'Mo fẹ́ kópa níbi ìgbéyàwó ọlọ́pọ̀ èrò nítorí àwọn tó fẹ́ fẹ́ mi lẹ́yìn ikú ọkọ mi ni wọ́n sọ wí pé kò sówó láti ṣayẹyẹ'

Kí ọdún yìí tó parí ìjọba ìpínlẹ̀ Kano yóò ṣe ìgbéyàwó alárinrin ńlá níbi tí wọ́n yóò ti ṣe ìgéyàwó fún ènìyàn 1,020 káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlélógójì ìpínlẹ̀ náà.
Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kẹjọ ọdún 2023 ni gómìnà Abba Kabir Yusuf ti ìpínlẹ̀ Kano kéde pé ìjọba òun ti ya owó N854 million sọ́tọ̀ fún ayẹyẹ ìgbéyàwó náà tí èyí sì ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára.
Ní ọdún 2011 ni ìjọba Kano bẹ̀rẹ̀ ètò ṣíṣe ìgéyàwó ọlọ́pọ̀ èrò níbi tí wọn yóò ti san owó orí àti ra àwọn ohun èlò inú ilé fún àwọn obìnrin tó bá ti tó lọ sílé ọkọ àti ọkùnrin tó bá ti tó gbé ìyàwó àmọ́ tí kò lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Zainab Dukawuya, ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó fẹ́ kópa níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó ọlọ́pọ̀ èrò ti ọdún yìí.
Ó ní ètò yìí yóò jẹ́ àǹfàní fún òun láti tún ṣe ìgbéyàwó mìíràn lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí ọkọ òun àkọ́kọ́ jáde láyé.
“Mo ní ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó wù láti fẹ́ mi àmọ́ tí wọn kò lágbára láti ṣayẹyẹ ìgbéyàwó nítorí gbogbo nǹkan tó ti gbówó lórí lásìkò yìí.
Àsìkò yìí dára fún mi láti ṣe ìgbéyàwó nítorí ìjọba lọ máa pèsè gbogbo nǹkan tí a nílò, tí mò sì ń gbàdúrà wí pé kí ètò náà lọ ní ìrọ̀wọ́rọsẹ̀ láì ní ẹja n bákàn nínú rárá.”
Zainab ṣàlàyé pé òun ní àwọn ọ̀rẹ́kùnrin méjì tí àwọn ń bá ara àwọn sọ̀rọ̀ lásìkò yìí ṣùgbọ́n tí òun bá ri pé kò sí èyí tó ṣetán láti gbé òun sílé nínú àwọn méjéèjì, òun máa kàn sí ikọ̀ Hisbah láti bá òun wá ọkọ lẹ́yìn tí òun bá fi orúkọ sílẹ̀ tán.

Ẹlòmíràn tí òun náà ń gbèrò láti kọpa níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó yìí, Abdullahi Dinga, ẹni ọdún méjìdínlógójì sọ fún BBC pé ó ti pẹ́ tí ó ti wu òunláti ṣe ìgbéyàwọ àmọ́ àìsí agbára rẹ̀ ni kò jẹ́ kí òun ti gbé ìyàwọ sílé.
Abdullahi ní láti ọjọ̀ pípẹ́ ni òun ti ń tu owó jọ tí òun fẹ́ fi ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó àmọ́ ọ̀wọ́n gógó tó bá gbogbo nǹkan ló mú kí òun ná owó ọ̀hún fi jẹun.
“Láti ọjọ́ pípẹ́ ni ìgbéyàwó ti wà ní ẹ̀mí mi, àǹfàní sì ni ètò ìjọba yìí jẹ́ fún mi láti mú àlá mi wá sí ìmúṣẹ.
Ní kété tí ètò náà bá ti bẹ̀rẹ̀ ni mà á lọ fi orúkọ sílẹ̀, mo ní àfẹ́sọ́nà, owó ló ń dáwa dúró tí a kò fi tíì ṣe ìgbéyàwó.”
Ọ̀pọ̀ ìwádìí la máa ṣe kí ìgbéyàwó náà tó wáyé
Nígbà tí ìjọba kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ètò yìí ní ọdún 2011, àwọn ìpèníjà kan ló wáyé lẹ́yìn ìgbéyàwó náà nígbà tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn kan ló ní ìpèníjà ìlera kan tàbí òmíràn nínú àwọn tí wọ́n ṣe ayẹyẹ náà fún.
Ìdí nìyí tí ọ̀gá àgbà ikọ̀ Hisbah, Sheik Daurawa ní àwọn kìí fi àyẹ̀wò ìlera ṣeré rárá.
Daurawa ní gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó náà ni ó pọn dandan fún láti ṣe àyẹ̀wò ìlera mẹ́rin kan kí àwọn tó lè yàn wọ́n rárá.
Ó ní àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe Kí àwọn tó lè mú ẹnikẹ́ni rárá ni àyẹ̀wò àrùn kògbóògùn HIV, àyẹ̀wò oyún, àyẹ̀wò “genotype” àti lílo egbògi olóró.
Ó fi kun pé ẹnikẹ́ni tí kò bá yege àwọn àyẹ̀wò yìí ni àwọn kò ní mú àti pé ogún ènìyàn ni àwọn máa mú ní ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan, tí àwọn ìgbìmọ̀ yóò sì pèsè ọgọ́fà ènìyàn tó kù.
Hajiya Hadiza Ado tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹgbẹ́ kan tí kìí ṣe ti ìjọba, Women and Child Initiative, ní àwọn fọwọ́ sí ohun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kano ń ṣe.
Hajiya Ado ní ìdí tí àwọn fi ṣàtìlẹyìn fún ètò ìjọba yìí kò ṣẹ̀yìn pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló wù láti ṣe ìgbéyàwó àmọ́ owó ló ń lé wọn sá.
Ó ní ìgbèsẹ́ ìjọba yìí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ àti pé yóò mú àdínkù bá bí àwọn ènìyàn ṣe ń lóyún lọ́nà àìtọ́ nítorí tí wọn kò lágbára ìgbéyàwó.
Bákan náà ló pàrọwà sí ìjọba láti mú àwọn àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba mọ́ra lórí ètò yìí kí wọ́n le máa tọpinpin àwọn ìgbéyàwó náà lẹ́yìn ọjọ́ ayẹyẹ àti pé yóò jẹ́ kí àwọn tọkọtaya tó bá jẹ àǹfàní ètò náà mọ̀ wí pé àwọn kò lè máa hùwà àìtọ́ nínú ìgbéyàwó àwọn.
Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbéyàwó 'Auren Zaurawa' tí ìjọba Kano fẹ́ ná N854m lé lórí

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Kano ti buwọlu lu owo to to ọtalelẹgbẹrin o din mẹfa miliọnu naira (N854 milion) fun ayẹyẹ igbeyawo ọlọgọọrọ ti wọn n pe ni Auren Zaurawa Mass Wedding Initiative.
Bakan naa ni ijọba fun buwọlu ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira (N700m) fun iranwọ awọn akẹkọọ to n kawe ni fasiti Bayero University Kano(BUK).
Gomina Abba Kabir Yusuf lo fi eyi lede ni loju opo X rẹeyi ti a mọ si oju opo Twitter tẹlẹ.
Gomina naa ni awọn buwọlu iye owo to to N700m naa fun awọn akẹkọọ fasiti BUK lasiko ijiroro awọn igbimọ amuṣẹya fun ijọba.
Wọn ni eyi yoo mu adinku ba iṣoro eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ ni Naijiria, ti wọn si ni awọn akẹkọọ ti wọn ko ni owo ni yoo jẹ anfaani rẹ.
Bakan naa ni wọn fikun un pe ẹkunrẹrẹ bi awọn yoo ṣe pin owo iranwọ naa ni wọn yoo fi lede ni aipẹ.
Ijọba buwọlu N854 milion naira fun eto igbeyawo ọlọgọọrọ Auren Zaurawa
Ijọba ni awọn ti owo iranwọ lede fun eto igbeyawo ọlọgọọrọ nibẹ ati owo iranwọ fun awọn oṣiṣẹ fẹyinti.
Owo iranwọ yii ni ijọba bẹrẹ ni nkan bii ọdun mẹfa ṣẹyin, ti wọn fi n ṣe iranwọ fun awọn ololufẹ nipinlẹ naa.
Owo naa ni wọn yoo fi ra eru lati fi ran ọkọ lọwọ ti wọn gbe lọ si ile ọkọ.
Ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa eto igbeyawo ọlọgọọrọ Auren Zaurawa

Oríṣun àwòrán, Others
Lasiko ijiroro pẹlu adari ẹka to wa nidi iyawo ọlọgọọrọ naa, Sheik Aminu Daurawa sọ fun BBC pe idi ti wọn fi n gbe igbeṣẹ naa ni lati rii wi pe awọn to fẹ ṣegbeyawo ti wọn ko ni owo ri iranwọ lati ṣe bẹẹ.
Eyi ni yoo jẹ ẹlẹẹkẹfa rẹ lẹyin ti gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Abdullahi Ganduje fi ofin de ayẹyẹ naa fun ọdun mẹrin.
O ni igbeṣẹ akọkọ ni ki wọn wa si ọfisi wọn lati wa gba fọọmu, bio tilẹ jẹpe wọn ko tii bẹrẹ si ni fun awọn eniyan ni fọọmu naa bayii.
Ẹ ni ti o fẹ gba fọọmu naa yoo ti ri ẹni ti o fẹ fẹ abi ki o gba Hisbah laaye lati fun ni ẹni ti oun naa n wa ọkọ tabi aya.
Sheik Daurawa ni igbimọ ẹlẹni mẹtalelogun ni yoo gbe ayẹyẹ igbeyawo naa kalẹ.
Lẹyin igbeyawo ọhun ni awọn igbimọ miran yoo bẹrẹ iṣẹ lati maa tọ pinpin awọn lọkọ-laya naa ki wọn ba le mọ pe wọn wa ni ailewu.












