Yoruba to kọ, o ni ki Aole to si igba wo, o pe oriki ati ipọnri awọn baba nla rẹ ati awọn Alaafin to ti jẹ saaju rẹ.
O ni lẹyin eyi ni Alaafin Aolẹ yin ọfà mẹta, ti kii ṣe ọfà lasan, si origun mẹta yika ilẹ Yoruba.
Aole wa ni " ki epe mi maa wa lori yin titi laelae ẹyin iran Yoruba ati arọmọ-dọmọ yin, fun iwa ailootọ ati aigbọran ti ẹ hu, awọn ọmọ yin yoo maa ṣe aigbọran si yin ni'.
O tun ni: " Tẹ ba ran awọn ọmọ yín ni iṣẹ, wọn ko ni pada wale, wa jiṣẹ pada fun yin,
Gbogbo igun ti mo ba si ta ọfà yii si, ni wọn yoo maa ko yin ni ẹrú ni.
Epe mi yii yoo si gbe yin de ori òkun ati ikọja rẹ, awọn ẹru ni yoo maa dari yin, ti awọn adari yin yoo si di ẹrú, bẹẹ ni ilu yin ko ni roju, alaafia ko si ni si nibẹ."
Epe yii si ni ọpọlọpọ eeyan maa n tọkasi lasiko ti idaluru, aawọ, iyapa ati aigbọraẹniye ba wa laarin awọn olori, araalu, paapaa awọn oloselu ati ẹya Yoruba lapapọ.
Idi si ree ti BBC Yoruba fi n beere pe: Ṣé lootọ ni pe epe ti Alaafin Aole ṣẹ yii n ja iran Yoruba abi irọ ni?













