Kí ló kàn fún ẹgbẹ́ òṣèlú LP lẹ́yìn tí iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kéde Apapa ní Alága?

Aworan Apampa, aworan idanimọ LP ati Abure

Oríṣun àwòrán, Others

Ileẹjọ kọtẹmilọrun to kalẹ si ilu Owerri, ni ipinlẹ Imo ti fi ọwọ osi juwe ile fun Julius Abure, ti wọn si buwọlu Lamido Apapa gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Bakan naa ni ileẹjọ paṣẹ pe ki ajọ INEC ki o kede orukọ awọn gomina ti ẹgbẹ oṣelu Labour, ti igun Apapa fi lede gẹgẹ bi gomina, ki wọn si yọ awọn gomina ti ẹgbẹ alatako fi lede pe o jawe olubori ni ipinlẹ Imo, Bayelsa, ati Kogi

Bakan naa ni ileẹjọ fi ọwọ osi juwe ile oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour lati igun Abure, Sẹnetọ Athan Achonu lati ipinlẹ Imo.

Kilo fa ifanfa laarin igun Abure ati igun Apapa?

Ẹgbẹ oṣelu Labour party lo kọkọ kede pe igun Lamidi Apapa n gbiyanju lati dabaru ẹjọ ti wọn pe tako esi idibo to gbe aarẹ Tinubu wọle.

Lẹyin naa ni ẹgbẹ sọ wipe awọn ti fi ọwọ osi juwe ile fun Apapa lati lọ rọkun nile, nitori o kede pe oun ni adele fun alaga ẹgbẹ oselu Labour Party.

Amọ ni oṣu kẹrin ni Apapa gbe ẹjọ lọ si ileẹjọ wi pe o lodi si ofin bi wọn ṣe yọ oun ninu ẹgbẹ oṣelu naa to si ni oun ni adari ẹgbẹ naa.

Ni Oṣu Kẹjọ ni ileẹjọ kotẹmilọrun to joko ni ilu Benin kede pe Abure ni adari ẹgbẹ naa, ti akọwe ẹgbẹ naa, Obiora Ifoh si fi lede.

Saaju ni ileẹjọ giga kan ni ilu Benin naa ti fi ọwọ osi da ẹjọ to ni ki wọn yọ Abure ni ipo.

Awọn kan kọlu Apampa nibi igbẹjọ esi ibo aarẹ nilu Abuja

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Awọn kan kọlu Apampa nibi igbẹjọ esi ibo aarẹ nilu Abuja

Njẹ idajọ kọtẹmilọrun yoo nipa lori idajọ Tribunal nipa ẹjọ ti Peter Obi pe tako Aarẹ Tinubu?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Onimọ nipa eto ofin, Agbẹjoro Inibehe Effiong lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni o da oun loju pe idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun ko ni nkankan se pẹlu igbẹjọ laarin Peter Obi ati Aarẹ Tinubu.

Effiong ni labẹ ofin eto idibo ko si nkan to kan Tribunal pẹlu iṣẹlẹ to n waye laarin ẹgbẹ oṣelu.

O fikun un pe ko si bi igun kan le gbe ohunkohun se lai si ekeji.

‘’Ko si pe ẹgbẹ labẹ aṣẹ Apapa yoo tako igbẹjọ to wa ni ile ẹjọ, iyẹn ko lee ṣeeṣe nitori wọn nilo ki ẹgbẹ oṣelu Labour ati Peter Obi buwọlu ki wọn to le ṣe ohunkohun.’’

Bakan naa lo fikun un pe o ṣeeṣe ki awọn igun Abure gbe ẹjọ lọ si ileẹjọ giga julọ, ti yoo si jẹ pe awọn ni yoo fi idajọ to peleke lede fun gbogbo awọn ti ọrọ kan.

Amọ ninu ọrọ tirẹ, Agbẹjọrọ Toyin Ojo ni nigba miran awọn adajọ ma n wo ohun ti awujọ n sọ lati gbe idajọ kalẹ, amọ o fikun un pe o da oun loju pe ko yẹ ki igbẹjọ to n waye labẹle niise pẹlu idajọ Tribunal ti gbogbo eniyan n reti.

Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi lo pe ẹjọ tako esi idibo to gbe aarẹ Tinubu wọle gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede Naijiria.