Bola Ahmed Tinubu
Wọn burawọle fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bi aarẹ16th ni May 29
O di ipo gomina Eko mu larin ọdun 1999-2007
O tun ṣe sẹnetọ ipinlẹ Eko, akọṣẹmọṣẹ iṣiro si tun ni pẹlu.

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti burawọle fun awọn minisita tuntun ni ijọba rẹ, lẹyin oṣu mẹta ti wọn burawọle fun.
Awọn minisita naa ni wọn jẹ marunlelogoji, ti ọpọ ninu wọn si jẹ gomina tẹlẹri tabi asọfin tẹlẹri.
Bakan naa ni pupọ ninu awọn Minisita naa jẹ akọṣẹmọ iṣẹ ti wọn yan laayo ni ẹka imọ ofin, eto ilera ati imọ ẹrọ.

Aarẹ naa tun mu awọn meji ni ijọba aarẹ Buhari to kọja lọ lati di ipo minisita mu, awọn ni Heineken Lokpobiri ati Festus Keyamo.
Gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹ ijọba ni ijọba to ti kọja lọ, yatọ si jọba Goodluck Jonathan, awọn obinrin ko to ida ogun ninu awọn ti wọn yan naa.
Ẹkunrẹrẹ ree nipa awọn eniyan tuntun ni ijọba aarẹ Tinubu.

Awọn obinrin wa ni ijọba aarẹ Tinubu. Gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹ ijọba ni ijọba to ti kọja lọ, yatọ si jọba Goodluck Jonathan, awọn obinrin ko to ida ogun ninu awọn ti wọn yan naa.
Iye awọn obinrin to wa ni ijọba aarẹ Tinubu pọ ju ti awọn to wa ni ijọba Muhammadu Buhari ni saa kini ati saa keji rẹ.
Olaniyi Adebimpe, Damilola Ojetunde, David Ayoola; Boaz Ochieng, Dorothy Otieno.